ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 4/8 ojú ìwé 12-27
  • Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ o Mọ̀?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
Jí!—2000
g00 4/8 ojú ìwé 12-27

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 27. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Ibo ni ààlà Ilẹ̀ Ìlérí dé níhà àríwá, tó tún jẹ́ ibi tó ga jù lọ ní àgbègbè Palẹ́sínì? (Jóṣúà 12:1)

2. Ànímọ́ wo ni Jèhófà ní, tó sì dáa kéèyàn ní, tí kì í ṣe àmì àìlera? (Sáàmù 18:35)

3. Jagunjagun Asíríà mélòó ni áńgẹ́lì Jèhófà pa lóru ọjọ́ kan ṣoṣo? (2 Àwọn Ọba 19:35)

4. Ta ló fi òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye pa ẹsẹ̀ Jésù, tó sì fi irun rẹ̀ nù ún? (Jòhánù 12:3)

5. Kí lorúkọ àwọn obìnrin agbẹ̀bí tí wọ́n jẹ́ Hébérù, tí kò tẹ̀ lé àṣẹ Fáráò pé kí wọ́n máa pa àwọn ọmọkùnrin, tí Jèhófà sì wá fi ìdílé jíǹkí àwọn náà? (Ẹ́kísódù 1:15-21)

6. Ọba Júdà wo ló jẹ́ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì ó ṣe nǹkan tí kò dáa láàárín ọdún mọ́kànlélógójì tó fi jọba, síbẹ̀síbẹ̀ Bíbélì pè é ní ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ ọba? (1 Àwọn Ọba 15:14, 18)

7. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò, ẹranko wo ni Bíbélì sọ pé á máa “jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù”? (Aísáyà 65:25)

8. Èé ṣe tí gbogbo ọkùnrin Sódómù, lọ́mọdé lágbà, fi yí ilé Lọ́ọ̀tì ká? (Jẹ́nẹ́sísì 19:4, 5)

9. Ní ìdáhùn sí àdúrà Sámúẹ́lì, kí ni Jèhófà lò láti fi kó àwọn Filísínì sínú ìdàrúdàpọ̀, tí a sì wá ṣẹ́gun wọn? (1 Sámúẹ́lì 7:9, 10)

10. Kí ni Mósè sọ fún Fáráò pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ lọ ṣe tó fi bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí wọ́n lọ? (Ẹ́kísódù 5:1)

11. Ẹ̀ka igi eléso wo ni wọ́n fi máa ń ṣe àpẹẹrẹ àlàáfíà? (Wo Aísáyà 17:6.)

12. Èwo làkọ́kọ́ lára ìwé Bíbélì márùn-ún tí Jòhánù kọ?

13. Ta ni òwe sọ pé ó jẹ́ “adé fún olúwa rẹ̀”? (Òwe 12:4)

14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tọ́ sí i, ta ló kọ̀ pé kí Dáfídì Ọba má ṣòpò san òun lẹ́san nítorí pé ẹni ọgọ́rin ọdún lòun? (2 Sámúẹ́lì 19:31-36)

15. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí ni ìpíndọ́gba iye àwọn áńgẹ́lì tí Bíbélì sọ pé Sátánì kó ṣìnà? (Ìṣípayá 12:4)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Òkè Hámónì

2. Ìrẹ̀lẹ̀

3. Ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000]

4. Màríà, arábìnrin Màtá àti Lásárù

5. Ṣífúrà àti Púà

6. Ásà

7. Kìnnìún

8. Wọ́n fẹ́ fipá bá àwọn áńgẹ́lì tó bá a lálejò lò

9. Ààrá

10. Kí wọ́n lè lọ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà ní aginjù

11. Igi ólífì

12. Ìṣípayá

13. “Aya tí ó dáńgájíá”

14. Básíláì, ọmọ Gílíádì láti Rógélímù

15. Ìdá mẹ́ta

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́