ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 5/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilé Iṣẹ́ Tábà Jẹ́wọ́ Pé Sìgá Mímu Ń Fa Àrùn Jẹjẹrẹ
  • Àwọn Àká Tó Ń Pòórá
  • Àkókò Tí Kò Tó Rí
  • Tẹ́tẹ́ Títa Di Bárakú ní Ọsirélíà
  • Gbígbógun Ti Másùnmáwo
  • Ẹwà Onímájèlé
  • “Ìhà Ọ̀dọ̀ Ta Ni Ọlọ́run Wà?”
  • Àwọn Iṣẹ́ Tó Léwu
  • Àwọn Ẹyẹ Tó Gbọ́n Féfé!
  • Owó Tó Dọ̀tí
  • “Àkóràn Inú Ẹ̀jẹ̀ Tó Wọ́pọ̀ Jù Lọ”
  • Kí Ló Burú Nínú Tẹ́tẹ́ Títa?
    Jí!—2002
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lòdì Sí Tẹ́tẹ́ Títa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2002
  • Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 5/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ilé Iṣẹ́ Tábà Jẹ́wọ́ Pé Sìgá Mímu Ń Fa Àrùn Jẹjẹrẹ

Lẹ́yìn tí wọ́n ti jiyàn pẹ̀lú àwárí àwọn oníṣègùn lóríṣiríṣi fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ilé iṣẹ́ tó ń ṣe sìgá jù lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn Philip Morris, ti gbà báyìí pé sìgá mímu ń fa àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró àti àwọn àrùn aṣekúpani mìíràn. Ìsọfúnni tí ilé iṣẹ́ kan kọ fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láti gbé jáde sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí jaburata ń bẹ tí ìlànà ìṣègùn àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹnu kò sí pé sìgá mímu ń fa jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró, àrùn ọkàn, àrùn ẹ̀dọ̀fóró wíwú àti àwọn àrùn burúkú mìíràn sára àwọn amusìgá.” Ìwé ìròyìn The New York Times ṣàkíyèsí pé ilé iṣẹ́ náà ti “kọ́kọ́ jiyàn . . . pé sìgá mímu wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ‘ewu tó máa ń dá kún’ àwọn àrùn bíi jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró ni, kì í ṣe pé òun gan-an ló ń fà wọ́n.” Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé iṣẹ́ náà gbà, wọ́n tún ṣì ń sọ pé: “Inú wa dùn gidigidi fún ẹ̀ya sìgá tiwa àti gbogbo ìpolówó ọjà tí a ti ṣe láti fi gbé e lárugẹ láti ọdún ta ti ń ṣe é.”

Àwọn Àká Tó Ń Pòórá

Àwọn àká irúgbìn oníwóró ti ń pòórá díẹ̀díẹ̀ ní àwọn oko ọkà ìwọ̀ oòrùn Kánádà. Àwọn àká irúgbìn oníwóró yìí pọ̀ gan-an ní ọdún 1933, nígbà tí ẹgbẹ̀rún márùn-ún, ọgọ́rùn-ún méje ó lé méjìdínlọ́gọ́ta [5,758] wà káàkiri àgbègbè àrọko náà. Láti ìgbà yẹn, iye náà ti lọ sílẹ̀ sí ẹgbẹ̀rún kan àti méjìléláàádọ́ta. Kí ló fà á? Ẹnì kan tó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń wó àká irúgbìn oníwóró kan palẹ̀ dárò pé: “Àkókò ti yí padà lọ́pọ̀lọpọ̀. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ti di iṣẹ́ òwò. Oko ìdílé ń parẹ́. Àká irúgbìn oníwóró náà ń pa rẹ́.” Ìwé ìròyìn Harrowsmith Country Life sọ pé: “Bí odò láìsí ipadò, bí ìlú New York láìsí àwọn ilé àwòṣífìlà, tàbí bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láìsí ilé ọtí ni oko ọkà láìsí àká irúgbìn oníwóró.” Àwùjọ àwọn elérò rere kan tó ní ire ẹ̀ lọ́kàn ti ń ṣiṣẹ́ láti dáàbò bo ohun tí wọ́n kà sí àmì ọnà ìkọ́lé sórí ilẹ̀ Kánádà. Wọ́n yí àká irúgbìn oníwóró kan padà sí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, wọ́n sì sọ òmíràn di gbọ̀ngàn ìwòran tó tún jẹ́ ilé àrójẹ.

