Àníyàn
Ṣé ò ń ṣàníyàn torí pé o ò lówó lọ́wọ́, o ò rí oúnjẹ jẹ tàbí torí pé o ò rílé gbé?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Ida 3:19—Lẹ́yìn tí wọ́n pa ìlú Jerúsálẹ́mù run, kò síbi tí wòlíì Jeremáyà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù á máa gbé
2Kọ 8:1, 2; 11:27—Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé òtòṣì paraku làwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì wà láìsí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
Tún wo Di 24:19
Ṣé ò ń ṣàníyàn torí pé o ò lọ́rẹ̀ẹ́, torí pé o dá wà tàbí torí pé àwọn èèyàn ò fẹ́ràn ẹ?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Ọb 18:22; 19:9, 10—Ìgbà kan wà tí wòlíì Èlíjà ń ṣàníyàn torí ó gbà pé òun nìkan ni ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì
Jer 15:16-21—Nígbà tí wòlíì Jeremáyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, wọn ò tẹ́tí sí i, ṣe ni wọ́n ń ṣàríyá. Ìyẹn sì mú kó máa ṣe wòlíì náà bíi pé òun dá wà
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tù wá nínú:
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó lè tù wá nínú:
1Ọb 19:1-19—Jèhófà fún wòlíì Èlíjà ní oúnjẹ àti omi, ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ó tún jẹ́ kó mọ̀ pé òun lágbára láti ràn án lọ́wọ́
Jo 16:32, 33—Jésù mọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun máa pa òun tì, àmọ́ kò ṣàníyàn torí ó dá a lójú pé Jèhófà máa dúró ti òun