LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
Ohun Tó Dáa Jù Ni Wọ́n Fi Ránṣẹ́
Ogun Àgbáyé Kejì ṣọṣẹ́ gan-an lórílẹ̀-èdè Jámánì. Nígbà tí ogun náà fi máa parí lọ́dún 1945, ọ̀pọ̀ ìlú ló ti pa run, àwọn ọmọ iléèwé ò lọ iléèwé mọ́, ilé ìwòsàn ò sì ṣeé lò. Ṣe ni bọ́ǹbù wà nílẹ̀ káàkiri. Yàtọ̀ síyẹn, oúnjẹ wọ́n gan-an, ìyẹn ò jẹ́ káwọn èèyàn rí oúnjẹ rà. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá fẹ́ ra bọ́tà ìlàjì kílò lọ́dọ̀ àwọn tó ń ta ọjà fàyàwọ́, iye tó máa san á tó owó iṣẹ́ oṣù kan ààbọ̀!
Ràbọ̀ràbọ̀ ogun náà kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ sẹ́wọ̀n, táwọn aláṣẹ sì rán lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Wọ́n dá wọn sílẹ̀ lọ́dún 1945, àmọ́ wọn ò rí nǹkan kan mú kúrò lẹ́wọ̀n yàtọ̀ sí aṣọ ẹlẹ́wọ̀n tó wà lọ́rùn wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì pàdánù àwọn ohun ìní wọn. Ebi han àwọn míì léèmọ̀ débi pé ṣe ni wọ́n máa ń dákú tí wọ́n bá wà nípàdé.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àwọn Ilẹ̀ Míì Tètè Dìde Ìrànwọ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì yára dìde ìrànwọ́ láti pèsè oúnjẹ àti aṣọ fáwọn ará. Àwọn ará tó wà ní oríléeṣẹ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì Switzerland tó wà nílùú Bern ran àwọn ará tó wà ní Jámánì lọ́wọ́. Nathan H. Knorr, tó jẹ́ aṣojú oríléeṣẹ́, rìnrìn àjò lọ sílẹ̀ Yúróòpù kó lè lọ ṣètò báwọn ará tí ọ̀rọ̀ kàn ṣe máa rí ìrànwọ́ gbà láìjáfara.
Arákùnrin Nathan H. Knorr ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ nílùú Wiesbaden, ní Jámánì lọ́dún 1947. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yẹn lédè Jámánì ló wà lókè ẹ̀ yẹn, tó sọ pé: “Ẹ Yin Jèhófà, Gbogbo Ẹ̀yin Orílẹ̀-èdè”
Tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Switzerland fi kó oúnjẹ, aṣọ àti owó ránṣẹ́. Wọ́n kọ́kọ́ kó o ránṣẹ́ sílùú Bern, ibẹ̀ ni wọ́n ti ṣètò bó ṣe máa dé ilẹ̀ Jámánì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn ilẹ̀ míì bíi Sweden, Kánádà àti Amẹ́ríkà náà ṣèrànwọ́, kì í sì í ṣe àwọn ará tó wà ní Jámánì nìkan ló jàǹfààní ohun tí wọ́n ṣe yẹn, ó tún ṣàǹfààní fáwọn ará tó wà láwọn agbègbè míì nílẹ̀ Yúróòpù àti Éṣíà tí ogun náà ti jà.
Adùn Ló Ń Gbẹ̀yìn Ewúro
Láàárín oṣù mélòó kan, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Switzerland fi ọ̀pọ̀ nǹkan ránṣẹ́, bíi kọfí, mílíìkì, ṣúgà, àtàwọn oúnjẹ bí ìrẹsì àti àgbàdo, tó fi mọ́ èso gbígbẹ, ẹ̀fọ́, ẹran àti ẹja. Kódà, wọ́n tún fi owó ránṣẹ́.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Switzerland fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ ránṣẹ́, títí kan àwọn aṣọ òtútù, aṣọ obìnrin àti kóòtù táwọn ọkùnrin lè wọ̀. Ilé Ìṣọ́ January 15, 1946 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ohun tó dára jù lọ làwọn ará wa fi ránṣẹ́. Ká sòótọ́, nǹkan tí wọ́n yááfì kí wọ́n lè ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ará ní Jámánì kì í ṣe kékeré.”
Àwọn ará ní Switzerland tún fi bàtà tó tó ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ránṣẹ́, wọ́n sì ti kọ́kọ́ yẹ àwọn bàtà náà wò kí wọ́n lè rí i pé ó dáa kí wọ́n tó fi ránṣẹ́. Nígbà táwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà nílùú Wiesbaden ní Jámánì rí àwọn bàtà náà gbà, ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí i bí bàtà táwọn ará fi ránṣẹ́ ṣe dáa tó, tó sì tún jẹ́ oríṣiríṣi. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sọ pé: “Mi ò rò pé ilé ìtajà kankan wà ní Jámánì tó ní adúrú aṣọ àti bàtà tó jẹ́ ojúlówó tóyẹn.”
Àwọn ará ṣì ń fi nǹkan ránṣẹ́ títí di August 1948. Lápapọ̀, ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Switzerland fi ránṣẹ́ sí Jámánì lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) kìlógíráàmù. Bá a ṣe sọ ṣáájú, kì í ṣe àwọn ará wa tó wà ní Switzerland nìkan ló ń fi nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́. Kódà, àwọn ará tó wà ní Switzerland ló kéré jù nínú àwọn tó ń fi nǹkan ránṣẹ́, torí nígbà yẹn, wọn ò ju ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) lọ!
‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Wà Láàárín Yín’
Jésù Kristi sọ pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Ìfẹ́ ló mú kí àwọn èèyàn Jèhófà fi ohun tó dáa jù nínú ohun tí wọ́n ní ránṣẹ́ sáwọn ará wọn. (2 Kọ́ríńtì 8:1-4) Lẹ́tà kan tá a rí gbà láti ìlú Zurich sọ pé “bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará wa kan wà tí ò ní lọ́wọ́, síbẹ̀ ó wu àwọn náà láti ṣèrànwọ́, torí náà wọ́n fi owó àti káàdì tí wọ́n fi ń rajà ní ẹ̀dínwó ránṣẹ́.”
Kò pẹ́ rárá tí ràbọ̀ràbọ̀ ogun náà fi tán lára àwọn èèyàn Jèhófà nílẹ̀ Jámánì, tí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ inúnibíni. Ọ̀kan lára ohun tó jẹ́ kó ṣeé ṣe ni ètò ìrànwọ́ tó mọ́yán lórí táwọn ará ṣe àti ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn tí wọ́n ní, tó mú kí wọ́n dìde ìrànwọ́ lọ́tùn-ún lósì.