“Mo Fẹ́ràn Bó Ṣe Ń Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀”
Ohun tí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ igbá kejì alábòójútó ètò òwò láti Yucatán ní Mẹ́síkò, sọ nìyẹn, nípa bí ìwé ìròyìn Jí! ṣe ń ṣàlàyé àwọn kókó ọ̀rọ̀. Nínú lẹ́tà tó kọ, ó ṣàlàyé pé Ẹlẹ́rìí kan táwọn jọ ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ abánigbófò kan ló kọ́kọ́ fojú òun mọ Jí!
Ó sọ nípa Jí! pé: “Ó jẹ́ orísun tòótọ́ tí a ti ń rí ìsọfúnni àti òtítọ́. Mo fẹ́ràn bó ṣe ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀, bó ṣe jẹ́ pé kì í dá sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìṣèlú, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gbé àwọn ènìyàn kan ga ju àwọn mìíràn lọ. Mo ti rí ojútùú sáwọn ìṣòro nípa kíka ìwé ìròyìn yìí. Ìtẹ̀jáde tó fani mọ́ra, tó wà déédéé, tó bágbà mu, tó sì kún fún ìsọfúnni ni. Mo fi ìkíni àtọkànwá mi ránṣẹ́ sí yín!”
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, Jí! ṣàlàyé nípa ìpèníjà tó wà nínú kíkojú ikú ẹnì kan tí a fẹ́ràn gan-an. Ìsọfúnni yẹn ni a tún tẹ̀ lẹ́yìn náà tí a sì gbé e sínú ìwé pẹlẹbẹ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Ó lè ṣeé ṣe pé kí ìwọ tàbí ẹnì kan tóo mọ̀ rí ìtùnú gbà nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ tó ní ojú ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí. Bóo bá fẹ́ ẹ̀dà kan rẹ̀, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bóo bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tí a kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, tàbí kí o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí táa tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi láti bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.