ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 1: Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run wà?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
    • Ọ̀dọ́ kan ń ṣàlàyé ìdí tó fi gbà pé Ọlọ́run wà fún akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀

      ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

      Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 1: Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run wà?

      • Ṣé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá kan wà?

      • Kí nìdí tí mo fi gbà pé Ọlọ́run wà?

      • Bí mo ṣe lè ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́

      Ṣé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá kan wà?

      Ṣé o gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo? Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé kì í ṣe ìwọ nìkan, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ náà ló gbà bẹ́ẹ̀ (títí kan àwọn tó ti dàgbà). Àmọ́ àwọn kan sọ pé ṣe ni àgbáálá ayé àtàwọn ohun alààyè ṣàdédé wà láìsí Ẹlẹ́dàá kankan tàbí Ẹni Gíga Jù Lọ tó dá wọn.

      Ǹjẹ́ o mọ̀? Lọ́pọ̀ ìgbà táwọn tí èrò wọn yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ yìí bá ń jiyàn, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló máa ń yá wọn lára láti sọ, kódà bí wọn ò tiẹ̀ mọ ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́.

      • Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo torí ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn ní ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn.

      • Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ohun alààyè kàn ṣàdédé wà ni, torí pé ohun tí wọ́n kọ́ wọn níléèwé nìyẹn.

      Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá lágbára sí i, wà á sì lè ṣàlàyé ìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó yẹ kó o kọ́kọ́ bi ara rẹ ní ìbéèrè pàtàkì kan:

      Kí nìdí tí mo fi gbà pé Ọlọ́run wà?

      Kí nìdí tí ìbéèrè yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ, ìyẹn ni pé kó o má a ronú jinlẹ̀. (Róòmù 12:1) Èyí túmọ̀ sí pé ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run wà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ torí

      • ohun tó o kàn rò (Mo kàn ronú pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tí agbára rẹ̀ ju ti ẹnikẹ́ni lọ)

      • ohun táwọn ẹlòmíì ń ṣe (Àárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ìsìn ni mò ń gbé)

      • pohun tí wọ́n fi kọ́ ẹ (Láti kékeré làwọn tó tọ́ mi dàgbà ti kọ́ mi láti gbà pé Ọlọ́run wà)

      Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó dá ìwọ fúnra rẹ lójú pé Ọlọ́run wà, ó sì yẹ kó o ní ìdí pàtàkì tó o fi gbà bẹ́ẹ̀.

      Torí náà, kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà? Apá tá a pè ní ibi tí mo kọ èrò mi sí, tó ní àkòrí náà “Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbà Pé Ọlọ́run Wà?” máa mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú. Tó o bá tún wo ohun táwọn ọ̀dọ́ míì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

      “Tí mo bá wà ní kíláàsì tí mò ń fetí sí olùkọ́ wa bó ṣe ń ṣàlàyé bí àwọn ẹ̀yà ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, ṣe ló túbọ̀ ń mú kó dá mi lójú pé Ọlọ́run wà. Ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ló ní iṣẹ́ tirẹ̀, àní títí dórí èyí tó kéré jù lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé a kìí mọ̀ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́. Ọ̀nà tí ara wa yìí ń gbà ṣiṣẹ́ kàmàmà lóòótọ́!”​—Teresa.

      “Tí mo bá rí ilé gogoro, ọkọ̀ òkun ńlá tí wọ́n fi ń gbafẹ́ tàbí mọ́tò, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ta ló kọ́ ilé yìí tàbí ta ló ṣe ọkọ̀ yìí?’ Bí àpẹẹrẹ, ó ní láti jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ní òye ló ṣe mọ́tò, torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan kéékèèké tó wà nínú rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí mọ́tò yẹn tó lè ṣiṣẹ́. Tó bá sì wá jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣe mọ́tò jáde, a jẹ́ pé ẹnì kan ló dá àwa èèyàn náà nìyẹn.”​—Richard.

