ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 4 ojú ìwé 10-11
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀
  • Jí!—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
  • OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • Báwo Ni Mo Ṣe Ní Ìforítì Tó?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìforítì
    Jí!—2019
  • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | MÁ ṢE JẸ́ KÁYÉ SÚ Ẹ 1 Torí Pé Nǹkan Máa Ń Yí Pa Dà
    Jí!—2014
  • Wà Lójúfò Kó O sì Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 4 ojú ìwé 10-11
Ojú ń ro obìnrin kan bí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe ń kó lọ

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

  • Dádì rẹ ríṣẹ́ sí ibòmíì, ó sì gba pé kẹ́ ẹ kó kúrò níbi tẹ́ ẹ̀ ń gbé báyìí.

  • Ọ̀rẹ́ rẹ fẹ́ kó lọ sí àdúgbò míì tó jìnnà.

  • Ẹ̀gbọ́n rẹ fẹ́ kó kúrò nílé torí pé ó fẹ́ ṣègbéyàwó.

Kí lo lè ṣe kí àwọn àyípadà yìí lè bá ẹ lára mu?

Atẹ́gùn tẹ igi kan sẹ́bẹ̀ẹ́

Igi tó bá lè fì sọ́tùn-ún fì sósì nígbà tí atẹ́gùn bá ń fẹ́, tí ìjì bá jà, igi náà lè máà wó. Bí àyípadà bá wáyé tí kò sì sí ohun tó o lè ṣe sí i, ohun tó kàn ni pé kó o mú kí àyípadà náà bá ẹ lára mu, bíi ti igi yẹn. Ká tó sọ ohun tó o lè ṣe, ó yẹ ká mọ nǹkan kan nípa àyípadà.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Àyípadà gbọ́dọ̀ wáyé. Bíbélì sọ ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn, ó ní: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Bó pẹ́ bó yá, ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn àyípadà náà ló máa ń burú. Àwọn àyípadà kan lè kọ́kọ́ dà bí ohun tó burú, àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó lè ṣe wá láǹfààní. Àwọn kan máa ń gbádùn ohun tí wọ́n ń ṣe déédéé, àmọ́ nǹkan máa ń nira fún wọn tí àyípadà bá wáyé, yálà àyípadà rere tàbí búburú.

Àyípadà máa ń mú kí nǹkan tojú sú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Kí nìdí? Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alexa sọ pé: “O ò tíì yanjú àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara rẹ, tí àwọn ohun míì tí o kò rò tẹ́lẹ̀ tún wá dá kún un.”

Ìdí míì rèé: Bí àyípadà bá dé bá àgbàlagbà, wọ́n máa ń ronú pa dà sẹ́yìn láti mọ bí wọ́n ṣe bójú tó o nígbà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ kò ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀.

O lè mú kí ipò náà bá ẹ lára mu. Èyí gba pé kó o fara mọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, kó o sì gbé e kúrò lọ́kàn. Nípa bẹ́ẹ̀ wàá lè fara da ipò tuntun tó o wà báyìí, wàá sì tún ronú nípa àǹfààní tó máa tìdí ẹ̀ yọ. Àwọn ọ̀dọ́ tó bá nírú èrò yìí kì í lo oògùn olóró tàbí mu ọtí àmujù láti fi pa ìrònú rẹ́.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Gba kámú. Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ pé kí gbogbo nǹkan máa lọ bó o ṣe fẹ́, àmọ́ ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Torí pé bó pẹ́ bó yá, ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ kò ní jọ wà níbì kan náà mọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àwọn àbúrò rẹ á kúrò nílé, ipò nǹkan sì lè mú kí ìdílé yín kó kúrò níbi tẹ́ ẹ̀ ń gbé, wàá sì fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sílẹ̀. Dípò tí wàá fi jẹ́ kí àwọn nǹkan yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, ó máa dáa kó o fara mọ́ bí nǹkan ṣe rí.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 7:10.

Iwájú ni kó o máa lọ. Tó o bá n ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń wà mọ́tò lọ àmọ́ tó kàn tẹ́jú mọ́ gíláàsì tí wọ́n fi ń wò ẹ̀yìn. Kò burú tó bá ń wẹ̀yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ iwájú tó ń lọ ló yẹ kó gbájú mọ́. Nǹkan tó yẹ kéèyàn ṣe náà nìyẹn bí àyípadà bá ṣẹlẹ̀ láìrò tẹ́lẹ̀. Bí ọjọ́ iwájú ṣé máa dáa ni kó o máa rò. (Òwe 4:25) Bí àpẹẹrẹ, o lè bí ara rẹ pé kí ni nǹkan tó dáa tí mo lè ṣe ní oṣù kan tàbí oṣù mẹ́fà sí àkókò yìí?

Ohun tó dáa ni kó o máa rò. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Laura sọ pé: “Ọkàn téèyàn bá fi gbà àyípadà ló ṣe pàtàkì jù, torí náà ohun tó dáa nípa àyípadà náà ni kó o máa rò.” Ṣé o lè sọ àǹfààní kan tí ipò tuntun tó o wà mú wá?—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 6:9.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Victoria rántí pé nígbà tí òun ṣì wà ní ọ̀dọ́, gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ òun ló kó lọ tán. Ó ní: “Àárò wọ́n sọ mí gan-an, ó ń sẹ́ mí bíi pé kí nǹkan ṣì rí bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí mo ronú pa dà sẹ́yìn, mo ṣàkíyèsí pé àsìkò yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í jára nù. Mo wá rí i pé àyípadà gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ bá a ṣe ń dàgbà. Ìgbà yẹn náà ni mo wá rí i pé á dáa kí n bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn tó wà nítòsí mi lọ́rẹ̀ẹ́.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 27:10.

Tó o bá n ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń wà mọ́tò lọ àmọ́ tó kàn tẹ́jú mọ́ gíláàsì tí wọ́n fi ń wò ẹ̀yìn

Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Ohun kan tó lè mára tù ẹ́ kúrò nínú ìṣòro rẹ ni pé kó o máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Anna tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Bí mo ṣe ń dàgbà sí i, mo rí i pé inú mi máa ń dùn tí mo bá ń ran àwọn èèyàn tó ní irú ìṣòro tí mo ní lọ́wọ́ tàbí èyí tó tiẹ̀ le ju tèmi lọ!”

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

FI ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN

  • “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’”​—Oníwàásù 7:10.

  • “Fífi ojú rí sàn ju kí ọkàn máa rìn káàkiri.”​—Oníwàásù 6:9.

  • “Aládùúgbò tí ó wà nítòsí sàn ju arákùnrin tí ó jìnnà réré.”​—Òwe 27:10.

Juan

JUAN

“Àwọn ọ̀dọ́ lè fara mọ́ àyípadà tó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn tí wọ́n bá gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò, tí wọ́n sì rí i pé àyípadà gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ bá a ṣe ń dàgbà. Bó o bá gbà pé kò sí ohun tó o lè ṣe tí àyípadà bá wáyé, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o kárí sọ. Máa rántí pé nǹkan ṣì máa wá dáa ju bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ.”

Carissa

CARISSA

“Tí mo bá ti borí ìṣòro kan, mi ò tún ń ronú ńpa ẹ̀ mọ́. Màá sì gbájú mọ́ ohun tó kàn nígbèésí ayé mi. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn máa ronú nípa ọjọ́ iwájú dípò táá fi jẹ́ kí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá gba òun lọ́kàn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́