ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 2/8 ojú ìwé 16-21
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
Jí!—2004
g04 2/8 ojú ìwé 16-21

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 21. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Ibo ni Jésù sọ pé kí ọkùnrin afọ́jú náà ti lọ wẹ̀ kó lè ríran? (Jòhánù 9:7)

2. Ọ̀gangan ibo ni Sátánì ti sọ fún Jésù pé kó bẹ́ sílẹ̀ kí àwọn áńgẹ́lì bàa lè dáàbò bò ó? (Mátíù 4:5, 6)

3. Kí nìdí tí ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn fi ń bẹ Jésù “pé kí wọ́n sáà lè fọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀”? (Mátíù 14:35, 36)

4. Èròjà tí wọ́n ń lò fún fífọ aṣọ mọ́ nígbàanì wo ni wọ́n tún máa ń lò fún yíyọ́ àwọn nǹkan bí òjé àti fàdákà? (Aísáyà 1:25)

5. Orúkọ méjì wo ni wọ́n sọ ọmọkùnrin Rèbékà tó jẹ́ àkọ́bí, kí sì nìdí? (Jẹ́nẹ́sísì 25:25, 30)

6. Ìlànà wo ni Jèhófà sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé fún yíyan àwọn amí méjìlá láti rán lọ sí ilẹ̀ Kénáánì? (Númérì 13:2)

7. Láti orílẹ̀-èdè wo ni Pọ́ọ̀lù ti kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn Hébérù? (Hébérù 13:24)

8. Inú oṣù àwọn Júù wo ni Sólómọ́nì parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà? (1 Ọba 6:38)

9. Àwọn ọkùnrin méjì wo ló gbé ọwọ́ Mósè ró títí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì? (Ẹ́kísódù 17:12)

10. Kòkòrò wo la mọ̀ tó máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára tó sì ní ọgbọ́n tí a dá mọ́ ọn? (Òwe 6:6)

11. Dípò kí Jónà lọ sí Nínéfè gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún un, ibo ló gbìyànjú láti sá lọ? (Jónà 1:2, 3)

12. Ibo ni Mósè ti kọ́ àgọ́ ìjọsìn? (1 Kíróníkà 21:29)

13. Níwọ̀n bí a kò ti pín ilẹ̀ èyíkéyìí fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ogún, báwo ni wọ́n ṣe ń rí ohun tí wọ́n nílò? (Númérì 18:21)

14. Lọ́jọ́ tí Jésù jíǹde, ibo ló ti fara han Kíléópà àti ọmọ ẹ̀yìn mìíràn kan? (Lúùkù 24:13)

15. Àwọn wo ni Jèhófà yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá oníṣẹ́ ọnà fún kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn? (Ẹ́kísódù 31:1-11)

16. Orúkọ wo ni Pọ́ọ̀lù sábà máa ń pe àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú rẹ̀? (Fílípì 4:3)

17. Kí nìdí tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti máa fi ìṣẹ́tí olókùn tín-ín-rín, tó ní àwọ̀ búlúù, sétí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ wọn? (Númérì 15:37-40)

18. Igi wo ni wọ́n lò láti fi ṣe àwọn kérúbù méjì náà àtàwọn ilẹ̀kùn Ibi Mímọ́ Jù Lọ? (1 Ọba 6:23, 31)

19. Gẹ́gẹ́ bí Sekaráyà ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà lò láti ṣàpèjúwe bó ṣe máa ń rí lára Rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ni àwọn èèyàn Rẹ̀ lára? (Sekaráyà 2:8)

20. Ta ni bàbá Jésíbẹ́lì? (1 Ọba 16:31)

21. Kí nìdí tí Pílátù fi gbìyànjú láti fi Jésù sílẹ̀? (Lúùkù 23:4)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Adágún Sílóámù

2. Odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì

3. Wọ́n fẹ́ kó wo àìsàn àwọn sàn

4. Ọṣẹ ìfọṣọ (èròjà sodium carbonate tàbí potassium carbonate)

5. “Ísọ̀” nítorí bó ṣe nírun lára gan-an nígbà tí wọ́n bí i àti “Édómù” nítorí ọbẹ̀ lẹ́ńtìlì pupa tó torí rẹ̀ ta ogún ìbí rẹ̀

6. “Ọkùnrin kan . . . fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ti àwọn baba rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìjòyè láàárín wọn”

7. Ítálì

8. Búlì, oṣù kẹjọ lórí kàlẹ́ńdà mímọ́

9. Áárónì àti Húrì

10. Eèrà

11. Táṣíṣì

12. Inú aginjù

13. Àwọn ẹ̀yà tó kù máa ń fún wọn ní ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí wọ́n bá mú jáde látinú ilẹ̀ àti látinú àwọn màlúù

14. Lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì

15. Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù

16. “Àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi”

17. Láti rán wọn létí pé èèyàn mímọ́ ni wọ́n lójú Jèhófà àti pé wọ́n ní láti máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́

18. Igi olóròóró

19. “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi”

20. Etibáálì, ọba àwọn ọmọ Sídónì

21. Kò rí ìwà ọ̀daràn kankan lọ́wọ́ rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́