ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 1/8 ojú ìwé 30-31
  • Píà Avocado—Èso Tó Wúlò Lọ́nà Púpọ̀ Ni!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Píà Avocado—Èso Tó Wúlò Lọ́nà Púpọ̀ Ni!
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbígbin Píà Avocado
  • Ó Ń Ṣara Lóore, Ó Sì Wúlò
  • Ríra Èso Náà Jẹ
  • Tòmátì Èlò Ọbẹ̀ Tí Ìwúlò Ẹ̀ Pọ̀
    Jí!—2005
  • Ọ̀pẹ—Igi Tó Wúlò fún Ọ̀pọ̀ Nǹkan
    Jí!—1999
  • ‘Ẹ Máa So Eso Púpọ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Jí!—2000
g00 1/8 ojú ìwé 30-31

Píà Avocado—Èso Tó Wúlò Lọ́nà Púpọ̀ Ni!

Láti ọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní Kòlóńbíà

ÀWỌN ajagunṣẹ́gun ará Sípéènì ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún kò rí ohun tó jọ ọ́ rí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó píà ńlá, ìrísí rẹ̀ sì jọ ọ́, ṣùgbọ́n àwọ̀ ewé ló máa ń ní kódà tó bá ti gbó pàápàá. Ó rọ̀, ó sì ṣe múlọ́múlọ́ bíi bọ́tà, ìtasánsán rẹ̀ sì fẹ́ dà bíi ti èkùrọ́. Níkẹyìn, ó wá di ohun tí a mọ̀ sí píà avocado, tó wá láti inú ọ̀rọ̀ Aztec náà, ahuacatl.

Martín Fernández de Enciso ló kọ́kọ́ mú píà avocado wọ ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 1519. Enciso rí èso náà nítòsí ibi tí a wá mọ̀ nísinsìnyí sí Santa Marta, ní Kòlóńbíà, ní ọ̀kan lára àwọn ìgbà tí àwọn ará Sípéènì kọ́kọ́ lọ ṣèwádìí nípa Gúúsù Amẹ́ríkà. Láàárín àwọn ọdún tí àwọn ará Yúróòpù fi ń ṣèwádìí yẹn, yàtọ̀ sí píà avocado, wọ́n tún tọ́ àwọn oúnjẹ kan tí wọn ò jẹ rí wò, àwọn oúnjẹ bíi ṣokoléètì, àgbàdo, àti ọ̀dùnkún.

Ṣùgbọ́n, kò sí èyí tó fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ tuntun lára àwọn oúnjẹ wọ̀nyẹn. Àìmọye ọ̀rúndún sẹ́yìn ni àwọn ọmọ onílẹ̀ tó ń gbé àwọn àgbègbè tí ojú ọjọ́ ti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ní Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé ti mọ gbogbo wọn, tí wọ́n sì ń jẹ wọ́n ní àjẹgbádùn. Àwọn kan lára àwọn ọmọ onílẹ̀ náà gbé píà avocado níyì gan-an débi tí wọ́n máa ń fi ṣe ẹ̀bùn ìgbéyàwó fún àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń fi ṣe àlejò.

Gbígbin Píà Avocado

Lónìí, ọ̀pọ̀ ibi tí ojú ọjọ́ ti móoru tàbí tó ti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ni wọ́n ti máa ń gbin píà avocado, àwọn orílẹ̀-èdè bí Ọsirélíà, Ísírẹ́lì, Kẹ́ńyà, New Zealand, Ilẹ̀ Àríwá àti Ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà, àti Philippines. Ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára nǹkan bí ogún èso, tí a ń gbìn ní ilẹ̀ olóoru, tó ń tà gan-an jákèjádò ayé.

Bó ti wù kó rí, oríṣiríṣi píà avocado ló wà káàkiri àwọn ilẹ̀ olóoru ní Amẹ́ríkà, àwọn kan rí pọlọgun bí ẹyin adìyẹ, àwọn míì tóbi tó bàrà, wọ́n tẹ̀wọ̀n kìlógíráàmù méjì. Àwọ̀ wọ́n lè yàtọ̀ síra, àwọn kan lè ní àwọ̀ ewé, kí àwọn mìíràn ní àwọ̀ àlùkò, èèpo àwọn kan rí ṣágiṣàgi, wọ́n sì rọ̀, nígbà tí tàwọn míì fẹ́lẹ́, tí wọ́n sì rí bọ̀rọ́bọ̀rọ́. Ṣùgbọ́n a lè gbin ọ̀pọ̀ igi píà avocado tí èso gbogbo wọ́n dára tí wọ́n sì rí bákan náà.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún yẹtuyẹtu òdòdó aláwọ̀ ìyeyè ràkọ̀ràkọ̀ la máa ń rí lórí igi píà avocado nígbà tó bá ń tanná. Ṣùgbọ́n ẹyọ kan péré lára ẹgbẹ̀rún márùn-ún yẹtuyẹtu òdòdó wọ̀nyí ló ń di píà avocado kan ṣoṣo. Nǹkan kan tó ṣàjèjì nípa àwọn òdòdó yìí ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní ẹ̀yà tó ń ṣẹ̀dá lẹ́búlẹ́bú akọ àti ẹ̀yà tó ń gbà wọ́n sára láti mú irú jáde. Èyí lè mú kí píà avocado dá mú èso jáde bí kì í bá ṣe ti ìṣiṣẹ́ àgbàyanu kan tí ń bẹ lára igi náà tó ń mú kí àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí máa ṣiṣẹ́ ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Nítorí èyí, àwọn igi kan máa ń mú kí òdòdó wọn ṣí sílẹ̀ láti gba lẹ́búlẹ́bú akọ nígbà yíyọ oòrùn òwúrọ̀, wọ́n á sì pa òdòdó náà dé ní ọjọ́ kanrí. Àwọn òdòdó kan náà á tún ṣí sílẹ̀ nírọ̀lẹ́, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí bí èyí tó ń mú lẹ́búlẹ́bú akọ jáde ni. Òdì kejì ohun tí ó ń ṣe yìí ni àwọn igi mìíràn tó wà nítòsí rẹ̀ máa ń ṣe. Gbígba lẹ́búlẹ́bú akọ sára yìí máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí igi tó ń mú lẹ́búlẹ́bú akọ jáde bá wà nítòsí èyí tó ń gba lẹ́búlẹ́bú akọ náà sára lákòókò kan náà. Bákan náà, àwọn oyin tàbí àwọn kòkòrò mìíràn máa ń kó ipa pàtàkì nínú gbígbé lẹ́búlẹ́bú akọ lọ sára èyí tí yóò gbà á. Nípa bẹ́ẹ̀, àjọṣepọ̀ kíkọyọyọ tó ń wáyé láàárín oòrùn, ooru, kòkòrò, afẹ́fẹ́, àti àyíká ibi tí igi èso yìí wà ló ń mú kí ó lè so.

