ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 2/8 ojú ìwé 12-14
  • Fífárùngbọ̀n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífárùngbọ̀n
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Látorí Karawun Òkòtó Dórí Abẹfẹ́lẹ́ Àlòkódànù
  • Ńṣe Ni Àṣà Fífárùngbọ̀n Ń Lọ, Tó Ń Bọ̀
  • Iṣẹ́ Tí Irun Imú Ológbò Ń Ṣe
    Jí!—2015
  • Ṣé o Máa Ń dààmú Nípa Bí Irun Rẹ Ṣe Rí?
    Jí!—2002
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Jí!—2000
g00 2/8 ojú ìwé 12-14

Fífárùngbọ̀n

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ

BÍ ỌKÙNRIN kan bá ń fi ìṣẹ́jú márùn-ún fárùngbọ̀n lóòjọ́, tó sì ń fá a bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ fún àádọ́ta ọdún, ó máa lé díẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gọ́ta nínú ìgbésí ayé ẹ̀ tó máa fi fárùngbọ̀n! Báwo ni iṣẹ́ ojoojúmọ́ yìí ṣe rí lára àwọn ọkùnrin?

Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe wẹ́rẹ́ láìpẹ́ yìí, ẹ gbọ́ èrò àwọn kan nípa irùngbọ̀n fífá: “Kì í wù mí í fá.” “Mo kórìíra ẹ̀.” “Ìfẹ̀mí-wewu ni.” “Ká sọ pé ó ṣeé ṣe ni, ohun téèyàn ń sá fún ni.” Bí ọ̀ràn irùngbọ̀n fífá bá le tó yẹn lára àwọn ọkùnrin kan, èé ṣe tí wọ́n fi ń fá a? Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ sí i nípa fífárùngbọ̀n. Bóyá a ó lè mọ̀dí abájọ.

Látorí Karawun Òkòtó Dórí Abẹfẹ́lẹ́ Àlòkódànù

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé gbọ́ sétí pé karawun òkòtó lèèyàn fi ń fárùngbọ̀n? Tó bá jẹ́ eyín ẹja ekurá ni ńkọ́? Bó sì jẹ́ abẹ táa fi akọ òkúta ṣe ńkọ́? Kò sọ́gbọ́n táwọn èèyàn ò tíì dá nídìí ṣíṣe ohun ìfárùngbọ̀n! Ní Íjíbítì ìgbàanì, abẹ bàbà tó jọ irin àáké kékeré làwọn ọkùnrin fi ń fárùngbọ̀n. Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún àná òde yìí, ohun tí wọ́n ń pè ní abẹ rẹ́rùnrẹ́rùn ni wọ́n ń lò, ìlú Sheffield, ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe é. Wọ́n máa ń ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára gan-an, ojú rẹ̀ tó mú sì ṣeé padé mọ́ èèkù rẹ̀ nígbà tí wọn ò bá lò ó. Èèyàn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an pẹ̀lú abẹ yìí, èèyàn á sì ti kọ́kọ́ fi abẹ géra ẹ lóríṣiríṣi kó tó mọ̀ ọ́n lò dáadáa. Fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ já fáfá, kí abẹ yẹn tó mọ́ wọn lọ́wọ́, á ti kọ́kọ́ dápàá sí wọn lára ná. Àmọ́, ọ̀rúndún ogún ti rẹ́yìn gbogbo ìyẹn.

Lọ́dún 1901, ọkùnrin kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ King Camp Gillette ṣe abẹ kan tó rọrùn-ún lò láìṣera ẹni léṣe, tó sì ní bíléèdì àlòkódànù. Ọgbọ́n tó fi ṣe é jọ aráyé lójú gan-an, ńṣe ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe oríṣiríṣi ẹ̀, títí kan abẹ ọlọ́wọ́ fàdákà tàbí ọlọ́wọ́ góòlù. Wọ́n tiẹ̀ ti ṣe àwọn kan báyìí tó jẹ́ pé ìlò ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ló wà fún, òmíì sì rèé, bíléèdì méjì alákànpọ̀ tàbí mẹ́ta alákànpọ̀ pàápàá ló ní, àwọn ọ̀pá ìfárùngbọ̀n kan sì wà tó jẹ́ pé ọrùn wọn ṣeé yí.

A ò tún ní gbàgbé àwọn ìfárùngbọ̀n tí ń lo iná mànàmáná, èyí tó kọ́kọ́ dọ́jà lọ́dún 1931. Ó ń ṣiṣẹ́ gan-an ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì ń lò ó, àmọ́ bíléèdì làwọn èèyàn ń lò jù, torí ìyẹn ni wọ́n gbà pé ó lè fárùngbọ̀n dáadáa.

