ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 14-15
  • Ṣé Irú Ẹ̀jẹ̀ Rẹ Ló Ń Sọ Irú Ẹni Tó O Jẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Irú Ẹ̀jẹ̀ Rẹ Ló Ń Sọ Irú Ẹni Tó O Jẹ́?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni ‘Irú Ẹ̀jẹ̀’ Túmọ̀ Sí?
  • Kí Ló Ń Jẹ́ Ká Máa Hùwà Bá A Ṣe Ń Hùwà?
  • Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Afòyebánilò
  • Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Fifi Ẹ̀jẹ̀ Gba Ẹmi Là—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Irú Ẹ̀jẹ̀ Rẹ Ló Ń Sọ Irú Ẹni Tó O Jẹ́?

FÍFI irú ẹ̀jẹ̀ tẹ́nì kan ní pinnu irú ẹni tó jẹ́ wọ́pọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Japan, àwọn kan sábà máa ń béèrè pé, “Irú ẹ̀jẹ̀ wo ni ẹ̀jẹ̀ rẹ?” láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Àwọn tó fara mọ́ èrò yìí sọ pé àwọn tó ní irú ẹ̀jẹ̀ tó wà ní ìpele A (type A), máa ń fara balẹ̀, wọ́n máa ń ṣeé gbára lé, wọ́n sì máa ń fura sáwọn ẹlòmíràn; àwọn tó ní ẹ̀jẹ̀ tó wà ní ìpele B (type B) ní tiwọn máa ń jẹ́ ọ̀làwọ́, wọ́n máa ń dì ṣunṣun, wọ́n sì máa ń dùn ún tàn jẹ; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n tún sọ bákan náà pé ó lè nira tàbí kó rọrùn fún ẹnì kan tó ní irú ẹ̀jẹ̀ kan pàtó láti gbọ́ ẹni tó ní irú ẹ̀jẹ̀ mìíràn lágbọ̀ọ́yé.

Fún ìdí yìí, àwọn kan ka irú ẹ̀jẹ̀ tí ẹnì kan ní sí ohun tó ṣe pàtàkì nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ nílé ẹ̀kọ́, tí wọ́n bá fẹ́ yan àwọn tó máa jẹ́ lọ́gàálọ́gàá ní iléeṣẹ́ tàbí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́ pàápàá. Ǹjẹ́ ẹ̀rí kankan wà pé irú ẹ̀jẹ̀ wa ló ń darí ìhùwàsí wa lóòótọ́? Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ kankan tiẹ̀ wà nínú Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú kókó yìí?

Kí Ni ‘Irú Ẹ̀jẹ̀’ Túmọ̀ Sí?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Multimedia Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Àwọn awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó bo àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ní àwọn èròjà purotéènì nínú tí wọ́n ń pè ní antigen [tó máa ń ran àwọn agbóguntàrùn inú ara lọ́wọ́]. Ó lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún àwọn èròjà inú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa wọ̀nyí tí wọ́n ti ṣàwárí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ní irú àwọn antigen kan, àwọn kan kò ní in lára, irú àwọn antigen kan sì wà tí wọn ò lè jọ wà pa pọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà ti sọ síwájú sí i, “nítorí àwọn antigen kan tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn kan tàbí tí kò sí nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn kan, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti pín ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá èèyàn sí onírúurú ọ̀nà.”

Ìlànà tó wọ́pọ̀ jù lọ tí wọ́n fi ń pín ẹ̀jẹ̀ ni ìlànà ABO, èyí tí wọ́n fi pín ẹ̀jẹ̀ sí ìpele mẹ́rin, ìyẹn ìpele A, B, AB àti O. Láfikún sí ìyẹn, wọ́n tún sábà máa ń lo ìlànà Rh. Ká sòótọ́, nǹkan bí ogún ìlànà tí wọ́n fi ń pín ẹ̀jẹ̀ ló wà. Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ẹ̀jẹ̀ díjú gan-an ni. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Níwọ̀n bí onírúurú àwọn antigen sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ti pọ̀ rẹpẹtẹ, yàtọ̀ sáwọn ìbejì tó jọra, kò wọ́pọ̀ kí àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ irú àwọn ohun kan náà tó ṣara jọ sínú ẹ̀jẹ̀.”

Èyí fi hàn pé, láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀, “irú ẹ̀jẹ̀” ẹnì kan yàtọ̀ sí ti ẹlòmíràn. Nípa bẹ́ẹ̀, sísọ pé àwọn èèyàn tó ní irú ẹ̀jẹ̀ kan pàtó máa ń hùwà bákan náà dà bí ohun tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú wa hùwà bá a ṣe ń hùwà.