Ó Ń Ṣara Lóore, Ó Sì Wúlò

Píà avocado ní èròjà aṣaralóore tó ṣàrà ọ̀tọ̀, nítorí pé ìwọ̀n èròjà protein, riboflavin, niacin, potassium, àti fitami C inú píà avocado pọ̀ gan-an. A gbọ́ pé èròjà fítámì tó wà nínú rẹ̀ tó mọ́kànlá, èròjà mineral inú rẹ̀ sì tó mẹ́rìnlá. Ní àwọn apá ibì kan ní Àárín Amẹ́ríkà, ẹni tó bá fi píà avocado jẹ búrẹ́dì tortilla, oúnjẹ gidi ni wọ́n gbà pé onítọ̀hún jẹ. Ọ̀rá tún wà nínú píà avocado dáadáa, òróró rẹ̀ sì dà bí òróró ólífì ní ti pé ó ní ìlọ́po èròjà àdàlù ọ̀rá nínú. Wọ́n tún máa ń fi epo rẹ̀ ṣe ọṣẹ àti èròjà ìṣaralóge.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí ohun tí kò wúlò lára igi píà avocado. Wọ́n máa ń fi igi rẹ̀ dáná. Ní Gúúsù Amẹ́ríkà, wọ́n máa ń fi èso rẹ̀ ṣe bátànì tí kì í parẹ́ sára aṣọ. Ní àwọn apá ibì kan ní Philippines, wọ́n máa ń fi ewé rẹ̀ ṣe tíì. A gbọ́ pé èèyàn lè fi èèpo igi rẹ̀ sọ awọ di rírọ̀.

Ríra Èso Náà Jẹ

Bí o bá lọ ra píà avocado lọ́jà, má ṣe fi àwọ̀ èèpo rẹ̀ pinnu bóyá ó ti pọ́n tàbí kò tíì pọ́n, níwọ̀n bí oríṣi kan kì í ti í jọ èkejì. Rọra tẹ èso náà. Bó bá rọ̀ díẹ̀, a jẹ́ pé ó ti pọ́n nìyẹn. Ibi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́, tí atẹ́gùn ń wọ̀ dáadáa ló dára fún kíkó píà avocado sí, o sì lè ṣe é kó tètè pọ́n nípa rírọra dì í sínú bébà. O tún lè kó wọn sínú fìríìjì, kódà lẹ́yìn tí o bá ti là wọ́n pàápàá. Tí o bá fún omi ọsàn wẹ́wẹ́ sí ojú rẹ̀ tóo là, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ojú èso tóo là náà pọ́n.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbádùn fífi àwọn èso bí òroǹbó tàbí tòmátì jẹ píà avocado. A lè fi èròjà tó mú lẹ́nu sí i kí ó má bàa tẹ́ lẹ́nu. Ní àfikún, píà avocado máa ń dá a pẹ̀lú edé, akàn, tàbí ọ̀kàṣà, a sì lè fi píà avocado tún ojú oríṣiríṣi sàláàdì ṣe. Àwọn èèyàn kan máa ń lọ̀ ọ́ mọ́ àwọn èso míì láti fi ṣe ohun mímu aládùn.

Tí a bá lọ píà avocado pẹ̀lú àwọn nǹkan amóúnjẹ-tasánsán àti àwọn èròjà oúnjẹ mìíràn, àpòpọ̀ aládùn tí a lè nà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ sórí búrẹ́dì gbígbẹ délẹ̀ nìyẹn. Dájúdájú, ohun mìíràn tí a kò ní gbójú fò ni àlọ̀pọ̀ guacamole tí àwọn kan mọ̀ bí ẹni mowó, tí wọ́n fi píà avocado, tòmátì, àlùbọ́sà, ata wẹẹrẹ, àti nǹkan amóúnjẹ-tasánsán ṣe. A tún lè pa á pọ̀ mọ́ oúnjẹ gidi tí a sè kalẹ̀. Tí a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, tí ẹni náà bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́ ni kí a gbé e tì í, kí ooru má bàa rà á lára.

Àbí o tiẹ̀ ti máa ń gbádùn píà avocado nínú oúnjẹ rẹ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ní àwọn apá ibì kan ní ayé, àwọn èèyàn lè kà á sí èso tó ṣàjèjì tó sì ṣọ̀wọ́n. Bí o kò bá tíì jẹ píà avocado rí, o ò ṣe gbìyànjú ẹ̀ wò nígbà mìíràn tóo bá láǹfààní ẹ̀. O lè wá rí i pé èso àjẹpọ́nnulá tó wúlò lọ́nà púpọ̀ ni!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́