      “Téèyàn bá mọ̀ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ló gba àwọn èèyàn tó ní òye jù lọ kí wọ́n tó lè lóye èyí tó kéré jù lára àwọn nǹkan tó wà ní àgbáálá ayé, kò ní bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti ronú pé ṣe ni àgbáálá ayé wa yìí kàn ṣàdédé wà láìsí onílàákàyè kan tó dá a.”​—Karen.

      “Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń hàn sí mi pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, mo ronú nípa bí ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ṣe wà lójú ibi tó yẹ kí wọ́n wà gẹ́lẹ́, tí wọ́n sì wà létòlétò, bí ẹ̀dá èèyàn ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀, títí kan bó ṣe máa ń wù wá láti mọ irú ẹni tá a jẹ́, bá a ṣe dáyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Àwọn tó ṣagbátẹrù ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti gbìyànjú láti fi àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko ṣàlàyé àwọn nǹkan yìí, àmọ́ wọn ò lè ṣàlàyé ìdí tí èèyàn fi yàtọ̀ sí ẹranko. Lójú tèmi, ó rọrùn láti gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà ju kéèyàn gbà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́.”​—Anthony.

      Bí mo ṣe lè ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́

      Táwọn ọmọ kíláàsì rẹ bá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé o gba ohun tó ò lè rí gbọ́ ńkọ́? Tàbí kí lo máa sọ tí wọ́n bá ní ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fìdí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n múlẹ̀?

      Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ dá ẹ lọ́jú. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n kó ẹ láyà jẹ, má sì tijú. (Róòmù 1:​16) Rántí pé:

      1. Ìwọ nìkan kọ́ lo gbà pé Ọlọ́run wà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì gbà bẹ́ẹ̀. Kódà àwọn kan tí òye wọn jinlẹ̀, tí wọ́n sì ní ìmọ̀ ìwé wà lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé Ọlọ́run wà.

      2. Nígbà míì táwọn èèyàn kan bá sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé àwọn ò rí ohun tó wà fún. Dípò kí wọ́n fi ẹ̀rí ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lẹ́yìn, ṣe ni wọ́n máa ń ṣe lámèyítọ́ pé, “Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà, kí ló dé tó fi gbà kí ìyà máa jẹ wá?” Nípa bẹ́ẹ̀, dípò kí wọ́n sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, bí nǹkan ṣe rí lára wọn ni wọ́n á máa sọ.

      3. Ó máa ń wu àwa èèyàn láti sin Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Èyí ló fà á tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run wà. Torí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò sí Ọlọ́run, òun fúnra rẹ̀ ló máa ṣàlàyé ìdí tó fi gbà bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ.​— Róòmù 1:​18-​20.

      4. Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run wà. Èyí bá òtítọ́ tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ mu pé kò sí ohun alààyè kankan tó kàn ṣàdédé wà. Kò sì sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ara àwọn ohun tí kò lẹ́mìí ni ohun alààyè ti wá.

      Kí lo máa wá sọ tẹ́nì kan bá sọ pé ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run wà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? Wo ohun to ṣeé ṣe káwọn kan sọ.

      Tẹ́nì kan bá sọ pé: “Àwọn tí ò kàwé nìkan ló gbà pé Ọlọ́run wà.”

      O lè sọ pé: “Ṣé o gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́? Èmi ò gbà bẹ́ẹ̀. Kódà, nígbà tí wọ́n bi èyí tó ju ẹgbẹ̀jọ [1,600] lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wà láwọn yunifásítì tó lórúkọ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ìdá mẹ́ta wọn ló gbà pé Ọlọ́run wà.a Ṣé wà á wá sọ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ò ní làákàyè torí pé wọ́n gbà pé Ọlọ́run wà?”

      Tẹ́nì kan bá sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà, kí ló dé tí ìyà tó pọ̀ báyìí fi ń jẹ wá?”

