“Ìwé Atọ́nà Tó Ń Sọ̀rọ̀ Síbi Tọ́rọ̀ Wà, Tó sì Gbéṣẹ́”
NÍGBÀ ẹ̀ẹ̀rùn tó kọjá ìwé ìròyìn Arkansas Democrat Gazette gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìwé tí Watch Tower Bible and Tract Society tẹ̀ jáde. Ohun tó sọ rèé nípa ọ̀kan lára wọn: “Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè jẹ́ ìwé atọ́nà tó ń sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó sì gbéṣẹ́ fún ìdílé, láìka ìsìn yòówù tí wọ́n lè máa dara pọ̀ mọ́ sí. . . .
“Ìwé yìí ń fún àwọn tó ń kà á ní ọ̀pọ̀ àmọ̀ràn tó yè kooro nípa ìwà rere àti bọ́ràn ṣe máa ń rí lára ẹni. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òǹṣèwé náà mọ̀ pé gbogbo ọ̀dọ́ ló ń fẹ́ káwọn òbí wọn fún wọn lómìnira, àmọ́, ó gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé:
“‘Ṣé o fẹ́ ká túbọ̀ fún ẹ ní ẹrù iṣẹ́ àti òmìnira púpọ̀ sí i? Nígbà náà, fẹ̀rí hàn pé o ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́. Fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ èyíkéyìí tí àwọn òbí rẹ bá yàn fún ọ.’
“Ṣàṣà òbí ni kò ní mọrírì ìwé kan tó ń sọ fún àwọn ọ̀dọ́ lemọ́lemọ́ pé ó yẹ kí wọ́n fọ̀wọ̀ wọ ara wọn àti àwọn ẹlòmíì, tó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àṣeélẹ̀ làbọ̀wábá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé yìí sábà ń fi Bíbélì kín àmọ̀ràn rẹ̀ lẹ́yìn, àlàyé rẹ̀ bọ́gbọ́n mu, ó sì kún fún làákàyè. . . . Apá tó sọ̀rọ̀ nípa iyì ara ẹni wúni lórí gan-an, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni wọ́n ti ṣì lọ́nà láti máa rò pé nǹkan gidi ni kí èèyàn máa rò pé kò sẹ́ni tó dáa tó òun.”
Lẹ́yìn tó ti fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú ìwé náà, àpilẹ̀kọ náà ń bá a lọ pé: “Àwọn ìránnilétí táa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ yìí pé ìwà ìgbéraga gbáà ni kéèyàn máa wú fùkẹ̀ àti pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ òpómúléró kan nínú ìgbésí ayé Kristẹni ló lè yọ èrò òdì àti ìwà tí kò bójú mu kúró lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ tí àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn olùgbani-nímọ̀ràn tó lérò rere lọ́kàn ti mú kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà.”
Bí ìwọ náà bá fẹ́ jàǹfààní láti inú ìsọfúnni tó wà nínú Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, o lè rí ẹ̀dà kan gbà tí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sójú ìwé 5 ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí mi nípa bí mo ṣe lè rí ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, gbà.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.