ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọmọkùnrin Opó kan Jíǹde
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Èlíjà ké sí opó kan tó ń kó igi ìdáná jọ

      Ẹ̀KỌ́ 48

      Ọmọkùnrin Opó Kan Jíǹde

      Ìkòkò ìyẹ̀fun àti ìṣà òróró

      Lásìkò tí òjò kò fi rọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: ‘Lọ sí Sáréfátì. Opó kan wà níbẹ̀ tó máa fún ẹ lóúnjẹ.’ Nígbà tí Èlíjà dé ẹnu ọ̀nà ìlú náà, ó rí opó kan tó ń ṣa igi. Èlíjà sọ pé kó fún òun lómi mu. Bí obìnrin yẹn ṣe fẹ́ lọ gbé omi náà, Èlíjà sọ fún un pé: ‘Jọ̀ọ́, bá mi mú búrẹ́dì wá tó o bá ń bọ̀.’ Àmọ́, opó náà sọ fún un pé: ‘Mi ò ní búrẹ́dì kankan mọ́. Ìyẹ̀fun àti òróró díẹ̀ tí mo fẹ́ fi ṣe búrẹ́dì fún èmi àti ọmọ mi ló kù.’ Èlíjà wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà ti ṣèlérí pé tó o bá fún mi ní búrẹ́dì, ìyẹ̀fun àti òróró rẹ kò ní tán títí tí òjò fi máa rọ̀.’

      Lẹ́yìn náà, opó yẹn lọ ṣe búrẹ́dì fún Èlíjà. Jèhófà sì mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ torí pé ìyẹ̀fun àti òróró obìnrin náà ò tán, òun àti ọmọ ẹ̀ sì rí oúnjẹ jẹ títí òjò fi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.

      Àmọ́, nǹkan burúkú kan ṣẹlẹ̀. Ọmọkùnrin opó yẹn ṣàìsàn, ó sì kú. Obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Èlíjà pé kó ran òun lọ́wọ́. Èlíjà gba ọmọ náà lọ́wọ́ obìnrin yẹn, ó sì gbé e lọ sí yàrá kan lókè ilé náà. Ó gbé ọmọ náà sórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kọ́mọ yìí jíǹde.’ Iṣẹ́ ìyanu ńlá ló máa jẹ́ tí Jèhófà bá jí ọmọ náà dìde. Ìdí sì ni pé kò tíì sẹ́nì kankan tó jíǹde rí ṣáájú ìgbà yẹn àti pé obìnrin náà àtọmọ ẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì.

      Àmọ́, Jèhófà jí ọmọ náà dìde! Èlíjà wá sọ fún opó náà pé: ‘Wò ó! Ọmọ ẹ ti jíǹde.’ Inú obìnrin náà dùn gan-an, ló bá sọ fún Èlíjà pé: ‘Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹ́ torí pé ohun tí Jèhófà ní kó o sọ nìkan lò ń sọ.’

      Èlíjà mú ọmọkùnrin tó jí dìde náà wá fún opó náà

      “Ẹ wo àwọn ẹyẹ ìwò: Wọn kì í fúnrúgbìn, wọn kì í sì í kárúgbìn; wọn ò ní abà tàbí ilé ìkẹ́rùsí; síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí gan-an ju àwọn ẹyẹ lọ ni?”​—Lúùkù 12:24

      Ìbéèrè: Kí ni opó Sáréfátì ṣe tó fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé wòlíì Jèhófà ni Èlíjà lóòótọ́?

      1 Àwọn Ọba 17:8-24; Lúùkù 4:25, 26

  • Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Kan Tó Burú Gan-an
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn ìránṣẹ́ Jésíbẹ́lì ju Jésíbẹ́lì sísàlẹ̀ látojú wíńdò

      Ẹ̀KỌ́ 49

      Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Kan Tó Burú Gan-an

      Lọ́jọ́ kan tí Ọba Áhábù wà lójú wíńdò àáfin ẹ̀ ní Jésírẹ́lì, ó rí ọgbà àjàrà kan tó jẹ́ ti ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Nábótì. Ojú Áhábù wọ ọgbà àjàrà yìí, ó sì fẹ́ kí Nábótì tà á fóun. Àmọ́ Nábótì ò tà á fún un torí pé òun náà jogún ẹ̀ ni, ó sì lòdì sí Òfin Jèhófà kéèyan ta ilẹ̀ tó bá jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ̀. Kàkà kí Áhábù mọrírì ohun rere tí Nábótì ṣe yìí, ṣe ni Áhábù bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Ó bínú gan-an débi pé kò sùn, kò sì jẹun.