      O lè sọ pé: “Ṣé ohun tó o ní lọ́kàn ni pé ohun tí Ọlọ́run ń ṣe sí ìyà tó ń jẹ wá kò yé ẹ ni àbí ṣe lo rò pé kò rí nǹkan kan ṣe sí i? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo ti rí àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tó fà á tí ìyà fi pọ̀ láyé tó báyìí. Àmọ́, kéèyàn tó lè lóye ọ̀rọ̀ náà dáadáa, ó gba pé kó mọ àwọn ẹ̀kọ́ bíi mélòó kan nínú Bíbélì. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i?”

      Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká rí ìdí tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n kò fi lè ṣàlàyé bí a ṣe dé ayé lọ́nà tó ń tẹ́ni lọ́rùn.

      a Orísun: Ìwé “Religion and Spirituality Among University Scientists,” láti ọwọ́ Elaine Howard Ecklund. Ẹgbẹ́ Social Science Research Council ló tẹ̀ ẹ́ jáde ní February 5, ọdún 2007.

  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé—Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 2
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
    • Olùkọ́ ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama nípa ẹfolúṣọ̀n

      ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

      Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 2: Ṣé Ó Yẹ Kó O Kàn Gbà Pé Òótọ́ ni Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n?

      Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ Alex ń kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ nípa àwọn ohun alààyè, ó sì sọ fún wọn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n torí pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣèwádìí nípa ẹ̀, wọ́n sì ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni. Ọ̀rọ̀ yìí ṣe Alex bákan, torí ó gbà pé Ọlọ́run wà, òun ló sì dá gbogbo nǹkan. Àmọ́ Alex ò fẹ́ kó jẹ́ pé èrò tiẹ̀ nìkan ló yàtọ̀ nínú kíláàsì. Ó wá ń sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé, ‘Táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ti ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, tí wọ́n sì gbà pé òótọ́ ni, kí wá ni tèmi?’

      Ṣé irú nǹkan yẹn ti ṣe ẹ́ rí? Bóyá láti kékeré lo ti gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ pé: “Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ó lè wá jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ti ń gbìyànjú láti yí ẹ lérò pa dà pé ẹfolúṣọ̀n ló tọ̀nà, pé kò sí ẹlẹ́dàá kankan níbì kankan. Ṣé ó yẹ kó o gbà wọ́n gbọ́? Sé ó yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹfolúṣọ̀n?

      • Ìdí méjì tí kò fi yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n

      • Àwọn ìbéèrè tó o lè bi ara rẹ

      • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

      Ìdí méjì tí kò fi yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n

      1. Ẹnu àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò kò lórí ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, síbẹ̀, èrò wọn ò tíì ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

        Ronú nípa èyí: Tí ẹnu àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó pe ara wọn ní ọ̀jọ̀gbọ́n ò bá kò lórí ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n, ṣé ó wá yẹ kó o kàn gbà pé òótọ́ ni ẹfolúṣọ̀n?​—Sáàmù 10:4.

      2. Má kàn gba ohunkóhun gbọ́. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Zachary sọ pé, “Tó bá jẹ́ pé ṣe ni gbogbo nǹkan ṣàdédé wà, a jẹ́ pé ayé wa ò nítumọ̀ nìyẹn, títí kan gbogbo ohun tó wà lágbàáyé.” Òótọ́ kúkú lohun tó sọ. Àbí, ká ní òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ni, ìgbésí ayé ò ní nítumọ̀ kankan sí wa. (1 Kọ́ríńtì 15:32) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan, a lè rí ìdáhùn tó tẹ́ wa lọ́rùn sáwọn ìbéèrè tó ń jẹ wá lọ́kàn nípa ìdí tá a fi wà láyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.​—Jeremáyà 29:11.

        Ronú nípa èyí: Tó o bá mọ̀ bóyá òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n àbí ẹlẹ́dàá kan ló dá gbogbo nǹkan, ipa wo ló máa ní nígbèésí ayé ẹ?​—Hébérù 11:1.

      Àwọn ìbéèrè tó o lè bi ara rẹ

      OHUN TÁWỌN KAN SỌ: ‘Ṣe ni nǹkan ṣàdédé bú gbàù, gbogbo ohun tó wà lágbàáyé wá bẹ̀rẹ̀ sí í jáde.’

