Ǹjẹ́ o Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 17. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sábà máa ń sọ kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lè mọ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe péye tó? (Mátíù 5:18)
2. Ta ni a sọ nípa rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó kéré jù lọ tó fún ọgọ́rùn-ún, ẹni tí ó tóbi jù lọ sì tó fún ẹgbẹ̀rún”? (1 Kíróníkà 12:8-14)
3. Ta ni a sábà máa ń ka orúkọ rẹ̀ mọ́ àwọn akíkanjú ọmọ ogun Dáfídì náà, Jóábù, Ábíṣáì, àti Ásáhélì? (2 Sámúẹ́lì 2:18)
4. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè kórìíra ẹnì kan nítorí orúkọ Jésù, kí ló sọ pé kí ẹni náà ṣe kí ó lè rí ìgbàlà? (Máàkù 13:13)
5. Ọmọkùnrin mélòó ni Hámánì bí, tí gbogbo wọ́n kú nítorí ẹ̀tanú tó ní sáwọn Júù? (Ẹ́sítérì 9:10)
6. Irú ẹ̀dá ẹ̀mí wo ló fi ẹyín iná pípọ́n yòò kan Aísáyà létè, kó lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì? (Aísáyà 6:6)
7. Ta ni “ọkùnrin tí Hẹ́rọ́dù fi ṣe alámòójútó,” tí ìyàwó rẹ̀, Jòánà, ṣèránṣẹ́ fún Jésù? (Lúùkù 8:3)
8. Ipò ẹrù iṣẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ọkùnrin nínú ìjọ láti nàgà fún? (1 Tímótì 3:1)
9. Kí ni orúkọ àwọn odò mẹ́rin tó ṣàn wá láti inú “odò . . . tí ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì”? (Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14)
10. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ìwúkàrà díẹ̀ lè ṣe? (Gálátíà 5:9)
11. Kí ni orúkọ àwọn ọmọ Nóà mẹ́ta tí “gbogbo iye àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé” ti ọ̀dọ̀ wọn wá? (Jẹ́nẹ́sísì 9:18, 19)
12. Ta ni bàbá tó bí wòlíì Sámúẹ́lì? (1 Sámúẹ́lì 1:19, 20)
13. Àgbègbè ìlú wo tó wà níbi tó tẹ́jú, tí a lè rí Àfonífojì Jésíréélì láti ibẹ̀ ni wọ́n ti ja ọ̀pọ̀ ogun àjàmọ̀gá? (Àwọn Onídàájọ́ 5:19)
14. Iṣẹ́ wo ni wọ́n gbé fún àwọn ará Gibeoni, tí a dá sílẹ̀ nítorí arúmọjẹ tí wọ́n ṣe? (Jóṣúà 9:27)
15. Orúkọ wo la ń pe àwọn ọmọlẹ́yìn méjìlá tí Jésù fúnra rẹ̀ yàn? (Mátíù 10:2)
16. Àwọn orúkọ oyè wo tí Jésù nìkan ń jẹ́, ló sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi pè wọ́n? (Mátíù 23:8, 10)
17. Orílẹ̀-èdè wo ni Pọ́ọ̀lù ti kọ ìwé Hébérù? (Hébérù 13:24)
18. Gbólóhùn wo ni Jóòbù lò láti fi hàn pé ṣín-ń-ṣín lòun fi yèbọ́ lọ́wọ́ ikú? (Jóòbù 19:20)
19. Ibo ni wọ́n ti ń ṣa ọkà kúrò nínú pòròpórò àti èèpo láyé àtijọ́? (Rúùtù 3:3)
20. Kí ló fà á táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù fi kórìíra rẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 37:3-11)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín”
2. Àwọn ọkùnrin ayára-bí-àṣá àti onígboyà tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà Gádì, tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Dáfídì nínú aginjù nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba kò jẹ́ kó rímú mí
3. Ìyá wọn, Seruáyà
4. Forí tì í títí dé òpin
5. Mẹ́wàá
6. Séráfù
7. Kúsà
8. “Ipò iṣẹ́ alábòójútó”
9. Píṣónì, Gíhónì, Hídẹ́kẹ́lì, àti Yúfírétì
10. Ó ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú
11. Ṣémù, Hámù, Jáfẹ́tì
12. Ẹlikénà
13. Mẹ́gídò
14. Wọ́n di ‘aṣẹ́gi àti apọnmi fún gbogbo àpéjọ àti fún pẹpẹ Jèhófà’
15. Àpọ́sítélì
16. Rábì àti Aṣáájú
17. Ítálì
18. “Bí awọ eyín mi ni mo . . . fi yèbọ́”
19. Ilẹ̀ ìpakà
20. Nítorí pé bàbá rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀ jù wọ́n lọ àti nítorí àwọn àlá tó lá