“Òkú” Tó Jíǹde
Látọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní INDONESIA
NÍ JULY 17, 1997, wọ́n ṣe ìkéde kàyéfì kan nínú ìròyìn àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Indonesia tí wọ́n sọ lálẹ́ ọjọ́ náà. Wọ́n ní ọ̀kan lára àwọn òdòdó tó tóbi jù lọ láyé ti tanná. Èwo wá ni bàbàrà nínú títanná tí òdòdó kan tanná tó fi di pé wọ́n ń sọ nípa rẹ̀ nínú ìròyìn alẹ́? Ohun tó ṣe bàbàrà níbẹ̀ ni pé ti òdòdó yìí yàtọ̀ o—ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta péré ló máa fi ń tanná, ìyẹn sì jẹ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹta tàbí ẹ̀ẹ̀mẹrin láàárín ogójì ọdún tó ń lò kó tó kú pátápátá. Lẹ́yìn ìkéde náà, iye àwọn tó lọ ṣèbẹ̀wò sí Ọgbà Ọ̀gbìn Bogor, níbi tí wọ́n gbé òdòdó náà sí, fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ká sọ tòótọ́, ó lé ní ọ̀kẹ́ kan èèyàn tó lọ wo òdòdó náà lọ́jọ́ kan ṣoṣo!
Orúkọ táwọn onímọ̀ nípa òdòdó ń pe ewéko náà ni Amorphophallus titanum. Àwọn kan máa ń ké orúkọ náà kúrú sí titan arum, ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ará Indonesia ló máa ń pè é ní òkú òdòdó nítorí pé nígbà tó bá ń yọ ìtànná, òórùn rẹ̀ máa ń rán wọn létí òórùn ẹja tó ti dómùkẹ̀ àti òórùn eku tó ti jẹrà. Òórùn burúkú náà ló fi ń sọ fún àwọn oyin tó ń gba lẹ́búlẹ́bú lára wọn pé òun ti ń tanná o.
Yàtọ̀ sí òórùn tó mú kó yàtọ̀ náà, ohun mìíràn tó tún mú kí òdòdó titan arum jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni bó ṣe tóbi tó. Tí òdòdó náà bá ti gbó dáadáa, ó máa ń ga ju èèyàn lọ, àfi béèyàn náà bá ga jù ló kù. Ọ̀kan lára òdòdó yìí tó wà ní Ọgbà Ọ̀gbìn Bogor fi mítà méjì ààbọ̀ ga, fífẹ̀ rẹ̀, tó ní ìrísí àgé òdòdó, tó dà bíi pé ó ṣẹ́ léra, lé ní mítà méjì ààbọ̀. Iṣu ìdí òdòdó ńlá yìí sì fẹ́rẹ̀ẹ́ wọ̀n tó ọgọ́rùn-ún kìlógíráàmù!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtànná titan arum tóbi gan-an, òun kọ́ ni ìtànná rẹ̀ tóbi jù láyé nítorí pé ẹyọ ìtànná kan péré kọ́ ló ń yọ lára òdòdó yìí, ṣùgbọ́n ó tún ní àwọn kéékèèké míì tó pọ̀ gan-an.
Àpẹẹrẹ míì ni òdòdó titan arum kàn tún jẹ́ lára àwọn ohun tó ń fi hàn kedere pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ onísáàmù náà tó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ . . . Kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.”—Sáàmù 40:5.