ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/15 ojú ìwé 32
  • Ibo ni Wọ́n Ti Rí Okun Wọn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo ni Wọ́n Ti Rí Okun Wọn?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/15 ojú ìwé 32

Ibo ni Wọ́n Ti Rí Okun Wọn?

BÍ O bá wo labalábá tí ó wà nínú fọ́tò yìí ní àwòfín, ìwọ yóò rí i pé ọ̀kan nínú àwọn ìyẹ́ mẹ́rin tí ó ní kò wúlò rárá. Síbẹ̀, labalábá náà ń bá a nìṣó láti máa jẹun, ó sì ń fò. Èyí kì í ṣe ohun tí ojú kò rí rí. A ti ṣàkíyèsí pé àwọn labalábá máa ń bá ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ wọn nìṣó nígbà tí wọ́n bá sọ ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ìyẹ́ wọn nù.

Lọ́nà jíjọra, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń mú ẹ̀mí ìdúróṣinṣin dàgbà. Láìka jíjìyà láti ọwọ́ àwọn ìṣòro nípa ti ara àti ti èrò ìmọ̀lára sí, wọn kò juwọ́ sílẹ̀.—Fi wé 2 Korinti 4:16.

Aposteli Paulu fúnra rẹ̀ fara da ìnira ńláǹlà nígbà àwọn ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. A nà án lọ́rẹ́, a lù ú, a sọ ọ́ lókùúta, a sì fi í sẹ́wọ̀n. Ní àfikún sí i, ó jìyà irú àrùn ara kan, bóyá ìṣòro ojú rẹ̀, tí ó jẹ́ “ẹ̀gún kan . . . ninu ẹran-ara” fún un.—2 Korinti 12:7-9; Galatia 4:15.

Kristian alàgbà kan tí ń jẹ́ David, tí ó jìjàkadì pẹ̀lú ìsoríkọ́ ńláǹlà fún ọ̀pọ̀ ọdún, gbà gbọ́ pé okun Jehofa ṣe pàtàkì fún ìkọ́fẹpadà. Ó ṣàlàyé pé: “Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó dà bíi pé ìtẹ̀síwájú tí ó nira láti rí lè pòórá. Nígbà tí irú ìrẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, mo gbé ara mi lé Jehofa, ó sì mú mi dúró ní tòótọ́. Àwọn àkókò kan wà tí mo gbàdúrà fún ọ̀pọ̀ wákàtí lẹ́ẹ̀kan. Nígbà tí mo bá Jehofa sọ̀rọ̀, ìmọ̀lára ìdánìkanwà àti àìjámọ́ nǹkan kan mi pòórá. Mo ti jìjàkadì la àwọn sáà àìlera ńláǹlà já, ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Jehofa pé, okun ti inú àìlera náà wá—àní okun láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.”

Jehofa Ọlọrun fún Paulu lókun. Nítorí náà, ó lè sọ pé: “Nígbà tí emi bá jẹ́ aláìlera, nígbà naa ni mo di alágbára.” (2 Korinti 12:10) Bẹ́ẹ̀ ni, ìlera Paulu kọ́ ọ láti gbára lé okun tí Ọlọrun ń fúnni. Aposteli náà sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni naa tí ń fi agbára fún mi.” (Filippi 4:13) Dájúdájú, Jehofa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́