Àṣálẹ́ Tó Yẹ Ká Máa Rántí—Sunday, April 4, 2004
LÁLẸ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí Jésù Kristi kú, ó dá ayẹyẹ Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tó ń jẹ àsè ráńpẹ́ kan pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, níbi tó ti lo wáìnì àti búrẹ́dì aláìwú gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ, Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí ọ láti wá bá wọn ṣe Ìṣe Ìrántí tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún yìí. Lọ́dún yìí, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀ lọ́jọ́ Sunday, April 4, la ó ṣe ayẹyẹ náà, ọjọ́ yìí ni déètì tó bá Nísàn 14 mu lórí kàlẹ́ńdà tí wọ́n ń fi òṣùpá kà, tí wọ́n ń lò láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì. Jọ̀wọ́ béèrè ibi tí ayẹyẹ náà á ti wáyé àti àkókò tí wọn yóò ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.