ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 1/8 ojú ìwé 32
  • Ẹ̀dà Tiẹ̀ Kì Í Gbọ́wọ́ Ẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀dà Tiẹ̀ Kì Í Gbọ́wọ́ Ẹ̀
  • Jí!—2000
Jí!—2000
g00 1/8 ojú ìwé 32

Ẹ̀dà Tiẹ̀ Kì Í Gbọ́wọ́ Ẹ̀

Ọkùnrin oníṣòwò kan kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Slovenia pé:

“Ẹ ṣeun gan-an fún fífi ìwé ìròyìn Jí! àti Ilé Ìṣọ́ ránṣẹ́ sí mi déédéé. Mo máa ń kó wọn dání tí mo bá ń rìnrìn àjò, nítorí pé mo máa ń kà wọ́n lẹ́nu ìrìn àjò àti nígbà tí mo bá ń dúró kí ìpàdé nípa iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀.

“Màá tún fẹ́ kí ẹ jọ̀ọ́ fi ìwé wọ̀nyí tẹ́ẹ dárúkọ nínú àwọn ìwé ìròyìn yín ránṣẹ́ sí mi, àwọn ìwé bíi: Is There a Creator Who Cares About You?, Kí Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? àti Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn.

“Màá fẹ́ kí ẹ fi wọ́n ránṣẹ́ ní ẹ̀dà méjìméjì. Nítorí pé gbogbo ìgbà tí mo bá ń ka ìtẹ̀jáde yín nígbà tí mo bá ń rìnrìn àjò, mi ò ní ṣàìrí ẹnì kan tí yóò máa ranjú mọ́ ohun tí mò ń kà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń wù mí kí n tọ́jú rẹ̀ síbi ìkówèésí mi, ńṣe ni mo máa ń fún wọn ní ẹ̀dà tèmi nígbẹ̀yìngbẹ́yín.”

Ó dá wa lójú pé ìwọ náà máa jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ tóo bá ka ìwé pẹlẹbẹ tó ní ojú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n náà, Kí Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? Ìwé yìí fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa ní ète ọlọ́lá tí yóò ní ìmúṣẹ láìpẹ́. O lè rí ìsọfúnni nípa bóo ṣe lè rí ẹ̀dà kan gbà tí o bá kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí wa tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, gbà.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́