Àrùn Éèdì Ní Áfíríkà—Àyípadà Rere Wo Ni Ẹgbẹ̀rúndún Tuntun Fẹ́ Mú Wá?
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ZAMBIA
LÓṢÙ September ọdún tó kọjá, àwọn aṣojú láti onírúurú orílẹ̀-èdè ní Áfíríkà kóra jọ sí ìlú Lusaka, lórílẹ̀-èdè Zambia, láti ṣe Àpérò Àgbáyé Lórí Ọ̀ràn Àrùn Éèdì àti Àwọn Àrùn Abẹ́ ní Áfíríkà, àpérò náà sì jẹ́ irú rẹ̀ kọkànlá. Ọ̀kan lára ète àpérò náà jẹ́ láti túbọ̀ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè níṣìírí nípa bí wọ́n ṣe lè dáhùn ìbéèrè náà, Báwo la ṣe lè yanjú ọ̀ràn ríràn tí àrùn éèdì ń ràn kálẹ̀ ní Áfíríkà?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Nkandu Luo, tó jẹ́ mínísítà ètò ìlera ní Zambia nígbà náà, sọ pé ọ̀ràn náà “burú jáì” ní Áfíríkà àti ní àwọn apá ibòmíì tí wọ́n ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lágbàáyé, ó tún sọ pé “ó ń fa ìdádúró nínú díẹ̀ lára ìtẹ̀síwájú pàtàkì tí a ti ṣe nínú ọ̀ràn ìlera àti nínú àwọn ọ̀ràn àbójútó àwùjọ ẹ̀dá àti ti ètò ọrọ̀ ajé míì, kódà, ó tiẹ̀ ń fawọ́ ẹ̀ sẹ́yìn pàápàá.”
Nínú ìjíròrò kan lórí ààbò ẹ̀jẹ̀, wọ́n sọ pé àwọn èèyàn ti kó àrùn éèdì nípasẹ̀ ìfàjẹ̀sínilára. Dókítà kan, tó jẹ́ aṣojú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ààbò Ẹ̀jẹ̀ ní Àjọ Ìlera Àgbáyé, sọ pé níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tó ní àrùn náà lára kì í fìgbà gbogbo yọrí sí kíkó kòkòrò àrùn éèdì, ṣùgbọ́n dandan ni kí ẹni tó bá gba ẹ̀jẹ̀ tó lárùn éèdì nínú kó o—kò sí ẹni tó gba irú ẹ̀jẹ̀ yẹn tí ò kó àrùn náà! Nítorí èyí, dókítà náà sọ pé nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, “ẹni tí ò bá tíì gbẹ̀jẹ̀ sára ni ààbò ẹ̀ pé jù lọ.”
Wọ́n ṣàlàyé níbi àpérò náà pé nítorí pé iye tí wọ́n fi ń tọ́jú àrùn náà pọ̀ gan-an, ìyẹn ń mú kó ṣòro, bó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe rárá, fún àwọn tí wọ́n lárùn éèdì láti rówó gba ìtọ́jú. Fún àpẹẹrẹ, ní ìpíndọ́gba, ara Uganda kan tó ń gbé àárín ìlú ń gba nǹkan bí igba dọ́là lóṣù. Ṣùgbọ́n iye owó tí àwọn oògùn tó ń gbógun ti kòkòrò àrùn náà ń gbà láti fi tọ́jú èèyàn kan ń tó ẹgbẹ̀rún kan dọ́là lóṣù!
Àpérò tí wọ́n ṣe ní Lusaka náà fi hàn pé ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rúndún tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú yìí kò lè mú ojútùú tó rọrùn kankan wá tí yóò yanjú ìṣòro ríràn tí àrùn éèdì ń ràn kálẹ̀. Àmọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ojútùú gbogbo àìsàn wà lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá, Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó ṣèlérí pé nínú ayé tuntun tí òun yóò mú wá, “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ọ̀jọ̀gbọ́n Nkandu Luo
[Credit Line]
Ẹni tó yọ̀ǹda fọ́tò yìí fún wa láti lò ni E. Mwanaleza, ti ilé iṣẹ́ Times of Zambia