Ńṣe Ni Àṣà Fífárùngbọ̀n Ń Lọ, Tó Ń Bọ̀

Látayébáyé, bí ìran kan ti ń lọ, tí òmíì ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àṣà fífárùngbọ̀n ń lọ, tó ń bọ̀. Ìwé náà, Everyday Life in Ancient Egypt, sọ pé àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì “kì í fẹ́ kéèyàn dá irun sí, wọ́n máa ń fẹ́ kéèyàn fá a dán ni, abẹ tó dáa sì ni wọ́n ń lò, èyí tí wọ́n ń tọ́jú sínú àpò awọ tó mọ́ tónítóní.” Bóyá àṣà yìí ló jẹ́ kí Jósẹ́fù, ọmọ Hébérù tó ń ṣẹ̀wọ̀n nígbà yẹn, kọ́kọ́ lọ fá gbogbo irun rẹ̀ kó tó wá síwájú Fáráò.—Jẹ́nẹ́sísì 41:14.

Onírùngbọ̀n yàùyàù làwọn ará Ásíríà. Wọ́n tiẹ̀ tún ń ki àṣejù bọ̀ ọ́, ní ti pé àkókò tí wọ́n fi ń ṣòfò nídìí títọ́jú irùngbọ̀n ti pọ̀ jù, wọ́n á jókòó tì í, wọ́n á máa dì í, wọ́n á máa kó o bí ẹní kórun, ó sáà gbọ́dọ̀ rí rèǹtè-rente ni.

Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń ní irùngbọ̀n tó mọ níwọ̀n, wọ́n sì máa ń fi abẹ gé eteetí rẹ̀ kó lè gún régé. Kí wá ni Òfin Ọlọ́run tó pa á láṣẹ pé àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ ‘gé kànnàǹgó wọn kúrú yí ká,’ àti pé wọn ò gbọ́dọ̀ ‘ba ìpẹ̀kun irùngbọ̀n wọn jẹ́’ túmọ̀ sí? Àṣẹ yìí ò sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ gé irun tàbí irùngbọ̀n wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí àṣẹ yìí ń sọ ni pé àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ fara wé àṣàkaṣà tó kún ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká.a—Léfítíkù 19:27; Jeremáyà 9:25, 26; 25:23; 49:32.

Láwùjọ àwọn Gíríìkì ìgbàanì, gbogbo ọkùnrin ló ń dárùngbọ̀n sí, àyàfi àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tó máa ń fá a. Ní Róòmù, ó jọ pé ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa ni àṣà fífárùngbọ̀n dóde, ó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀rúndún mélòó kan.

Àmọ́ nígbà tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ṣubú, làwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí dárùngbọ̀n sí, ó sì wà bẹ́ẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún títí di ìlàjì ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, nígbà táwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí fárùngbọ̀n. Irùngbọ̀n fífá ń bá a lọ jálẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún. Àmọ́ ṣá o, nígbà tó di àárín ọ̀rúndún kọkàndínlógún sí apá ìgbẹ̀yìn rẹ̀, ṣe ni ọwọ́ aago tún yí, táwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí dárùngbọ̀n sí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé táa bá wo àwọn fọ́tò C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, àti Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, W. E. Van Amburgh, a óò rí i pé wọ́n ní irùngbọ̀n tó gún régé, tó gbayì tó gbẹ̀yẹ lákòókò tiwọn. Àmọ́, nígbà tó di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ló tún di pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fárùngbọ̀n, ó sì wà bẹ́ẹ̀ dòní olónìí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Ṣé o wà lára ọ̀kẹ́ àìmọye ọkùnrin tó máa ń fi abẹ fárùngbọ̀n lójoojúmọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, máa rọra ṣe o, kóo má bàa fi abẹ géra ẹ, kí ẹ̀jẹ̀ sì wáá jáde. Ṣùgbọ́n, rí i pé o fá a dán o. Láti ṣe èyí láṣeyọrí, bóyá wàá fẹ́ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá tó wà nínú àpótí táa pè ní, “Ìmọ̀ràn Fáwọn Tó Ń Fi Abẹfẹ́lẹ́ Fárùngbọ̀n.” Bóyá ni àbá wọ̀nyẹn máa jẹ́ tuntun sí ẹ. Èyí ó wù ó jẹ́—sá máa rọra o, àmọ́ fá a kanlẹ̀, kó máa dán!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 266 àti 1021, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìmọ̀ràn Fáwọn Tó Ń Fi Abẹfẹ́lẹ́ Fárùngbọ̀n

Ìwé náà, Men’s Hair, ló dá àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí, tó lè wúlò fáwọn tó ń fi abẹfẹ́lẹ́ fárùngbọ̀n.b

1. Mímú kí irùngbọ̀n rẹ jọ̀lọ̀: Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà mú kí irùngbọ̀n àti kànnàǹgó jọ̀lọ̀ ni bíbu omi lílọ́wọ́ọ́rọ́ pa á dáadáa. Bó bá ṣeé ṣe, ẹ̀yìn tóo bá wẹ̀ tán ni kóo tó fá a, nítorí èyí ló máa jẹ́ kí omi túbọ̀ wọnú irùngbọ̀n àti kànnàǹgó rẹ dáadáa.

