Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 14. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Ìlú wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wakọ̀ ojú omi lọ tí wọ́n fi rí Jésù tó ń rìn lórí òkun? (Máàkù 6:45-49)
2. Orúkọ wo ni Jésù sọ Símónì ọmọkùnrin Jòhánù? (Jòhánù 1:42)
3. Kí ni ẹni yòówù tó bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ sí wọn? (Máàkù 10:44)
4. Ìlú àwọn ará Kálídíà wo ni Jèhófà pàṣẹ pé kí Ábúrámù ti kúrò? (Jẹ́nẹ́sísì 11:31; 12:1)
5. Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kí nìdí tó fi sọ pé kí wọ́n má ṣe máa wá àmì ìṣẹ̀lẹ̀? (Diutarónómì 18:10-13)
6. Ìbùkún wo ni Jésù sọ pé àwọn Kristẹni á rí gbà bí wọ́n bá ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ àti afọ́jú nígbà tí wọ́n bá se àsè? (Lúùkù 14:13, 14)
7. Béèyàn bá kú, kí ló máa ń kú pẹ̀lú ẹ̀? (Oníwàásù 9:6)
8. Báwo ni ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ka àkókò ṣe yàtọ̀ sí tiwa? (2 Pétérù 3:8)
9. Báwọn Kristẹni bá ń kọ́ agbára ìwòye wọn, èrè wo ni wọ́n lè retí pé àwọn á rí nínú ẹ̀? (Hébérù 5:14)
10. Kí ló fà á tí Báláámù fi lu abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀? (Númérì 22:22-25)
11. Kí ni orúkọ aṣọ gígùn tí àlùfáà àgbà máa ń wọ̀ sórí àwọ̀lékè rẹ̀ tí kò lápá tí wọ́n fi òwú aláwọ̀ búlúù ṣe? (Ẹ́kísódù 28:4, 31)
12. Ìlú wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ṣìkejì lẹ́yìn tí wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì? (Jóṣúà 8:18, 19)
13. Nínú gbogbo opó tó wà lákòókò Èlíjà, èwo ni Jésù sọ pé Ọlọ́run rán Èlíjà sí? (Lúùkù 4:26)
14. Báwo ni Jésù ṣe sọ pé ká máa bá àwọn tó bá kórìíra wa lò? (Mátíù 5:44)
15. Kí ni ìyá Sólómọ́nì hun fún un lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? (Orin Sólómọ́nì 3:11)
16. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ṣe sọ, kí nìdí tí ẹni yíyára kì í fi í gbégbá orókè nínú eré ìje nígbà míì? (Oníwàásù 9:11)
17. Kí lorúkọ àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù méjèèjì, tí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjì ti ara wọn wá? (Jẹ́nẹ́sísì 41:50-52)
18. Ọdún mélòó ni Jákọ́bù sọ fún Fáráò pé òun ti fi ṣe àtìpó? (Jẹ́nẹ́sísì 47:7-9)
19. Kí ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ jẹ ní ìrọ̀lẹ́ tó lò kẹ́yìn kó tó kú? (Lúùkù 22:20)
20. Kí lorúkọ ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà tí Pétérù mú lára dá lẹ́yìn tó ti fi ọdún mẹ́jọ dùbúlẹ̀ sórí àkéte? (Ìṣe 9:33, 34)
21. Ta ni Bíbélì pè ní “ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè”? (Jẹ́nẹ́sísì 3:20)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Bẹtisáídà
2. Kéfà
3. Ẹrú wọn
4. Úrì
5. Iṣẹ́ wíwò ni, ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ló sì jẹ́ lójú Jèhófà
6. Wọ́n á láyọ̀, Ọlọ́run ló sì máa san án padà fún wọn, nítorí wọn ò retí pé káwọn rí ohunkóhun gbà padà
7. Ìfẹ́ rẹ̀, ìkórìíra rẹ̀ àti owú rẹ̀
8. Lọ́dọ̀ Jèhófà ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí ọjọ́ kan
9. Wọ́n á dàgbà dénú, wọ́n á sì lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́
10. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Ọlọ́run tó dúró sójú ọ̀nà, ó gbìyànjú láti yà lọ sínú pápá
11. Éfódì
12. Áì
13. Opó ‘Sáréfátì ní ilẹ̀ Sídónì’
14. Ẹ “máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín”
15. Ọ̀ṣọ́ òdòdó
16. Nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀”
17. Mánásè àti Éfúráímù
18. Àádóje [130]
19. Oúnjẹ alẹ́
20. Énéà
21. Éfà