Àkókò Tí Kò Tó Rí

Ìwé ìròyìn èdè Jámánì náà, Gießener Allgemeine, sọ pé, jákèjádò Yúróòpù làwọn èèyàn túbọ̀ ń mọ̀ ọ́n lára pé wọ́n ń kán àwọn lójú jù nítorí àkókò. Ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ yálà èèyàn ń jáde lọ ṣiṣẹ́ níta ni o, tàbí iṣẹ́ ilé ló ń ṣe, tàbí pé ó tiẹ̀ ń ṣe fàájì. Manfred Garhammer, tó jẹ́ onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Bamberg, sọ pé: “Àwọn ènìyàn kì í sùn tó, wọ́n ń sáré jẹun, wọ́n sì ń mọ̀ ọ́n lára pé àwọn ń kánjú lẹ́nu iṣẹ́ sí i ju bó ti rí ní ogójì ọdún sẹ́yìn.” Ó rí i pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè Yúróòpù tóun ti ṣèwádìí, ọ̀nà ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ti di kòókòó jàn-án jàn-án. Àwọn ohun èlò amúṣẹ́rọrùn inú ilé àti wákàtí iṣẹ́ tó dín kù sí i kò torí ẹ̀ mú “fàájì wá fún àwùjọ,” kò sì mú kí “àkókò pọ̀ sí i.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ní ìpíndọ́gba, àkókò oúnjẹ ti fi ogún ìṣẹ́jú dín kù, tí ogójì ìṣẹ́jú sì ti kúrò nínú àkókò tí a fi ń sùn lálẹ́.

Tẹ́tẹ́ Títa Di Bárakú ní Ọsirélíà

Ìwé ìròyìn The Australian sọ pé: “Tẹ́tẹ́ títa ti di ọ̀ràn ìṣòro ìlera lílekoko báyìí ní Ọsirélíà, ìṣòro ọ̀hún sì ń yọ, ó kéré tán ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún ààbọ̀ [330,000] àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún lẹ́nu.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé ìròyìn náà, ìkan nínú márùn-ún lára àwọn ẹ̀rọ tẹ́tẹ́ tó wà jákèjádò ayé ló fìdí kalẹ̀ sí Ọsirélíà, níbi tí ìpín méjìlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ibẹ̀ ti ń ta tẹ́tẹ́. Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan tó ń rí sí ọ̀ràn òwò tẹ́tẹ́ títa ní Ọsirélíà ti rí i pé ó lé ní ìpín méjì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà Ọsirélíà tó ní ìṣòro tẹ́tẹ́ títa lọ́nà tó le koko. Nínú àwọn wọ̀nyí, ìpín mẹ́tàdínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún ló ti ronú láti para wọn rí, nígbà tí èyí tó ju ìpín mọ́kànlá nínú ọgọ́rùn-ún tiẹ̀ ti gbìyànjú ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé tẹ́tẹ́ tí àwọn ń ta mú àwọn rẹ̀wẹ̀sì gidigidi. Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe náà wá pe ìpè fún àyẹ̀wò kínníkínní nípa tẹ́tẹ́ títa, ó sì dámọ̀ràn pé kí wọ́n fi àmì ìkìlọ̀ sí àwọn ilé tẹ́tẹ́.

Gbígbógun Ti Másùnmáwo

Ṣé másùnmáwo ń yọ ẹ́ lẹ́nu? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn El Universal ti sọ, Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ire Ìlú ní Mẹ́síkò dábàá àwọn atọ́nà wọ̀nyí láti gbógun ti pákáǹleke. Sun ìwọ̀n oorun tí ara rẹ nílò—bíi wákàtí mẹ́fà sí mẹ́wàá lóòjọ́. Jẹ oúnjẹ tí èròjà aṣaralóore inú rẹ̀ pé láàárọ̀, jẹ oúnjẹ ọ̀sán ní ìwọ̀n tó ṣe déédéé, kí o sì jẹ oúnjẹ tó fúyẹ́ sùn lálẹ́. Bákan náà, àwọn ògbóǹkangí tún dámọ̀ràn pé kí o dín jíjẹ àwọn ohun tí ọ̀rá pọ̀ nínú wọn kù, máa jẹ iyọ̀ níwọ̀nba, tí o bá sì ti lé lógójì ọdún, dín ṣúgà tí o ń jẹ àti mílíkì tí o ń mu kù. Gbìyànjú láti wá àkókò fún ṣíṣe àṣàrò. Túbọ̀ dín másùnmáwo kù nípa níní ìfarakanra pẹ̀lú ìṣẹ̀dá nígbà gbogbo.