2. Lílo àwọn èròjà táa fi ń pa irùngbọ̀n káa tó fá a: Ohun mẹ́ta pàtàkì ni onírúurú ọṣẹ, àwọn èròjà tó ń hó, oríṣiríṣi ìpara, àti gírísì ń ṣe. (1) Wọn kì í jẹ́ kí irun wọ̀nyẹn gbẹ háúháú, (2) wọ́n ń jẹ́ kí wọ́n nàró ṣánṣán, àti pé (3) wọ́n ń jẹ́ kí awọ ara máa yọ̀ bọ̀rọ́, kí bíléèdì lè rọra máa lọ tẹ̀nrẹ́n lórí rẹ̀. Èròjà tó bá bá ẹ lára mu jù lọ ni kóo lò. Tiẹ̀ gbọ́ ná, ṣé o ti gbìyànjú àwọn èròjà amúrunjọ̀lọ̀ rí? Ohun tí wọ́n ṣe wọ́n fún ni láti mú kí irun jọ̀lọ̀.

3. Lílo abẹ yíyẹ lọ́nà yíyẹ: Abẹ tó mú ló yẹ kéèyàn lò. Bíléèdì tó ti kújú lè ba awọ ara rẹ jẹ́. Ìhà ibi tí irun ń hù lọ ni kí o máa fá a lọ. Téèyàn ò bá tẹ̀ lé ìhà ibi tí irun ń hù lọ, òótọ́ ni pé èèyàn ṣì lè fá a mọ́, àmọ́ èèyàn lè gé irùngbọ̀n wọnú awọ ara, èyí sì lè wá mú kó bẹ̀rẹ̀ sí hù lójú ibòmíì dípò kó máa hù ní ojúhò rẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé, bí ọkùnrin tàbí obìnrin bá ń fárun ní ìfákúfàá, ó lè fa kíkó onírúurú fáírọ́ọ̀sí tí ń fa àwọn kókó tó máa ń yọ lẹ́yìn fífárùngbọ̀n.

4. Àwọn èròjà tó ń dáàbo bo awọ ara lẹ́yìn téèyàn bá fárùngbọ̀n: Gbogbo ìgbà tóo bá fàrùngbọ̀n lo máa ń ṣí abala fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kan kúrò lára awọ ara, níbi tí kòkòrò àrùn lè gbà wọlé. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti fomi tó mọ́ fọ gbogbo ojú rẹ dáadáa—kọ́kọ́ fomi tó lọ́ wọ́ọ́rọ́ fọ̀ ọ́, lẹ́yìn náà kóo wá fi omi tútù fọ̀ ọ́ kí ó lè pa àwọn ojúhò ara dé, kí ara sì máa tutù yọ̀yọ̀. Bóo bá fẹ́, o lè lo àwọn gírísì amárajọ̀lọ̀ tí wọ́n ṣe fún lílò lẹ́yìn fífárùngbọ̀n, láti fi dáàbò bo awọ ara rẹ, tí yóò sì mú kó máa dán.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Ọ̀rọ̀ fífárùgbọ̀n táà ń sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, tàwọn ọkùnrin ni o. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn obìnrin pẹ̀lú máa ń fá irun kúrò lára, fún ìdí yìí, àwọn náà lè rí mú lò lára kókó wọ̀nyí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Kí Ni Kànnàǹgó?

Kànnàǹgó ni irun tó ń hù sí ẹ̀bátí. Èròjà purotéènì táa mọ̀ sí keratin àtàwọn míì tó fara pẹ́ ẹ ló máa ń di kànnàǹgó. Keratin jẹ́ èròjà kan tí ara ẹ̀dá ènìyàn àti ẹranko máa ń mú jáde, tó ní oríṣi ẹ̀yà purotéènì tó ní imí ọjọ́ àti àwọn fọ́nrán nínú, èròjà yìí ló sì máa ń pilẹ̀ irun, èékánná, ìyẹ́, pátákò ẹsẹ̀, àti ìwo. Lára gbogbo irun tó wà lára èèyàn, kànnàǹgó, túbọ̀mu, àti irùngbọ̀n, wà lára àwọn tó yi, tó sì rọ́ jù lọ, àwọn ló sì ṣòroó gé jù lọ, bí wọ́n ṣe mọ yẹn, bíi wáyà ni wọ́n rí. Táa bá ní ká máa kà á ní méní-méjì, a lè rí tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lójú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì ń yọ tó nǹkan bí ìdájì mìlímítà láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún.

[Credit Line]

Àwọn ọkùnrin: A Pictorial Archive from Nineteenth-Century Sources/ Dover Publications, Inc.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ńṣe ni àṣà fífárùngbọ̀n ń lọ, tó ń bọ̀

Íjíbítì

Ásíríà

Róòmù

[Àwọn Credit Line]

Museo Egizio di Torino

Iléeṣẹ́ British Museum ló fún wa láṣẹ láti ya fọ́tò wọ́nyí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́