      • Tá ló mú kí nǹkan ọ̀hún bú gbàù?

      • Èwo ló bọ́gbọ́n mu nínú kí gbogbo nǹkan ṣàdédé wà àbí kó jẹ́ pé ohun kan tàbí ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan?

      OHUN TÁWỌN KAN SỌ: ‘Ẹranko ló di èèyàn.’

      • Tó bá jẹ́ pé ẹranko ló di èèyàn, ká fi ìnàkí ṣe àpẹẹrẹ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwa èèyàn gbọ́n ju àwọn ìnàkí lọ fíìfíì?a

      • Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn ohun alààyè tó “kéré jù” pàápàá máa ń yà wá lẹ́nu torí wọ́n díjú gan-an?b

      OHUN TÁWỌN KAN SỌ: ‘Wọ́n ti ṣèwádìí nípa ẹfolúṣọ̀n, wọ́n sì ti rí i pé òótọ́ ni.’

      • Ṣẹ́ni tó ń sọ̀rọ̀ yẹn ti ṣèwádìí fúnra ẹ̀?

      • Ṣé gbogbo èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ torí pé àwọn kan kàn sọ fún wọn pé gbogbo ẹni tí orí ẹ̀ pé ló gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n?

      OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

      Gwen

      Gwen

      “Ká sọ pé ẹnì kan sọ fún ẹ pé nǹkan kan bú gbàù lára ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan tó ń ṣiṣẹ́, yíǹkì sì fọ́n jáde sára ògiri àti òrùlé. Ni yíǹkì tó fọ́n jáde yẹn bá di ìwé atúmọ̀ èdè ńlá. Ṣé o máa gbà á gbọ́? Tẹ́nì kan bá wá sọ pé ohun kan ló bú gbàù, tó wá di gbogbo ohun tó wà lágbàáyé, àgbáyé tó jẹ́ pé ṣe ló wà létòlétò, ṣé ó ṣe é gbà gbọ́?”

      Jessica

      Jessica

      “Ó láwọn ohun tó yẹ ká ṣe ká lè máa wà láàyè, àmọ́ àwa èèyàn láwọn ànímọ́ kan tó mú ká yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń tọ́jú àwọn tó ń ṣàìsàn, a sì máa ń ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́. Tó bá jẹ́ pé ká ṣáà ti rí ayé gbé ló ṣe pàtàkì bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe sọ, kí ló wá dé tá a fi ń ṣe irú àwọn nǹkan rere bẹ́ẹ̀?”

      Julia

      Julia

      “Ká sọ pé lọ́jọ́ kan, ò ń lọ nínú igbó kan, o wá rí ilé kan tó rẹwà tí wọ́n fi pákó kọ́, kí ló máa wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé wàá sọ pé: ‘Ẹ̀n ẹ́n! Ó ní láti jẹ́ pé ṣe làwọn igi kan to ara wọn pọ̀, tó sì wá di ilé yìí.’ Ó dájú pé o ò ní sọ bẹ́ẹ̀! Kò tiẹ̀ mọ́gbọ́n dá ní. Ṣé ó wá yẹ ká gbà pé ṣe ni gbogbo ohun tó wà lágbàáyé kàn ṣàdédé wà?”

      a Àwọn kan lè sọ pé torí ọpọlọ èèyàn tóbi ju ti ìnàkí lọ ló jẹ́ ká gbọ́n jù wọ́n lọ. Àmọ́ tó o bá fẹ́ mọ ìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn ò fi lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, wo ìwé náà, The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, ojú ìwé 28.

      b Wo ìwé náà, The Origin of Life—Five Questions Worth Asking, ojú ìwé 8 sí 12.

  • Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
    • Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń wo àṣẹ́kù egungun ẹranko dinosaur níbi tí wọ́n ń kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí

      ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

      Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

      “Tó o bá gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, àwọn èèyàn á rò pé orí ẹ ò pé tàbí pé ńṣe lo kàn jẹ́ kí àwọn òbí ẹ kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ tí ò nítumọ̀. Wọ́n á máa fojú ọmọdé wò ẹ́ tàbí kí wọ́n máa fojú agbawèrèmẹ́sìn wò ẹ́.”​—Jeanette.

      Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jeanette náà ló ṣe rí lára tìẹ? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà ti lè máa ṣiyèméjì nípa ìṣẹ̀dá. Ó ṣe tán kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n máa fojú ẹni tí kò dákan mọ̀ wo òun. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

      • Ohun tó mú kí o má gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá

      • Ronú nípa ohun tí o gbà gbọ́

      • Àwọn ohun tó o lè fi ṣèwádìí ohun tó o gbà gbọ́

      • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

      Ohun tó mú kí o má gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá

      1. Tó o bá gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá àwọn èèyàn á sọ pé ò ń ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.

      “Olùkọ́ mi sọ pé àwọn tí kò lè ronú jinlẹ̀, tí wọn ò sì lè ṣàlàyé bí ayé ṣe wà àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ló máa gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo.”​—Maria.

      Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Nǹkan tí àwọn tó gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ kò yé wọn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó gbajúmọ̀ bíi Galileo àti Newton gbà gbọ́ pé ẹlẹ́dàá kan wà. Ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yìí kò ṣèdíwọ́ fún ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ní. Bákan náà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lóde òní gbà pé ìgbàgbọ́ nínú ẹlẹ́dàá kò ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.

      Gbìyànjú èyí wò: Tẹ ọ̀rọ̀ náà “ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́” tàbí “sọ ìdí tó fi gba Ọlọ́run gbọ́” (fi àmì àyọlò sí i) sínú àpótí tó o ti lè wá ọ̀rọ̀ jáde tó wà ní ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower, kó o lè ka àpẹẹrẹ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti onímọ̀ ìṣègùn tí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. Kíyè sí ohun tó mú kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀.

      Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kò túmọ̀ sí pé ò ń ta ko ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó o bá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. Kódà, bí o bá ṣe ń kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ni ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹlẹ́dàá á máa lágbára sí i.​—Róòmù 1:​20.

      2. Tó o bá gba ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo gbọ́, àwọn èèyàn á máa rò pé agbawèrèmẹ́sìn ni ẹ́.

      “Ẹ̀fẹ̀ làwọn èèyàn ka ìgbàgbọ́ nínú ìṣẹ̀dá sí. Wọ́n ka ohun tí Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa ìṣẹ̀dá sí ìtàn lásán.”​—Jasmine.

      Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Àwọn èèyàn máa ń ní èrò òdì nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá. Bi àpẹẹrẹ, àwọn kan gbà pé kò tíì pẹ́ tí Ọlọ́run dá ayé tàbí pé ọjọ́ oní wákàtí mẹ́rìnlélógún mẹ́fà ni Ọlọ́run fi dá ayé. Bíbélì ò fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí.

      • Jẹ́nẹ́sísì 1:1 sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Ohun tí Bíbélì sọ yìí kò tako ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe pé ayé ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ bílíọ̀nù ọdún.

      • Ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” tí Bíbélì lò nínú Jẹ́nẹ́sísì lè túmọ̀ sí àkókò tó gùn. Kódà, nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:4, Bíbélì lo “ọjọ́” fún gbogbo ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọrun fi dá ohun gbogbo.

      Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá bá àwọn àlàyé tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe mu.

      Ronú nípa ohun tí o gbà gbọ́

      Téèyàn bá gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, ó yẹ kó lè fi “àwọn ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀” ti ohun tó gbà gbọ́ lẹ́yìn. Ó sì tún yẹ kéèyàn ronú jinlẹ̀ dáadáa lórí àwọn ẹ̀rí náà. Ronú nípa èyí:

      Kò sí ohun tá a rí láyé yìí tó kàn ṣàdédé wà, ó máa lẹ́ni tó ṣe é. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí a bá rí àwọn nǹkan bíi kámẹ́rà, ọkọ̀ òfuurufú tàbí ilé lá ti máa ń gbà pé ẹnì kan ló ṣe wọ́n. Ǹjẹ́ o lè ronú lórí àpẹẹrẹ yìí àti àwọn nǹkan míì bí ẹyinjú èèyàn, ẹyẹ tó ń fò lókè tàbí pílánẹ́ẹ̀tì wa?

      Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ sábà máa ń wo bí àwọn ohun tí Ọlọrun dá ṣe rí láti mú kí àwọn ohun tí wọ́n ṣe túbọ̀ dáa sí i, wọ́n sì máa ń fẹ́ kí àwọn èèyàn kan sáárá sí wọn torí ohun tí wọ́n ṣe. Tó bá rọrùn láti mọ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti iṣẹ́ tó ṣe, ǹjẹ́ ó wa yẹ kó nira láti mọ Ẹlẹ́dàá tó ga jù lọ àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀ tí kò láfiwé?

      Ọkọ̀ òfuurufú kan àti ẹyẹ ń fò lókè

      Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ẹnì kan lo ṣe ọkọ̀ òfuurufú àmọ́ kò sí ẹni tó dá àwọn ẹyẹ?

      Àwọn ohun tó o lè fi ṣèwádìí ohun tó o gbà gbọ́

      Tó o bá ń fara balẹ̀ ronú lórí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, èyí á túbọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹlẹ́dàá lágbára sí i.

      Gbìyànjú èyí wò: Tẹ “ta ló ṣiṣẹ́ àrà yìí” (fi àmì àyọlò sí i) sínú àpótí tó o ti lè wá ọ̀rọ̀ jáde tó wà ní ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower. Ka èyí tó o bá fẹ́ràn lára àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! Nínú àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan, wo ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run dá tí ìwé ìròyìn náà sọ nípa rẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ kó o gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà?

      Ṣe ìwádìí sí i: Ka àwọn ìwé pẹlẹbẹ tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o lè rí ẹ̀rí púpọ̀ sí i tó fi hàn pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo.

      • Was Life Created? (Èdè Gẹ̀ẹ́sì)

        • Ibi tó dára jù lọ ni ayé wà, gbogbo ohun tá a sì nílò ló wà níbẹ̀.​—Wo ojú ìwé 4 sí 10.

        • A lè rí oríṣiríṣi àrà lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.​—Wo ojú ìwé 11 sí 17.

        • Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ba ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ mu.​—Wo ojú ìwé 24 sí 28.

      • The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking (èdè Gẹ̀ẹ́sì)

        • Kì í ṣe ara ohun tí kò ní ẹ̀mí ní àwa èèyàn ti jáde.​—Wo ojú ìwé 4 sí 7.

        • Ara àwọn ohun alààyè díjú ju pé kó jáde látinú ohun tí kò ní ẹ̀mí.​—Wo ojú ìwé 8 sí 12.

        • Àwọn ìsọfúnni tó wà nínú èròjà tó pilẹ̀ àbùdá èèyàn kọjá agbára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀.​—Wo ojú ìwé 13 sí 21.

        • Kì í ṣe ibi kan náà ni gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí ti ṣẹ̀ wá. Àwọn onímọ̀ nípa egungun àwọn ẹranko tí wọ́n ṣàwárí sọ pé ńṣe ni àwọn ẹranko kan ṣàdédé wà, àmọ́ wọn ò sọ bí àwọn ẹranko náà ṣe ń dàgbà.​—Wo ojú ìwé 22 sí 29.

      “Bí àwọn nǹkan ṣe rí, tí gbogbo rẹ̀ sì wà létòletò, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ẹranko tó fi dórí àgbáálá ayé yìí jẹ́ kí n gbà dájú pé Ọlọrun wà.”​—Thomas.

      OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

      Hannah

      “Tí n bá kà nípa ewéko, àwọn ẹranko àti ara àwa èèyàn lódindi nínú kíláàsì tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ẹnu kàn má ń yà mí ni! Ó dá mi lójú pé iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá kan ni gbogbo rẹ̀. Ohun tí mo rò ni pé ìgbàgbọ́ nínú ẹfolúṣọ̀n ni kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ kì í ṣe ìgbàgbọ́ nínú ìṣẹ̀dá.”​—Hannah.

