ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 5/8 ojú ìwé 16
  • Lílo Òmìnira Kristẹni Lọ́nà Yíyẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílo Òmìnira Kristẹni Lọ́nà Yíyẹ
  • Jí!—2004
Jí!—2004
g04 5/8 ojú ìwé 16

Lílo Òmìnira Kristẹni Lọ́nà Yíyẹ

NÍTORÍ pé àwọn Kristẹni tá a mí sí láti kọ Bíbélì mọrírì ète Ọlọ́run tó mú kó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi hàn sí wọn (“Dájúdájú, òmìnira ni a pè yín fún, ẹ̀yin ará”), lemọ́lemọ́ ni wọ́n gba àwọn Kristẹni níyànjú láti wà lójúfò kí wọ́n má bàa ṣi òmìnira wọn lò gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti máa mòòkùn nínú àwọn iṣẹ́ ti ara (Gálátíà 5:13) tàbí gẹ́gẹ́ bíi bojúbojú fún ìwà búburú. (1 Pétérù 2:16) Jákọ́bù sọ̀rọ̀ nípa ‘wíwo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín,’ ó sì ṣàlàyé pé ẹni tó bá jẹ́ olùgbọ́ tí kì í gbàgbé, ṣùgbọ́n tó ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olùṣe, yóò láyọ̀.—Jákọ́bù 1:25.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbádùn òmìnira tó ti rí gbà nípasẹ̀ Kristi àmọ́, kò jẹ́ lo òmìnira yìí láti tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn, kò sì fi pa àwọn ẹlòmíràn lára. Nínú lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sọ pé òun ò ní ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn nípa ṣíṣe ohun kan tí Ìwé Mímọ́ fún òun lómìnira láti ṣe ṣùgbọ́n tó lè máa kọ ẹnì kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ lóye lóminú, ẹni tí ohun tí Pọ́ọ̀lù bá ṣe lè pa ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ lára. Ó lo jíjẹ ẹran tí wọ́n ti fi rúbọ sí òrìṣà kí wọ́n tó wá tà á lọ́jà bí àpẹẹrẹ. Jíjẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀ lè mú kí ẹnì kan tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò lágbára dẹ́bi fún Pọ́ọ̀lù pé kò lo òmìnira rẹ̀ lọ́nà yíyẹ, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó ń ṣèdájọ́ Pọ́ọ̀lù, èyí tí kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èé ṣe tí ó fi ní láti jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ní ń ṣèdájọ́ òmìnira mi? Bí mo bá ń fi ọpẹ́ ṣalábàápín, èé ṣe tí a ó fi máa sọ̀rọ̀ mi tèébútèébú lórí èyíinì tí mo ti dúpẹ́ fún?” Láìfi ìyẹn pè, àpọ́sítélì náà ti pinnu láti má ṣe lo òmìnira rẹ̀ lọ́nà tí yóò pa àwọn ẹlòmíràn lára, bí kò ṣe lọ́nà tí ń gbéni ró.—1 Kọ́ríńtì 10:23-33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́