-
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ SíÀwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
-
-
ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí
Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré ló máa ń ṣèrìbọmi. Ṣé ìwọ náà ti ń ronú láti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi túmọ̀ sí.
Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí?
Nínú Bíbélì, ìrìbọmi túmọ̀ sí ríri èèyàn bọ inú omi pátápátá, kì í ṣe wíwọ́n omi séèyàn lára. Bí wọ́n sì ṣe ri ẹni náà bọ inú omi yẹn ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì gan-an.
Bí wọ́n ṣe ri ẹni náà bọnú omi nígbà ìrìbọmi fi hàn pé, ẹni náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò tún ní gbé ìgbésí ayé òun láti ṣe ohun tó wu òun mọ́.
Bí wọ́n ṣe gbé ẹni náà sókè nínú omi fi hàn pé ẹni náà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun, ní ti pé bó ṣe máa ṣe ohun tó mú inú Ọlọ́run dùn ló gbájú mọ́.
Tó o bá ṣèrìbọmi, ṣe lò ń jẹ́ kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé Jèhófà ló láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, o sì ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ ni wàá máa ṣe láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni fipá mú ẹ.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tó o fi fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé o fẹ́ máa ṣègbọràn sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ? Wo 1 Jòhánù 4:19 àti Ìfihàn 4:11.
Kí ni ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí?
Kó o tó ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Báwo lo ṣe máa ṣe é?
Gbàdúrà sí Jèhófà níwọ nìkan, ṣèlérí fún un pé títí ayé ni wàá máa sìn ín, wàá sì ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ kó o ṣe láìka ohun táwọn ẹlòmíì bá ṣe tàbí ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí.
Ìrìbọmi lo fi ń sọ fáwọn èèyàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìyẹn sì máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìwọ kọ́ lo ni ara rẹ mọ́ àti pé Jèhófà ló ni ẹ́.—Mátíù 16:24.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tí ayé ẹ fi máa dáa sí i tó bá jẹ́ pé Jèhófà ló ni ẹ́? Wo Àìsáyà 48:17, 18 àti Hébérù 11:6.
Kí nìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì?
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣèrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, àìgbọ́dọ̀máṣe ni ìrìbọmi jẹ́ fáwọn Kristẹni. Kódà, Bíbélì sọ pé ó ṣe pàtàkì ká ṣèrìbọmi ká tó lè rí ìgbàlà.—1 Pétérù 3:21.
Àmọ́, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú kó o ṣèrìbọmi. Ó yẹ kí èrò tìẹ náà rí bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi? . . . Màá ké pe orúkọ Jèhófà. Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà.”—Sáàmù 116:12-14.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Oore wo ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ, báwo lo sì ṣe lè san án pa dà fún un? Wo Diutarónómì 10:12, 13 àti Róòmù 12:1.
-
-
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún ÌrìbọmiÀwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
-
-
ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi
Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tó o sì ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, ó dájú pé wàá tí máa ronú nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Àmọ́, báwo lo ṣe máa mọ̀ pé o ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?a
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Báwo ni nǹkan tí mo mọ̀ ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó?
Tó o bá ń múra láti ṣèrìbọmi, kò pọn dandan kó o máa há ohun tó ò ń kọ́ sórí bí ìgbà tó ò ń múra ìdánwò nílé ìwé. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ lo “agbára ìrònú” rẹ kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé òtítọ́ làwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì. (Róòmù 12:1) Bí àpẹẹrẹ:
Ṣé ó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà àti pé òun ló yẹ kó o máa sìn?
Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.”—Hébérù 11:6.
Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló mú kí n gba Ọlọ́run gbọ́?’ (Hébérù 3:4) ‘Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun ló yẹ kí n máa sìn?’—Ìfihàn 4:11.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 1: Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run wà?”
Ṣé ó dá ẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì lóòótọ́?
Bíbélì sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò fún kíkọ́ni, fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́, fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo”—2 Tímótì 3:16.
Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló mú kí n gbà pé èrò èèyàn kọ́ ló wà nínú Bíbélì?’—Àìsáyà 46:10; 1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kìíní: Wo Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì.”
Ṣé ó dá ẹ lójú pé ìjọ Kristẹni ni Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?
Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ àti nípasẹ̀ Kristi Jésù títí dé gbogbo ìran láé àti láéláé.”—Éfésù 3:21.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn nǹkan tá à ń gbọ́ láwọn ìpàdé Kristẹni ti ń wá, kì í ṣe ọ̀dọ̀ èèyàn?’ (Mátíù 24:45) ‘Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé, kódà táwọn òbí mi ò bá lè lọ (tí wọ́n bá gbà ẹ́ láyè láti máa lọ)?’—Hébérù 10:24, 25.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?”
Kí ló yẹ kí n máa ṣe?
Kò dìgbà tó o bá di ẹni tó pé kó o tó lè ṣèrìbọmi. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o fẹ́ “jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere” (Sáàmù 34:14) Bí àpẹẹrẹ:
Ṣé o máa ń fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésì ayé rẹ?
Bíbélì sọ pé: “Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn rere”—1 Pétérù 3:16.
Bi ara ẹ pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni mo ti ṣe tó fi hàn pé mo ti “kọ́ agbára ìfòyemọ̀” mi, kí n lè máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́”?’ (Hébérù 5:14) ‘Ṣé mo lè rántí àwọn ìgbà kan táwọn ojúgbà mi fẹ́ kí n ṣe ohun tí ò dáa, àmọ́ tí mo kọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́? Ṣé àwọn tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́ ni mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́?’—Òwe 13:20.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?”
Ṣé o mọ̀ pé gbogbo ohun tó o bá ṣe lo máa jíhìn fún Jèhófà?
Bíbélì sọ pé: “Kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run”—Róòmù 14:12.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í tan ara mi jẹ, ṣe mo sì jẹ́ olóòótọ́ nínú àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn èèyàn?’ (Hébérù 13:18) ‘Tí mo bá ṣe ohun tí ò dáa, ṣé mo máa ń gbà pé mo jẹ̀bi, ṣé kì í ṣe pé mo máa ń dọ́gbọ́n bo ohun tí mo ṣe mọ́lẹ̀ àbí kí n di ẹ̀bi ẹ̀ ru àwọn ẹlòmíì?’—Òwe 28:13.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Mo Lè Ṣe Nípa Àwọn Àṣìṣe Mi?”
Ṣé ò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín”—Jémíìsì 4:8
Bi ara ẹ pé: ‘Kí làwọn nǹkan tí mò ń ṣe kí n lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ Bí àpẹẹrẹ, ‘Ṣé mo máa ń ka Bíbélì déédéé?’ (Sáàmù 1:1, 2) ‘Ṣé mo máa ń gbàdúrà déédéé?’ (1 Tẹsalóníkà 5:17) ‘Tí mo bá ń gbàdúrà, ṣé mo máa ń sọ àwọn nǹkan pàtó tí mo fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún mi? Ṣé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni mò ń bá ṣọ̀rẹ́?’—Sáàmù 15:1, 4.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kejì: Jẹ́ Kí Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ” àti “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?”
ÀBÁ: Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi, ka orí 37 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 2. Ní pàtàkì wo àpótí tá a pè ní “Ṣó O Ti Ń Ronú Láti Ṣèrìbọmi?” tó wà lójú ìwé 308 sí 309.
a Kó o lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara ẹ sí mímọ́ kó o sì ṣèrìbọmi àti ìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 1.”
-
-
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 3: Kí Ló Ń Dá Mi Dúró?Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
-
-
ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 3: Kí Ló Ń Dá Mi Dúró?
Ṣé ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ìbẹ̀rù ẹ.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Tí mo bá lọ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn ìrìbọmi ńkọ́?
Kí ló lè mú kó o ronú bẹ́ẹ̀: Ó ṣeé ṣe kó o mọ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n sì yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà.
“Ṣe lẹ̀rù ń bà mí pé màá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn tí mo bá ṣèrìbọmi. Ọkàn mi ò balẹ̀ torí mo mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa kó ìtìjú bá àwọn òbí mi gan-an.”—Rebekah.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ . . . Kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀, sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, torí ó máa dárí jini fàlàlà.”—Àìsáyà 55:7.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò bá ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ, Jèhófà máa ń ṣàánú àwọn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì gba ìbáwí tí wọ́n bá fún wọn.—Sáàmù 103:13, 14; 2 Kọ́ríńtì 7:11.
