ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 12/8 ojú ìwé 32
  • ‘Ìrètí Párádísè’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ìrètí Párádísè’
  • Jí!—2002
Jí!—2002
g02 12/8 ojú ìwé 32

‘Ìrètí Párádísè’

Lọ́dún tó kọjá, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Papua New Guinea gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tó máa ń ka ìwé ìròyìn Jí!, tó ń gbé ní ìlú Lae, ní Ẹkùn-Ìpínlẹ̀ Morobe. Ó kọ̀wé pé:

“Ó dá mi lójú gbangba pé mi ò ṣàṣìṣe rárá lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn (nígbà tí mo wà ní Etíkun Moresby) fún kíkà tí mo ka ìwé ìròyìn Jí! tí ètò àjọ yín ń tẹ̀ jáde. Láti ọdún 1997 títí dòní, mi ò tíì pa ìtẹ̀jáde kan jẹ. Ńṣe ni gbogbo ilé mi kún fún ìwé ìròyìn Jí!

“Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti kọ́. Mo ti mọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀, ìmọ̀ mi lórí onírúurú nǹkan ti pọ̀ sí i, gírámà mi, àti òye mi nípa Ẹlẹ́dàá ti pọ̀ sí i. Mo ti dẹni tó túbọ̀ ń rí ara gba nǹkan sí, tí mo túbọ̀ ń gba tàwọn èèyàn rò, mo sì ti ń pọkàn pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ti dẹni tó ń fojú pàtàkì wo àwọn ewéko àtàwọn ẹranko ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìmọ̀ràn mi ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn púpọ̀ sí i máa ka ìwé ìròyìn Jí! àtàwọn ìtẹ̀jáde yín yòókù.”

Ẹni tó kọ̀wé náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Mo gbà pé bí gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé yìí bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó dájú pé lọ́gán ni ìrètí wa nípa Párádísè yóò nímùúṣẹ. Ẹ máà jáwọ́ nínú iṣẹ́ àtàtà tí ẹ̀ ń ṣe o.”

Àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tọ́ka sí ìlérí tí Bíbélì ṣe pé, láìpẹ́, ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí máa di èyí tí ayé tuntun rọ́pò rẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run ni yóò sì mú èyí wá. Ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun tọ́ka sí Ìjọba yẹn gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí àwọn ìṣòro tó ń dààmú aráyé.

O lè béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé olójú ewé 192 yìí láti ṣe àyẹ̀wò fúnra rẹ nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́