Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 23. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Kí ni Ábúráhámù rà ní irínwó ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hétì? (Jẹ́nẹ́sísì 23:16-20)
2. Àwọn ohun wo ni Jèhófà lò bí àmì nígbà tí Gídíónì fẹ́ láti mọ̀ bóyá ó fọwọ́ sí i pé kí òun bá àwọn ará Mídíánì jagun? (Àwọn Onídàájọ́ 6:36-40)
3. Irú ilé wo ló jẹ́ pé nínú ìwé Kíróníkà, Nehemáyà, Ẹ́sítérì àti Dáníẹ́lì nìkan la ti mẹ́nu kàn án nínú Bíbélì? (Dáníẹ́lì 8:2)
4. Kí ló wọ Ákáánì lójú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi ka àṣẹ Ọlọ́run sí, tó sì wá mú ká ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìlú Áì? (Jóṣúà 7:21)
5. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dá Éfà tó sì fi í fún Ádámù bí aya, kí ló pàṣẹ pé kí gbogbo lọ́kọ láya máa jẹ́ látìgbà náà lọ? (Jẹ́nẹ́sísì 2:24)
6. Àwọn àṣà ìbẹ́mìílò wo ni Bíbélì dẹ́bi fún? (Diutarónómì 18:10, 11)
7. Báwo ni Ọba Ahasuwérúsì ṣe dáwọ̀ọ́ ìdùnnú sísọ tó sọ Ẹ́sítérì di ayaba? (Ẹ́sítérì 2:18)
8. Kí ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò jẹ́ nítorí orúkọ òun? (Mátíù 10:22)
9. Ta ni ọmọbìnrin Mídíánì tí Fíníhásì pa nígbà tí Símírì mú un wá sáàárín àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wá bá a ṣèṣekúṣe? (Númérì 25:15)
10. Ta ni Bíbélì ṣàpèjúwe nínú Òwe orí kọkànlélọ́gbọ̀n? (Òwe 31:10)
11. Ọ̀rọ̀ wo ni Míkà fi bẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ alápá mẹ́ta tó sọ fún ìlú Samáríà àti Jerúsálẹ́mù? (Míkà 1:2; 3:1; 6:1)
12. Ta ló pa Ámínónì, tí í ṣe dáódù Dáfídì, síbẹ̀ tí Dáfídì forí jìn ín lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? (2 Sámúẹ́lì 13:32, 33)
13. Kí nìdí tí Míkálì, ìyàwó Dáfídì, fi “tẹ́ńbẹ́lú” ọkọ “rẹ̀ nínú ọkàn-àyà rẹ̀,” tí èyí sì wá mú kó kú láìbímọ? (2 Sámúẹ́lì 6:14-16, 20-23)
14. Kí ni Bíbélì sọ pé Amágẹ́dọ́nì jẹ́? (Ìṣípayá 16:14, 16)
15. Ní Lísírà, kí ló fà á táwọn ogunlọ́gọ̀ fi tètè yí èrò wọn padà, tí wọn ò fi rúbọ sí Pọ́ọ̀lù mọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kúkú fẹ́ sọ ọ́ lókùúta? (Ìṣe 14:19)
16. Kí ni Pétérù ṣe níbi tó ti ń gbìyànjú láti dáàbò bo Jésù lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wá mú un? (Jòhánù 18:10)
17. Nígbà ìdẹwò kẹta nínú aginjù, kí ni Èṣù gbìyànjú láti mú kí Jésù ṣe? (Mátíù 4:9)
18. Èròjà wo ló dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìwà ìbàjẹ́ nínú Bíbélì? (Mátíù 16:6)
19. Àwọn mìíràn wo ni ọgbọ́n Sólómọ́nì ju tiwọn lọ? (1 Àwọn Ọba 4:31)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Ibi ìsìnkú ìdílé
2. Ìrì àti ìṣùpọ̀ irun
3. Ilé aláruru
4. “Ẹ̀wù oyè kan láti Ṣínárì” pẹ̀lú fàdákà àti wúrà díẹ̀
5. “Ara kan”
6. Iṣẹ́ wíwò, idán pípa, wíwá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀, iṣẹ́ oṣó, fífi èèdì di àwọn ẹlòmíràn, wíwádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò, gbígbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ látẹnu àwọn abẹ́mìílò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
7. Ó se àsè ńlá, ó yọ̀ǹda ìdáríjì ọba fáwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ rẹ̀, ó sì fúnni ní àwọn ẹ̀bùn
8. “Ẹni ìkórìíra”
9. Kọ́síbì, ọmọbìnrin Súúrì
10. “Aya tí ó dáńgájíá”
11. “Ẹ gbọ́”
12. Ábúsálómù, ọmọkùnrin tí Dáfídì bí ṣìkẹta
13. Ìdí ni pé inú rẹ̀ kò dùn sí bí Dáfídì ṣe “ń fò sókè, tí ó sì ń jó yí ká níwájú Jèhófà”
14. “Ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè”
15. Nígbà táwọn Júù tó wá láti Áńtíókù àti Íkóníónì dé, wọ́n yí àwọn èèyàn náà lérò padà pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀
16. Ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fi ṣá Málíkọ́sì tó jẹ́ ẹrú, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù
17. Pé kí Jésù ‘jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo’
18. Ìwúkàrà (amúyẹ̀funwú)
19. Étánì, Hémánì, Kálíkólì àti Dáádà