ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 9/8 ojú ìwé 32
  • Gbogbo Wọn Pátá Ló Gbà Á

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Wọn Pátá Ló Gbà Á
  • Jí!—2002
Jí!—2002
g02 9/8 ojú ìwé 32

Gbogbo Wọn Pátá Ló Gbà Á

Ní iléèwé kan ní ìlú Basel, lórílẹ̀-èdè Switzerland, olùkọ́ kan sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n múra ọ̀rọ̀ kan tí wọn yóò sọ wá, èyí tó máa gbà tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórí kókó ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tó bá wù wọ́n. Rosi, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, pinnu láti sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tó sọ pé: “Ìgbà Èwe Rẹ—Bí O Ṣe Lè Gbádùn Rẹ̀ Jù Lọ.”

Àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bi í léèrè pé: “Irú kókó ọ̀rọ̀ wo lèyí kẹ̀? Ṣé oògùn olóró lo fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ni?”

Ló bá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ṣáà máa wòran.”

Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ńṣe làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà da àtẹ́wọ́ bò ó. Rosi wá sọ fún wọn pé: “Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kò tó rárá láti sọ̀rọ̀ lórí bí ẹnì kan ṣe lè gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ gan-an.” Ó wá fi kún un pé: “Mo ní ẹ̀bùn kan fún gbogbo yín pátá.” Ó sì fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Ogún ni gbogbo ìwé tó fún wọn lápapọ̀. Ó ti fi nǹkan wé ìwé ọ̀hún mọ́ránmọ́rán, ó sì ti kọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ sí i lára.

Pẹ̀lú ìmọrírì ni gbogbo wọn fi tẹ́wọ́ gba ìwé náà ó sì rí wọn lẹ́yìn náà tí wọ́n ń yẹ àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ wò. Lára àwọn àkòrí tó wà nínú ìwé náà ni: “Bawo ni Mo Ṣe Lè Mú Ki Awọn Obi Mi Túbọ̀ Fun Mi Ní Ominira Sii?,” “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Ní Awọn Ọ̀rẹ́ Tootọ?,” “Iṣẹ́ Igbesi-Aye Wo Ni Mo Nilati Yàn?,” “Ki Ni Nipa Ti Ibalopọ Takọtabo Ṣaaju Igbeyawo?,” àti “Bawo Ni Mo Ṣe Lè Mọ̀ Bi O Ba Jẹ́ Ifẹ Gidi Ni?”

Lápapọ̀, àkòrí mọ́kàndínlógójì ni ìwé náà ní. Bó o bá fẹ́ ẹ̀dà kan, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́