ORIN 107
Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa
1. Àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Jèhófà kọ́ wa
Ló yẹ ká máa tẹ̀ lé.
Gbogbo ‘hun tó ṣe fẹ̀rí hàn pó fẹ́ wa,
Ká fara wé e; ká fìfẹ́ hàn.
Ó fún wa lọ́mọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo;
Ó kú fẹ́ṣẹ̀ wa kí a lè rí ìyè.
Kò sóhun tá a lè fi wé ìfẹ́ ńlá yìí!
Ìfẹ́ yìí ga; Bàbá nífẹ̀ẹ́ wa.
2. Tá a bá fara wé e, ìfẹ́ wa yóò jinlẹ̀,
Yóò máa tuni lára.
Yóò jẹ́ ká lè máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo
Ẹgbẹ́ ará, tàgbà tèwe.
Ó ṣe pàtàkì ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,
Ká sì tún rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa.
Yóò jẹ́ ká lè máa dárí ji ara wa;
Ìyẹn fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ tòótọ́.
3. Ìfẹ́ òtítọ́ tá a ní ló so wá pọ̀
Bí ọmọ ìyá kan.
Bàbá wa ọ̀run fìfẹ́ ké sí wa pé:
“Tọ́ ọ wò kóo rí ìfẹ́ tòótọ́.”
Ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtẹ̀mí mímọ́ rẹ̀
Ṣèrànwọ́ fún wa, ká lè wà níṣọ̀kan.
Ìfẹ́ àárín wa sì ń rán wa létí pé
Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́.
(Tún wo Róòmù 12:10; Éfé. 4:3; 2 Pét. 1:7.)