Ẹwà Onímájèlé

Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé ọ̀nà ìṣoge kan tó ní nínú gígún abẹ́rẹ́ májèlé botulinum ti wà lóde báyìí láti fi mú awọ ojú jọ̀lọ̀, kó má ṣe hun jọ. Májèlé náà ń sọ àwọn iṣan ojú kan di aláìlágbára, tó jẹ́ pé láàárín ọjọ́ mélòó kan, wọ́n á ti di èyí tí kò wúlò mọ́, tí èyí á sì mú kí àwọn ibi tó hun jọ lójú jọ̀lọ̀. Nǹkan bí oṣù mẹ́rin ni ìtọ́jú yìí ń gbà tí yóò sì ti sọ awọ ojú ẹni náà di èyí tó túbọ̀ dẹ̀ sí i, tí yóò sì máa jà yọ̀yọ̀ bíi ti èwe. Àmọ́ o, ohun tó ń tẹ̀yìn ẹ̀ jáde ò dáa. Ìròyìn náà ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé “kì í ṣe pé awọ ojú híhunjọ á di àwátì lójú àwọn tó ń lò ó nìkan ni o, wọ́n tún ń pàdánù agbára láti lè ṣí ìpéǹpéjú wọn sókè nígbà tí wọ́n bá rí nǹkan ìyàlẹ́nu, láti lè rẹ́rìn-ín músẹ́, kó sì hàn lójú wọn, [àti] nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fajú ro.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, “tóo bá fẹ́ padà ní ẹwà ọ̀dọ́, ẹnu kí o ṣe tán láti sọ apá kan ojú rẹ di èyí tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ ni.”

“Ìhà Ọ̀dọ̀ Ta Ni Ọlọ́run Wà?”

Sam Smith, tí í ṣe oníròyìn eré ìdárayá sọ pé: “Kì í ṣe pé mo fẹ́ fi ìgbàgbọ́ ẹnikẹ́ni wọ́lẹ̀ o. Ṣùgbọ́n ṣé ìfọkànsìn aláṣehàn nínú eré ìdárayá yìí kò wá ti ń pọ̀ jù báyìí? Kí ló dé ná, tí àwọn agbábọ́ọ̀lù máa ń gbàdúrà nígbà tí wọ́n bá gbá bọ́ọ̀lù wọlé alábàádíje wọn?” Smith tún wá kíyè sí i pé, àwọn eléré ìdárayá kan náà tí wọ́n ṣù jọ gbàdúrà lẹ́yìn ìdíje kan ni a tún máa ń rí tí wọ́n “ń ṣépè fún àwọn oníròyìn” nínú iyàrá tí wọ́n ti ń múra tàbí “kí wọ́n máa gbìyànjú láti ṣe àwọn tí wọ́n ń bá díje léṣe” nígbà tí wọ́n bá ń figagbága lọ́wọ́. Ó wá sọ pé, ríronú pé Ọlọ́run ń ṣojú rere sí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan ju ọ̀kan lọ “dà bí ìgbà tí èèyàn ń fi ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run wọ́lẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ rẹ̀ wá sọ pé: “Ẹ máà jẹ́ ká pọ́n eré ìdárayá ju bó ṣe yẹ lọ.”

Àwọn Iṣẹ́ Tó Léwu

Àwọn iṣẹ́ mẹ́wàá wo ló léwu jù lọ? Ní ìbámu pẹ̀lú iye tí Ilé Iṣẹ́ Tó Ń Ṣàkọsílẹ̀ Iye Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba ní Amẹ́ríkà kó jọ, ti àwọn agégẹdú ló pọ̀ jù, èèyàn mọ́kàndínláàádóje [129] ló ń kú nínú gbogbo ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn apẹja àti àwọn tó ń fi ọkọ̀ ojú omi kérò wà ní ipò kejì àti ẹ̀kẹta pẹ̀lú nǹkan bíi mẹ́tàlélọ́gọ́fà àti mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún tó ń kú nínú gbogbo ọ̀kẹ́ márùn-ún wọn. Táa bá tò ó látòkè wá sísàlẹ̀, àwọn iṣẹ́ mìíràn tó léwu tún ni wíwakọ̀ òfuurufú, àwọn òṣìṣẹ́ tó ń fi mẹ́táàlì kọ́lé, àwọn awakùsà, àwọn lébìrà kọ́lékọ́lé, àwọn awakọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ akérò, àwọn awakọ̀ akẹ́rù, àti àwọn àgbẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé, “gbogbo àwọn tí jàǹbá ń pa lẹ́nu iṣẹ́ ní àpapọ̀ tó jẹ́ nǹkan bí ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ọ̀kẹ́ márùn-ún òṣìṣẹ́ ti fi ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún wá sílẹ̀” láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá.

