ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 3/8 ojú ìwé 24-25
  • A Dán Ìgbàgbọ́ Wọn Wò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Dán Ìgbàgbọ́ Wọn Wò
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífipá Múni Wọṣẹ́ Ológun
  • Àwọn Mẹ́rìndínlógún Tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n ní Ilé Olódi Richmond
  • Wọ́n Wà Wọ́n Lọ sí Ilẹ̀ Faransé —Wọ́n Tún Kó Wọn Padà!
  • Ohun Táwọn Èèyàn Fi Ń Rántí Wọn
  • Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo Là Ń Tì Lẹ́yìn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1916
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Ibì Kọ̀ọ̀kan
    Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́
  • Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Singapore
    Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́
Jí!—2004
g04 3/8 ojú ìwé 24-25

A Dán Ìgbàgbọ́ Wọn Wò

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

RICHMOND jẹ́ ìlú ẹlẹ́wà kan ní àgbègbè North Yorkshire, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Béèyàn bá dúró lókè ilé olódi tó wà níbẹ̀, èyí tí wọ́n kọ́ ní kété lẹ́yìn ìṣẹ́gun Norman lọ́dún 1066, yóò láǹfààní láti wo gbogbo àfonífojì tó wà níbi odò Swale, títí lọ dé Ọgbà Ìtura Ìjọba Àpapọ̀ ti Yorkshire Dales.

Ètò orí tẹlifíṣọ̀n náà, The Richmond Sixteen, ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun pàtàkì kan nípa ilé olódi náà nínú ìtàn rẹ̀ lóde-òní. Ohun náà ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n níbẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn kò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wọn?

Fífipá Múni Wọṣẹ́ Ológun

Lẹ́yìn tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kéde ogun ní 1914, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni sún nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ ọkùnrin láti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Àmọ́, nítorí pé àwọn tó ń kú lójú ogun ń pọ̀ sí i, àti pé àwọn ológun kíyè sí i pé ogun náà kò ní tètè kásẹ̀ nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn olóṣèlú ti ṣèlérí, “ńṣe ni wọ́n kúkú wá ń fipá mú àwọn èèyàn láti wọṣẹ́ ológun dípò kí wọ́n máa rọ̀ wọ́n,” gẹ́gẹ́ bí Alan Lloyd, òpìtàn kan nípa ogun, ṣe sọ. Torí náà, fúngbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní March 1916, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fipá mú àwọn àpọ́n wọṣẹ́ ológun.

Ẹgbẹ̀rún méjì ìgbìmọ̀ ni wọ́n dá sílẹ̀ láti máa gbọ́ ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn, àmọ́, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn tó kọ̀ láti jagun nítorí ẹ̀rí ọkàn ni wọ́n dá sílẹ̀ pátápátá. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ni wọ́n pàṣẹ fún láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ológun tí kì í gbé ohun ìjà, èyí tí wọ́n dá sílẹ̀ láti ti ogun náà lẹ́yìn. Àwọn tí wọ́n kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí ni wọ́n ṣì ń wò gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n fipá mú wọṣẹ́ ológun, wọ́n sì sọ pé kí àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n dá sílẹ̀ bá wọn ṣẹjọ́. Wọ́n fojú wọn rí màbo, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé inú ibi tó há, tí kò sì bójú mu rárá ni wọ́n máa ń wà.

Àwọn Mẹ́rìndínlógún Tí Wọ́n Fi Sẹ́wọ̀n ní Ilé Olódi Richmond

Márùn-ún nínú àwọn ẹni mẹ́rìndínlógún tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní ilé olódi Richmond ló wà lára Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn. Herbert Senior, tó di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1905 lẹ́ni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, kọ ohun tó tẹ̀ lé e yìí ní àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, ó ní: “Wọ́n fi wá sí yàrá ẹ̀wọ̀n tí kò yàtọ̀ sí àjà ilẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọn ò ti lò wọ́n mọ́, nítorí pé pàǹtírí tó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀ ga dé kókósẹ̀.” Àwọn àwòrán tó wà lára ògiri, àtàwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tó ti ń pa rẹ́ báyìí tàbí téèyàn ò lè rí kà, èyí táwọn ẹlẹ́wọ̀n yà tí wọ́n sì kọ sára ògiri yàrá ẹ̀wọ̀n wọn tí wọ́n kùn lẹ́fun, ti di ohun táwọn èèyàn ń rọ́ wá wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Lára ohun tó wà lára ògiri wọ̀nyẹn ni orúkọ àwọn ẹbí wọn, ìsọfúnni nípa wọn àti àwòrán wọn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Ẹlẹ́wọ̀n kan wulẹ̀ kọ àkọsílẹ̀ ṣókí sára ògiri, ó ní: “Ó sàn kí n kú nítorí mo rọ̀ mọ́ ìlànà mi ju kí n kú nítorí pé mi ò ní ìlànà kankan lọ.” Ọ̀pọ̀ lára ìsọfúnni náà làwọn ẹlẹ́wọ̀n fi mẹ́nu kan Jésù Kristi àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fara balẹ̀ ya àwòrán àmì àgbélébùú-òun-adé, èyí tí International Bible Students Association (IBSA), ìyẹn ni Ẹgbẹ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé ń lò nígbà yẹn. Herbert Senior rántí pé òun ya ohun kan sára ògiri yàrá ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi òun sí, ìyẹn ni “Chart of the Ages,” èyí tó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà The Divine Plan of the Ages, àmọ́ kò sẹ́ni tó tíì rí àwòrán náà. Ó lè jẹ́ pé àwòrán náà ti pa rẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tó wà lára àwọn ògiri tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n gan-an tàbí níbòmíràn nínú ọgbà náà. Àkọlé mìíràn kà pé: ‘Clarence Hall, Leeds, I.B.S.A. May 29, 1916. Wọ́n Wà Mí Lọ sí Ilẹ̀ Faransé.’

