ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 1/8 ojú ìwé 13
  • Ṣé Oúnjẹ Rẹ Kò Lè Ṣe Ọ́ Ní Jàǹbá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Oúnjẹ Rẹ Kò Lè Ṣe Ọ́ Ní Jàǹbá?
  • Jí!—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣàníyàn
  • Bí A Ṣe Lè Dín Ewu Inú Oúnjẹ Kù
    Jí!—2002
  • Oúnjẹ Tí Kò Léwu Máa Wà fún Gbogbo Èèyàn
    Jí!—2002
  • Kí Là Ń Sọ Oúnjẹ Wa Dà?
    Jí!—2002
  • Oúnjẹ Aṣaralóore Máa Wà Fún Gbogbo Èèyàn Láìpẹ́!
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Jí!—2002
g02 1/8 ojú ìwé 13

Ṣé Oúnjẹ Rẹ Kò Lè Ṣe Ọ́ Ní Jàǹbá?

ṢÉ O máa ń jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mẹta lóòjọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, tó o bá fi máa pé àádọ́rin ọdún, iye ìgbà tí wàá ti jẹun á ti lé ní ìgbà ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́rin [75,000]. Tó bá jẹ́ ará Yúróòpù pọ́ńbélé ni, ìyẹn túmọ̀ sí pé á ti jẹ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ẹyin, ẹgbẹ̀rún márùn-ún búrẹ́dì, ọgọ́rùn-ún kan àpò ànàmọ́, ẹran tó tó ìhà màlúù mẹ́fà àti àgùntàn méjì. Ṣé wàhálà ni jíjẹ gbogbo oúnjẹ tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yẹn jẹ́? Rárá o! Ta ni kì í dùn mọ́ nínú wa láti gbọ́ gbólóhùn náà, “á gbabiire o”! Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ nípa oúnjẹ sísè kan tiẹ̀ sọ pé: “Oúnjẹ ò sí, ẹ̀mí ò sí.”

Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í fi bẹ́ẹ̀ bìkítà bóyá oúnjẹ tí a ń jẹ lè ṣe wá ní jàǹbá tàbí kò lè ṣe wá, bóyá ó ní láárí tàbí kò ní láárí. Àmọ́ tí èyíkéyìí nínú gbogbo oúnjẹ tí a ń jẹ ní ìgbésí ayé bá lọ ní nǹkan tó lè pani lára nínú pẹ́nrẹ́n, a lè ṣàìsàn àṣefẹ́ẹ̀ẹ́kú. Ǹjẹ́ ó dá wa lójú pé gbogbo nǹkan tí a ń jẹ ni kò lè ṣe wá ní jàǹbá? Lọ́jọ́ tòní, ńṣe làwọn èèyàn tí wọn ò mọ ohun tí wọ́n lè sọ lórí kókó yìí ń pọ̀ sí i. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, olórí àníyàn wọn báyìí kò ju ọgbọ́n tí wọ́n á dá tí oúnjẹ wọn kò fi ní ṣe wọ́n ní jàǹbá. Kí ló fà á?

Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣàníyàn

Lọ́dọọdún, nǹkan bí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ara Yúróòpù ló ń kó àìsàn látinú oúnjẹ. Bí àpẹẹrẹ, níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan èèyàn ni epo ìsebẹ̀ tó ní májèlé pa ní Sípéènì, tí àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún sì ṣàìsàn bí ẹni máa kú. Ní 1999, jìnnìjìnnì bo àwọn ará Belgium nígbà tí wọ́n gbọ́ nínú ìròyìn pé ó dà bíi pé àwọn oúnjẹ bí ẹyin, adìyẹ, wàràkàṣì àti bọ́tà ti ní májèlé kan tí wọ́n ń pè ní dioxin nínú. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ṣìbáṣìbo bá àwọn tó ń jẹ ẹran màlúù ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí àwọn tó ń ṣòwò rẹ̀ sì di ẹdun arinlẹ̀ nígbà tí àrùn dìgbòlugi bẹ̀rẹ̀ sí kọlu àwọn màlúù. Lẹ́yìn náà ni àrùn kan tí ń mú màlúù lẹ́nu àti kókósẹ̀ tún bẹ́ sílẹ̀, èyí tó mú kí wọ́n pa ọ̀kẹ́ àìmọye màlúù, àgùntàn, ẹlẹ́dẹ̀ àti ewúrẹ́ dà nù.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ewu yìí kì í ṣe kékeré, àwọn kókó mìíràn tún wà tó ń mú káwọn èèyàn máa jáyà nípa oúnjẹ. Àwọn ọ̀nà tuntun tí wọ́n ń lò báyìí láti mú oúnjẹ jáde tí wọ́n sì ń fi yí wọ́n padà ti ń kó ìdààmú bá àwọn tó ń rà wọ́n báyìí. Ní 1998, Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe fún Ilẹ̀ Yúróòpù kọ̀wé pé: “Arukutu tí ìmọ̀ ẹ̀rọ tó wà lóde báyìí, tí wọ́n fi ń yí oúnjẹ àti àbùdá àwọn irè oko padà ń fà kì í ṣe kékeré o.” Ṣé ìlànà sáyẹ́ǹsì tó wà lòde yìí ń tún àwọn oúnjẹ wa ṣe ni àbí ńṣe ló ń bà wọ́n jẹ́? Kí làwa fúnra wa lè ṣe tí oúnjẹ wa kò fi ní ṣe wá ní jàǹbá?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́