ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt ojú ìwé 34-ojú ìwé 35
  • Ìbéèrè 19: Kí ló wà nínú oríṣiríṣi ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè 19: Kí ló wà nínú oríṣiríṣi ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì?
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ìsọ̀rí
  • ÌWÉ MÍMỌ́ LÉDÈ HÉBÉRÙ (“MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ”)
  • ÌWÉ MÍMỌ́ KRISTẸNI LÉDÈ GÍRÍÌKÌ (“MÁJẸ̀MÚ TUNTUN”)
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìbéèrè 19: Kí ló wà nínú oríṣiríṣi ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì?

ÌBÉÈRÈ 19

Kí ló wà nínú oríṣiríṣi ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì?

ÌWÉ MÍMỌ́ LÉDÈ HÉBÉRÙ (“MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ”)

ÌWÉ MÁRÙN-ÚN ÀKỌ́KỌ́:

Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Nọ́ńbà, Diutarónómì

Ìtàn látìgbà ìṣẹ̀dá títí tá a fi dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀

ÀWỌN ÌWÉ ÌTÀN (ÌWÉ MÉJÌLÁ):

Jóṣúà, Àwọn Onídàájọ́, Rúùtù

Ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà

1 Sámúẹ́lì àti 2 Sámúẹ́lì, 1 Àwọn Ọba àti 2 Àwọn Ọba, 1 Kíróníkà àti 2 Kíróníkà

Ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì títí dìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run

Ẹ́sírà, Nehemáyà, Ẹ́sítà

Ìtàn àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì

ÀWỌN ÌWÉ EWÌ (ÌWÉ MÁRÙN-ÚN):

Jóòbù, Sáàmù, Òwe, Oníwàásù, Orin Sólómọ́nì

Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àtàwọn orin

ÀWỌN ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀ (ÌWÉ MẸ́TÀDÍNLÓGÚN):

Àìsáyà, Jeremáyà, Ìdárò, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì, Hósíà, Jóẹ́lì, Émọ́sì, Ọbadáyà, Jónà, Míkà, Náhúmù, Hábákúkù, Sefanáyà, Hágáì, Sekaráyà, Málákì

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Ọlọ́run

ÌWÉ MÍMỌ́ KRISTẸNI LÉDÈ GÍRÍÌKÌ (“MÁJẸ̀MÚ TUNTUN”)

ÀWỌN ÌWÉ ÌHÌN RERE (ÌWÉ MẸ́RIN):

Mátíù, Máàkù, Lúùkù, Jòhánù

Ìtàn ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù

ÌṢE ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ (ÌWÉ KAN):

Ìtàn bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ àti iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì

ÀWỌN LẸ́TÀ (ÌWÉ MỌ́KÀNLÉLÓGÚN):

Róòmù, 1 Kọ́ríńtì àti 2 Kọ́ríńtì, Gálátíà, Éfésù, Fílípì, Kólósè, 1 Tẹsalóníkà àti 2 Tẹsalóníkà

Lẹ́tà sáwọn ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

1 Tímótì àti 2 Tímótì, Títù, Fílémónì

Lẹ́tà sáwọn Kristẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Hébérù, Jémíìsì, 1 Pétérù àti 2 Pétérù, 1 Jòhánù, 2 Jòhánù àti 3 Jòhánù, Júùdù

Lẹ́tà sí gbogbo Kristẹni

ÌFIHÀN (ÌWÉ KAN):

Oríṣiríṣi ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi han àpọ́sítélì Jòhánù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́