      Àmọ́ ìyàwó Áhábù burú gan-an, Jésíbẹ́lì lorúkọ ẹ̀. Jésíbẹ́lì sọ fún Áhábù pé: ‘Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì. O sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ohunkóhun tó o bá fẹ́. Màá gba ọgbà àjàrà náà fún ẹ.’ Jésíbẹ́lì wá kọ lẹ́tà sáwọn àgbà ìlú náà pé kí wọ́n parọ́ mọ́ Nábótì pé ó bú Ọlọ́run, kí wọ́n sì pa á. Àwọn àgbààgbà yẹn ṣe ohun tí Jésíbẹ́lì ní kí wọ́n ṣe, Jésíbẹ́lì wá sọ fún Áhábù pé: ‘Nábótì ti kú, ọgbà àjàrà náà ti di tìẹ.’

      Nábótì nìkan kọ́ ni aláìṣẹ̀ tí Jésíbẹ́lì pa, ó tún pa àwọn míì tó ń jọ́sìn Jèhófà. Abọ̀rìṣà ni, iṣẹ́ ibi sì kún ọwọ́ ẹ̀. Jèhófà rí gbogbo ohun burúkú tí Jésíbẹ́lì ṣe. Kí ni Jèhófà wá ṣe sí i?

      Lẹ́yìn tí Áhábù kú, Jèhórámù ọmọ ẹ̀ di ọba. Jèhófà wá rán ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jéhù pé kó lọ fìyà jẹ Jésíbẹ́lì àti ìdílé ẹ̀ torí ohun tí wọ́n ṣe.

      Jéhù gbéra, ó gun kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ lọ sí Jésírẹ́lì níbi tí Jésíbẹ́lì ń gbé. Nígbà tí Jèhórámù rí Jéhù lọ́ọ̀ọ́kán, òun náà gun kẹ̀kẹ́ ogun wá pàdé ẹ̀, ó sì bi Jéhù pé: ‘Ṣé àlàáfíà ni?’ Jéhù dáhùn pé: ‘Kò sí àlàáfíà torí pé Jésíbẹ́lì ìyá ẹ ṣì ń hùwà burúkú ẹ̀ lọ.’ Bí Jèhórámù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó yí pa dà, ó fẹ́ sá lọ. Àmọ́, Jéhù ta ọfà lu Jèhórámù, ó sì kú.

      Jéhù ní kí wọ́n ju Jésíbẹ́lì sísàlẹ̀

      Lẹ́yìn náà, Jéhù forí lé ààfin, nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé Jéhù ń bọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ojú ẹ̀ lóge, ó tún irun ẹ̀ ṣe. Ó wá dúró sójú wíńdò ẹ̀ lókè, torí pé ilé olókè ló ń gbé. Nígbà tí Jéhù dé, Jésíbẹ́lì fìbínú kí i káàbọ̀. Jéhù sì pàṣe fáwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésíbẹ́lì pé: “Ẹ gbé e, kẹ́ ẹ sì jù ú sísàlẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ náà gbé Jésíbẹ́lì, wọ́n sì tì í ṣubú látojú wíńdò, ó jábọ́ sísàlẹ̀, ó sì kú.

      Jéhù tún rí àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áhábù, ó sì pa wọ́n kó lè mú ìjọsìn òrìṣà Báálì kúrò pátápátá. Ṣéwọ náà ti rí i pé Jèhófà mọ ohun gbogbo, tó bá tó àkókò lójú ẹ̀, ó máa fìyà jẹ gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú?

      “Ogún téèyàn bá fi ojúkòkòrò gbà níbẹ̀rẹ̀ kì í ní ìbùkún lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”​—Òwe 20:21

      Ìbéèrè: Kí ni Jésíbẹ́lì ṣe tó fi gba ọgbà Nábótì fún Áhábù? Kí nìdí tí Jèhófà fi fìyà jẹ Jésíbẹ́lì?

      1 Àwọn Ọba 21:1-29; 2 Àwọn Ọba 9:1–10:30

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́