Àṣé Ó Ṣeé Ṣe Kéèyàn ní Ìdílé Aláyọ̀!
O BÌNRIN ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún kan láti ìlú Maladzyechna, lórílẹ̀-èdè Belarus, kọ lẹ́tà kan sí ọ́fíìsì ẹ̀ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ó ṣàlàyé nínú lẹ́tà ọ̀hún pé ilé ọkọ lòún wà, òún sì ti bímọ méjì. Ó ní: “Èmi àti ọkọ mi fẹ́ràn ara wa. Àmọ́, mo ṣàkíyèsí pé, bó ṣe ń pẹ́ sí i tá a ti jọ ń gbé, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ń fìjà pẹẹ́ta tó tá a sì máa ń bára wa jiyàn tó, ọ̀rọ̀ ọ̀hún tiẹ̀ lè máà lórí kó máà nídìí rárá. Lóṣù bíi mélòó kan sẹ́yìn, obìnrin kan tí mi ò mọ̀ rí pàdé mi lójú títì, ó sì fún mi ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan, èyí tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Gbadun Igbesi-aye Idile. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwòrán ẹlẹ́wà tí wọ́n yà sára rẹ̀ nípa ìdílé aláyọ̀ ló fà mí mọ́ra. Lẹ́yìn ìyẹn ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ka ọ̀rọ̀ inú rẹ̀, kí n tó mú un fún ọkọ mi kóun náà lè kà á.
“Bí idán lọ̀rọ̀ ọ̀hún rí, torí pé, kì í ṣe pé ìdílé wa ti láyọ̀ sí i nìkan ni, àmọ́ kí n kúkú sọ pé, ó ti yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀. Ó ti wá yé wa báyìí pé jíjẹ́ aláyọ̀ kì í ṣe ohun tó nira débi pé kò lè ṣeé ṣe. Gbogbo ohun tó ń béèrè ni ìsapá, fífi ojúlówó ọ̀yàyà hàn, ká sì tún lẹ́mìí fífúnni. Ó tún ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run, ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn, títí kan ìdílé wa àtàwọn àjèjì.”
Ó wá parí lẹ́tà rẹ̀ pé: “A ti ń gbádùn ayé wa báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, a sì ti láyọ̀ sí i. A fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó, ká sì máa fi kọ́ àwọn ọmọ wa.”
A gbà gbọ́ pé ìwọ náà lè jàǹfààní látinú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Gbadun Igbesi-aye Idile. Inú wa yóò dùn láti tún fún ọ ní ìwé olójú ewé 192 náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. O lè béèrè fún ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé náà nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó yẹ lára èyí tá a tò sójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.