Àwọn Ẹyẹ Tó Gbọ́n Féfé!

Ìwé ìròyìn èdè Faransé tó ń sọ nípa ìṣẹ̀dá, Terre Sauvage, sọ pé: “Àwọn ológoṣẹ́ ní Calcutta ti yẹra fún kíkó àìsàn ibà.” Àwọn ògbóǹkangí ti ṣe àkíyèsí pé nítorí bí àìsàn ibà ṣe ń pọ̀ sí i, ṣe ni àwọn ológoṣẹ́ ń fò lọ jìnnà sínú igbó láti lọ wá ewé kan tó ní egbòogi àdánidá lílágbára, tó wà fún wíwo àìsàn ibà. Láfikún sí kíkó ewé náà sínú ìtẹ́ wọn, ó hàn gbangba pé àwọn ẹyẹ náà tún ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ó jọ pé àwọn ológoṣẹ́ tó fẹ́ràn àárín ìlú, àmọ́ tí wọ́n kò fẹ́ kó àìsàn ibà ti rí ọ̀nà láti dáàbò bo ara wọn báyìí.”

Owó Tó Dọ̀tí

Ìwé ìròyìn Guardian sọ pé lára owó bébà tó ń ti báńkì ìlú London jáde wá, ó ju ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún tó ní àbààwọ́n kokéènì lára. Àwọn ògbógi ṣàyẹ̀wò ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó bébà, wọ́n sì rí i pé mẹ́rìndínlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú ẹ̀ ló ní àbààwọ́n oògùn olóró lára. Àbààwọ́n yìí máa ń dé ara àwọn owó náà nígbà tí àwọn tó ń lo oògùn líle náà bá fọwọ́ mú un. Àwọn owó tí wọ́n fọwọ́ kàn náà á wá kó èérí bá àwọn owó mìíràn níbi tí wọ́n bá ti ń fi ẹ̀rọ ṣà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí níbi tí wọ́n kó wọn pọ̀ sí. Kokéènì ti di oògùn líle táwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ń tura, ó sì ń yára gbilẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ogún ọdún àti ọdún mẹ́rìnlélógún. Ní ìbámu pẹ̀lú Àjọ Tó Ń Kíyè sí Ọ̀ràn Àwọn Ọ̀dọ́ ní ìlú London, àwọn ọ̀dọ́langba ń lo kokéènì nítorí pé wọ́n lérò pé ó ń mú iyì àti agbára wọn pọ̀ sí i.

“Àkóràn Inú Ẹ̀jẹ̀ Tó Wọ́pọ̀ Jù Lọ”

Ìròyìn Associated Press kan sọ pé: “Ó kéré tán, ó lé ní mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ àwọn ará Amẹ́ríkà tó ní kòkòrò tó ń fa àrùn mẹ́dọ̀wú, tí ìyẹn sì mú kí ó jẹ́ àkóràn inú ẹ̀jẹ̀ tó wọ́pọ̀ jù lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.” Ìbálòpọ̀ takọtabo ni lájorí ọ̀nà tí àrùn mẹ́dọ̀wú máa ń gbà tàn láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí ẹlòmíràn tàbí láti inú ẹ̀jẹ̀ tí a ti kó èèràn ràn. Àwọn tó wà nínú ewu kíkó àrùn yìí jù ni àwọn ajoògùnyó tí wọ́n máa ń pín abẹ́rẹ́ tí wọ́n fi ń gún oògùn sínú iṣan ẹ̀jẹ̀ lò àti àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ láìlo fèrè ààbò tí wọ́n ń pè ní kọ́ńdọ̀ọ̀mù. Ọ̀nà mìíràn tí àrùn yìí tún ń gbà tàn kálẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ àwọn irinṣẹ́ tí kò mọ́ tónítóní tí àwọn tó ń fín àmì sára àti àwọn tó ń ki abẹ́rẹ́ sínú ara láti fi wo àìsàn ń lò. Àwọn èèyàn tó ti gba ẹ̀jẹ̀ sára náà wà nínú ewu. Lọ́dọọdún, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ń pààrọ̀ ẹ̀dọ̀ wọn nítorí àìṣiṣẹ́mọ́ ẹ̀dọ̀ tí kòkòrò àrùn náà ń fà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́