      Talia

      “Mo fẹ́ràn kí n máa ka àpilẹ̀kọ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ ‘Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?’ tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! Ó máa ń jẹ́ kí ń mọ̀ pé irọ́ gbuu ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Kò bọ́gbọ́n mu láti parí èrò sí pé bí labalábá àbí ẹyẹ akùnyùnmù ṣe rẹwà tó yẹn, kò sí ẹni tó dá wọn.”​—Talia.

  • Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 4: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
    • Ọ̀dọ́bìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀

      ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

      Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 4: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?

      O gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà, àmọ́ o ò fẹ́ sọ bẹ́ẹ̀ lójú àwọn tí ẹ jọ wà níléèwé rẹ. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ yín ní kíláàsì, ẹ̀rù wá ń bà ẹ́ pé àwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọ iléèwé rẹ lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Báwo lo ṣe lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀, kó o sì ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá?

      • O lè ṣe é!

      • Múra sílẹ̀

      • Àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́

      • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

      O lè ṣe é!

      O lè máa rò ó pé: ‘Mi ò lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì àti ẹfolúṣọ̀n dáadáa.’ Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Danielle ti ronú bẹ́ẹ̀ rí. Ó sọ pé: “Inú mi kì í dùn tí mo bá ti rántí pé ọ̀rọ̀ yẹn á mú kí n tako olùkọ́ mi àtàwọn ọmọ kíláàsì mi.” Diana náà gbà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Tí wọ́n bá ti ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yẹn, tí wọ́n ń fi sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé ẹ̀, ṣe ni gbogbo ẹ̀ máa ń dàrú mọ́ mi lójú.”

      Ṣùgbọ́n mọ̀ pé, kó o bá wọn jiyàn kó o sì borí kọ́ ló ṣe pàtàkì. Ó sì yẹ kínú ẹ dùn pé kò dìgbà tó o bá tó di ọ̀gá nídìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kó o tó lè ṣàlàyé ìdí tí ìwọ fi rò pé ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pẹ́ ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan tó wà láyé.

      Àbá: Ṣàlàyé ohun kan tó bọ́gbọ́n mu tí Bíbélì sọ nínú Hébérù 3:4: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.”

      Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Carol ṣàlàyé ohun tó rò nípa ìlànà inú ìwé Hébérù 3:4, ó ní: “Ká sọ pé o wà nínú aginjù kan. O ò pàdé ẹnì kankan, ó sì dájú pé kò séèyàn nítòsí. Bó o ṣe ń rìn lọ, o wolẹ̀, lo bá rí igi ìtayín kan. Kí lo máa parí èrò sí? Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa sọ ni pé, ‘Ẹnì kan ti débí.’ Tá a bá gbà pé ọlọ́gbọ́n èèyàn kan ló ṣe igi ìtayín kékeré yẹn, kí ni ká wá sọ nípa àgbáyé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀!”

      Tẹ́nì kan bá sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló dá wa, ta ló wá dá Ẹni yẹn?”

      O lè dáhùn pé: “Torí pé a ò mọ gbogbo nǹkan nípa Ẹlẹ́dàá ò túmọ̀ sí pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Bí àpẹẹrẹ, o lè má mọ nǹkan kan nípa ẹni tó ṣe fóònù rẹ, àmọ́ o ṣì gbà pé ẹnì kan ló ṣe é, àbí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí a lè mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá. Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, inú mi á dùn láti sọ ohun tí mo ti kọ́ nípa rẹ̀ fún ẹ.”

      Múra sílẹ̀

      Bíbélì sọ pé kí o ‘wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú rẹ, ṣùgbọ́n kí o máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.’ (1 Pétérù 3:​15) Torí náà, kíyè sí ohun méjì​—ohun tó o máa sọ àti bí o ṣe máa sọ ọ́.