Wọ́n Wà Wọ́n Lọ sí Ilẹ̀ Faransé —Wọ́n Tún Kó Wọn Padà!

Ńṣe làwọn abógunrìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá ní ilẹ̀ Faransé àti Belgium. Èyí ló mú kí Horatio Herbert Kitchener, mínísítà fún ọ̀ràn ogun nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti Ọ̀gágun Douglas Haig bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn ọmọ ogun sí i lójú méjèèjì, títí kan àwọn tó ti láya nílé, tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí fipá mú wọṣẹ́ ológun láti May 1916. Láti mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ dara pọ̀ mọ́ wọn, àwọn aláṣẹ pinnu láti fàwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun jófin. Látàrí èyí, lẹ́yìn tí wọ́n dojú ìbọn kọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìndínlógún náà tí wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí wọn lọ́wọ́, wọ́n kó wọn sínú ọkọ̀ ojú irin kan láìbófinmu, wọ́n sì wà wọ́n lọ sí ilẹ̀ Faransé ní bòókẹ́lẹ́, nípa gbígba ọ̀nà ẹ̀bùrú. Ní etíkun Boulogne, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Heritage ṣe sọ, “wọ́n fi wáyà ẹlẹ́gùn-ún de àwọn ọkùnrin náà mọ́gi, bí ẹni pé wọ́n fẹ́ kàn wọ́n mọ́ àgbélébùú,” lójú wọn kòró ni wọ́n sì ṣe yìnbọn pa ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó sá kúrò lójú ogun. Wọ́n wá sọ fún wọn pé bí wọn kò bá pa àṣẹ mọ́, irú ikú yẹn làwọn náà á kú.

Ní àárín oṣù June ọdún 1916, wọ́n ní kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìndínlógún náà dúró níwájú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọmọ ogun kí wọ́n lè gba ìdájọ́ ikú wọn, àmọ́ nígbà tó fi máa di àkókò yìí Kitchener ti kú, olórí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sì ti dá sí ọ̀ràn náà. Àwọn kan ti fi káàdì pélébé kan tó ní ọ̀rọ̀ àṣírí nínú ṣọwọ́ sí àwọn aláṣẹ ní ìlú London, àwọn yẹn sì ti fagi lé àṣẹ táwọn ológun pa. Wọ́n pàṣẹ fún Ọ̀gágun Haig láti yí gbogbo ìdájọ́ ikú náà padà sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára.

Nígbà tí wọ́n padà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n mú díẹ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìndínlógún náà lọ sí ibì kan tí wọ́n ti ń fọ́ akọ òkúta nílẹ̀ Scotland láti ṣe “iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì fún orílẹ̀-èdè” lábẹ́ ipò tó ń kóni nírìíra, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ ti fi hàn. Àwọn mìíràn, tí Herbert Senior wà lára wọn, ni wọ́n rán padà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí kì í ṣe tàwọn ológun.

Ohun Táwọn Èèyàn Fi Ń Rántí Wọn

Níwọ̀n bí ògiri ẹ̀wọ̀n náà ti di ahẹrẹpẹ, wọ́n ṣètò ohun àfihàn híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ kan sí Ilé Olódi Richmond, èyí tí Àjọ English Heritage ń bójú tó báyìí. Ohun àfihàn náà ni àwòrán ara ògiri kan tí wọ́n fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣe, èyí tó máa mú kó ṣeé ṣe fún àwọn olùṣèbẹ̀wò láti ṣàyẹ̀wò àwọn yàrá ẹ̀wọ̀n náà àtàwọn ohun tí wọ́n kọ sára wọn fínnífínní, láìsí pé wọ́n bà wọ́n jẹ́. Wọ́n máa ń fún àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wá ṣèbẹ̀wò níṣìírí láti ṣèwádìí kí wọ́n lè mọ ìdí táwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun fi múra tán láti jìyà, láti ṣẹ̀wọ̀n, àní láti kú pàápàá nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tọkàntọkàn.

Àwọn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní ilé olódi Richmond “mú kí ọ̀ràn kíkọ̀ láti wọṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn wá sójú táyé, èyí sì mú kí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kan sáárá sí wọn.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló jẹ́ káwọn aláṣẹ túbọ̀ mọ bí wọ́n á ṣe máa bójú tó ọ̀ràn àwọn tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

Lọ́dún 2002, wọ́n ya ọgbà ẹlẹ́wà kan nínú àgbàlá ilé olódi náà sọ́tọ̀ lápá kan, ní ìrántí àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìndínlógún náà láti fi ìmọrírì hàn fún bí wọ́n ṣe dúró ṣinṣin lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Ilé ìṣọ́ ọ̀rúndún kejìlá tó wà ní Ilé Olódi Richmond, àti ibi tí àwọn yàrá ẹ̀wọ̀n wà

Herbert Senior, ọ̀kan lára àwọn mẹ́rìndínlógún tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n

Ọ̀kan lára àwọn yàrá ẹ̀wọ̀n níbi tí wọ́n fi àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rìndínlógún náà sí

Àwòrán tí kò hàn ketekete lójú ìwé méjèèjì: Díẹ̀ lára àwọn àkọlé àti àwòrán tó wà lára ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n náà látọjọ́ pípẹ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́