ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 2/8 ojú ìwé 32
  • “Gbogbo Ìgbà Làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Ń Ṣèwádìí Nínú Rẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Gbogbo Ìgbà Làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Ń Ṣèwádìí Nínú Rẹ̀”
  • Jí!—2002
Jí!—2002
g02 2/8 ojú ìwé 32

“Gbogbo Ìgbà Làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Ń Ṣèwádìí Nínú Rẹ̀”

ALÁBÒÓJÚTÓ ibi ìkówèésí kan ní Divinópolis, ìpínlẹ̀ Minas Gerais ní ilẹ̀ Brazil, kọ̀wé sí ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brazil nípa bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe fẹ́ràn ìwé ìròyìn Jí! lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sọ pé:

“Ní ibi ìkówèésí ilé ìwé tí mo ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n máa ń fi àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn táwọn [Ẹlẹ́rìí Jèhófà] tẹ̀ jáde ta wá lọ́rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí, inú Jí! ni wọ́n sábà ń lọ tí wọ́n bá ń ṣèwádìí lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ lóríṣiríṣi. Bí àpẹẹrẹ, ìtẹ̀jáde September 8, 2000 (Gẹ̀ẹ́sì), wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé táwọn àpilẹ̀kọ náà ṣe lórí Eré Ìdárayá Òlíńpíìkì. Nítorí náà, mo fẹ́ sọ fún un yín pé kẹ́ ẹ máa fún wa ní oríṣiríṣi ìtẹ̀jáde Jí! lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ sí i. Ó dá mi lójú pé bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ sí pé káwọn èwe wa máa rí àwọn ìwé tó ń gbéni ró kà ni ẹ̀yin náà ṣe nífẹ̀ẹ́ sí i.”

Ojú ìwé 4 ìtẹ̀jáde Jí! kọ̀ọ̀kan máa ń ṣàlàyé ìdí tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn náà jáde. Ó sọ pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìwé ìròyìn yìí ń gbé ìgbẹ́kẹ̀lé ró nínú ìlérí tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe nípa ayé tuntun alálàáfíà, tí kò sì léwu, tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rọ́pò ètò àwọn nǹkan búburú aláìlófin tí ń bẹ nísinsìnyí.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ṣe àwọn ìwé pẹlẹbẹ kan jáde fún ète yẹn, àkọlé ọ̀kan lára wọn ni Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Báwo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? O lè rí ẹ̀dà kan ìwé yìí gbà bí o bá kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́