Kí Ló Ń Jẹ́ Ká Máa Hùwà Bá A Ṣe Ń Hùwà?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Ìwà ni àwọn ìṣesí tí a bí mọ́ ẹnì kan àti èyí tó kọ́ fúnra rẹ̀, tó mú kí àwọn èèyàn yàtọ̀ síra.” Bẹ́ẹ̀ ni, yàtọ̀ sáwọn ohun tá a jogún, àwọn ohun mìíràn tún wà tó ń nípa lórí ìhùwàsí wa, ìyẹn irú àwọn nǹkan bí ìdílé tẹ́nì kan ti wá, ìmọ̀ ẹ̀kọ́, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ àtàwọn ohun tójú ti rí nígbèésí ayé, àtèyí tó dára àtèyí tí kò dára. Nípa bẹ́ẹ̀, apilẹ̀ àbùdá wa nìkan ṣoṣo kọ́ lohun tó ń pinnu irú ìwà táà ń hù. Kódà, ìwà àwọn ìbejì tó jọra pàápàá máa ń yàtọ̀ síra, bó tilẹ̀ jẹ́ pé apilẹ̀ àbùdá kan náà ni wọ́n ní.

Kókó mìíràn tó tún ṣe pàtàkì ni pé, ìwà ẹnì kan lè yí padà tàbí ó ṣeé yí padà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kó ṣe kedere pé àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni lágbára láti yí àwọn èèyàn padà. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.” (Kólósè 3:9, 10) Àwọn Kristẹni mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn àti pé àwọn ti jogún èrò tó ń súnni dẹ́ṣẹ̀. Kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gbà wọ́n, wọ́n ní láti yí ìwà wọn padà.

Kí ló ń mú kó ṣeé ṣe láti ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀? Agbára ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní, èyí tá a rí nínú Bíbélì nísinsìnyí, ó kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Nígbà tí ẹnì kan bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun tó sì ń sapá láti mú ara rẹ̀ bá àwọn ìlànà rẹ̀ lórí ìwà rere mu, èyí tá a là lẹ́sẹẹsẹ nínú Bíbélì, ìwà rẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí yí padà díẹ̀díẹ̀. Ìwà Kristẹni téèyàn á wá tipa báyìí ní yóò ní nínú “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra.”—Kólósè 3:12.

Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Afòyebánilò

Ká sòótọ́, kò sí ìlànà Bíbélì kankan tó sọ pé kéèyàn má ṣèwádìí nípa irú ẹ̀jẹ̀ tó wà. Àmọ́, nǹkan ọ̀tọ̀ pátápátá ni láti máa sọ pé ó ṣeé ṣe kí èyí nípa lórí ìwà ẹ̀dá èèyàn. Gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú gbogbo nǹkan téèyàn ń ṣe nígbèésí ayé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa tọ́ ìṣísẹ̀ wa. (Sáàmù 119:105) Ìfòyebánilò tún ṣe kókó.—Fílípì 4:5.

Kò ní bọ́gbọ́n mu rárá láti máa lo irú ẹ̀jẹ̀ téèyàn ní gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún kíkọ̀ láti gbìyànjú láti ṣàtúnṣe àwọn ìwà tí kò dára téèyàn ń hù. Láìka ohunkóhun tó lè jẹ́ àbùdá àwọn Kristẹni sí, wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti mú ìwà wọn dára sí i kó lè bá àwọn ànímọ́ Jèhófà àti Jésù mu bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—Éfésù 5:1.

Láfikún sí i, àwọn Kristẹni ń sapá láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíràn wò wọ́n. “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34, 35) Tìdùnnú-tìdùnnú ni Jèhófà fi ń tẹ́wọ́ gba onírúurú èèyàn. Nítorí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu bẹ́ẹ̀ ni kò ní bá ìlànà Kristẹni mu láti máa yẹra fún àwọn èèyàn kan kìkì nítorí irú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ní tàbí láti má ṣe fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú wọn. Bákan náà lọ̀rọ̀ á ṣe rí bó bá jẹ́ pé kìkì àwọn tẹ́nì kan gbà pé ẹ̀jẹ̀ òun pẹ̀lú wọn bára mu nìkan ṣoṣo lòun á máa bá rìn. Bíbélì ṣí wa létí pé: “Bí ẹ bá ń bá a lọ ní fífi ìṣègbè hàn, ẹ ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 2:9.

Bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti ń tẹ̀ síwájú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nǹkan tuntun àti àbá èrò orí tuntun nípa ara èèyàn ń yọjú. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí àwọn èrò wọ̀nyí máa fani mọ́ra. Àmọ́ ṣá o, yóò dára kó jẹ́ pé Bíbélì, kì í ṣe èrò èèyàn, làwọn Kristẹni á jẹ́ kó máa darí ìrònú wọn. Nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe nígbèésí ayé, àwọn Kristẹni ní láti “máa wádìí ohun gbogbo dájú,” kí wọ́n sì “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.”—1 Tẹsalóníkà 5:21.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́