Ohun kan ni pé: Bó o tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, o lè borí ìdẹwò tó o bá gbára lé Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ó ṣe tán, ìwọ fúnra ẹ lo máa pinnu ohun tó o máa ṣe, kì í ṣe ẹlòmíì.
“Ṣe lẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí pé mo lè ṣàṣìṣe lẹ́yìn tí mo bá ṣèrìbọmi, àmọ́ mo wá rí i pé àṣìṣe ńlá ló máa jẹ́ tí mo bá fà sẹ́yìn láti ṣèrìbomi. Àti pé kò yẹ kí n jẹ́ káwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú dí mi lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́ nísinsìnyí.”—Karen.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Bíi ti ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà, o lè borí ìdẹwò èyíkéyìí tó o bá pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Fílípì 2:12.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?”
Tó bá jẹ́ pé ojúṣe tí mo máa ní lẹ́yìn ìrìbọmi ló ń bà mí lẹ́rù ńkọ́?
Kí ló lè mú kó o ronú bẹ́ẹ̀: Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ti fi tẹbítọ̀rẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì kó lọ síbi tó jìnnà torí àtiṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. O wá ń ṣàníyàn pé àwọn èèyàn lè máa retí pé kíwọ náà gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
“Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn Kristẹni tó bá ti ṣèrìbọmi máa ń ní láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, àmọ́ àwọn kan ò ṣe tán láti yọ̀ǹda ara wọn tàbí kó jẹ́ pé ipò wọn ò fàyè gbà wọ́n.”—Marie.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”—Gálátíà 6:4.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Dípò tí wàá fi máa fi ara ẹ wé àwọn míì, á dáa kó o ronú lórí ohun tó wà nínú Máàkù 12:30 tó sọ pé: ‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.’
Kíyè sí pé ó yẹ kó o sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn ẹ, kì í ṣe ti ẹlòmíì. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀.
“Òótọ́ ni pé ìrìbọmi kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré, síbẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira. Tó bá jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ gidi lò ń bá kẹ́gbẹ́, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá nílò wọn. Tó o bá wá láǹfààní iṣẹ́ ìsìn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wàá láyọ̀ gan-an. Àmọ́ tó o bá ń sá láti ṣèrìbọmi, ara ẹ lò ń ṣe.”—Julia.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí ẹ, ìyẹn á mú kó wù ẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe fún un.—1 Jòhánù 4:19.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo “How Responsible Am I?” lédè Gẹ̀ẹ́sì
Tó bá ń ṣe mí bíi pé kì í ṣe irú mi ló ń sin Jèhófà ńkọ́?
Kí ló lè mú kó o ronú bẹ́ẹ̀: Àwa èèyàn kéré gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Torí náà, o lè máa ronú pé bóyá ni Jèhófà rí tìẹ rò.
“Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi, ó ń ṣe mí bíi pé mo ‘jogún’ àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà látọ̀dọ̀ wọn àti pé Jèhófà ò dìídì fà mí sọ́dọ̀ rẹ̀.”—Natalie.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á.”—Jòhánù 6:44.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ti pé ò ń ronú nípa ìrìbọmi fi hàn pé Jèhófà ń fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀, ó sì fẹ́ kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Torí náà, ṣé kò ní dáa kíwọ náà gbé ìgbésẹ̀ kó o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀?
Má gbàgbé pé Jèhófà ló ń pinnu ẹni tóun máa fà sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kì í ṣe ìwọ tàbí ẹlòmíì. Bíbélì sì jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá ‘sún mọ́ Ọlọ́run, òun náà á sún mọ́ wa.’—Jémíìsì 4:8.
“Ti pé o mọ Jèhófà àti pé ó fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò yẹ lẹ́ni tó ń sìn ín, rántí pé ojú yẹn kọ́ ni Jèhófà fi ń wò ẹ́. Ojú tí Jèhófà fi ń wò ẹ́ ló sì ṣe pàtàkì jù.”—Selina.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá ti ń ṣe àwọn ohun tí Bíbélì ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi, á jẹ́ pé o kúnjú ìwọ̀n láti sin Jèhófà nìyẹn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà lẹni tó yẹ kó o máa sìn.—Ìfihàn 4:11.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?”
-