      1. Ohun tó o máa sọ. Ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run ṣe pàtàkì, ó sì lè mú kó o sọ fún àwọn ẹlòmíì nípa Ọlọ́run. Tó o bá kàn ń sọ fún wọn nípa bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó, ìyẹn nìkan ò tó láti jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Ó máa dáa kó o lo àwọn ohun kan tí Ọlọ́run dá bí àpẹẹrẹ láti ṣàlàyé ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu ká gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà.

      2. Bí o ṣe máa sọ ọ́. Jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ sọ dá ẹ lójú, àmọ́ má sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí ẹnikẹ́ni, má sì ṣe bíi pé o mọ̀ jù wọ́n lọ. Tí o kò bá bẹnu àtẹ́ lu ohun tí wọ́n gbà gbọ́, tó o sì gbà pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ gbà gbọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú lórí ohun tó o sọ.

        “Ó ṣe pàtàkì kéèyàn má sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, kó má sì ṣe bíi pé òun mọ gbogbo nǹkan tán. Téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ bíi pé òun mọ̀ jù wọ́n lọ, wọn ò ní gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀.”​—Elaine.

      Àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́

      Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń rìn nínú òjò

      Tó o bá múra sílẹ̀ kó o lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tó o múra dáadáa torí pé òjò lè rọ̀

      Alicia tó ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sọ pé: “Téèyàn ò bá múra sílẹ̀, ṣe ló máa rọra dákẹ́ táwọn míì bá ń sọ̀rọ̀ kí wọ́n má báa dójú tì í.” Bí Alicia ṣe sọ, ó yẹ kéèyàn múra sílẹ̀ tó bá fẹ́ ṣàṣeyọrí. Jenna sọ pé, “Tí mo bá fẹ́ ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá, ohun tó lè mú kí n ṣàlàyé ẹ̀ dáadáa ni tí mo bá ti ronú nípa àpẹẹrẹ kan tó rọrùn tí mo lè lò láti fi ti ọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn.”

      Ibo lo ti lè rí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀? Àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ti ran ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí:

      • Ìwé náà, Was Life Created?

      • Ìwé náà, The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking

      • Fídíò náà, The Wonders of Creation Reveal God’s Glory

      • Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! (Tẹ “ta ló ṣiṣẹ́ àrà yìí” [fi àmì àyọkà sí i] síbi tí èèyàn ti lè wá ọ̀rọ̀ ní ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower.)

      • Lo ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower láti ṣèwádìí sí i.

      O tún lè wo àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ọ̀wọ́ yìí, ìyẹn “Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?”

      1. Apá 1: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

      2. Apá 2: Ṣé Ó Yẹ Kó O Kàn Gbà Pé Òótọ́ ni Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n?

      3. Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbà Pé Ọlọ́run Ló Dá Ohun Gbogbo?

      Ìmọ̀ràn: Yan àwọn àpẹẹrẹ tó dá ìwọ gangan lójú. Wàá tètè rántí wọn, ohun tó o bá sì sọ á lè dá ẹ lójú. O lè fi ohun tó o fẹ́ ṣàlàyé nípa ìgbàgbọ́ ẹ dánra wò.

      OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

      Brittany

      “Tó bá jẹ́ pé kò sí Ẹlẹ́dàá, báwo la ṣe wá ní àwọn ànímọ́ bí ìyọ́nú àti ìfẹ́? Àwọn ànímọ́ yẹn máa ń mú kéèyàn ronú nípa àwọn ẹlòmíì dípò kó máa ro tara ẹ̀ nìkan. Mi ò gbà pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn sọ pé ṣe la kàn dédé ní àwọn ànímọ́ yẹn.”​—Brittany.

      Breanna

      “Nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwàláàyè, mo kọ́ nípa bí àwọn ẹ̀yà ara wa àti bí àwọn sẹ́ẹ̀lì wa ṣe ń ṣiṣẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún mú ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n wọnú ẹ̀kọ́ yẹn, ohun tí mo kọ́ jẹ́ kó ṣe kedere sí mi pé ẹnì kan tó gbọ́n ló dá wa.”​—Breanna.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́