ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt ojú ìwé 16-ojú ìwé 17
  • Ìbéèrè 7: Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè 7: Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa?
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìbéèrè 7: Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa?

ÌBÉÈRÈ 7

Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa?

Ọkùnrin kan ń ronú nípa bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ogun, ìyàn àti ìwà ọ̀daràn ṣe ń ṣẹ ní àyíká rẹ̀

“Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba . . . Gbogbo nǹkan yìí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà tó ń fa ìrora.”

Mátíù 24:7, 8

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké máa dìde, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà; torí pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.”

Mátíù 24:11, 12

“Tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun, tí ẹ sì gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ má bẹ̀rù; àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.”

Máàkù 13:7

“Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì; ẹ máa rí àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì tó lágbára sì máa wà láti ọ̀run.”

Lúùkù 21:11

“Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́, ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà, abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run, wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ìṣe wọn ò ní fi agbára rẹ̀ hàn.”

2 Tímótì 3:1-5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́