ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g05 5/8 ojú ìwé 31
  • Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?
  • Jí!—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orukọ Ọlọrun ati Awọn Atumọ Bibeli
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
Àwọn Míì
Jí!—2005
g05 5/8 ojú ìwé 31

Ṣé Ó Yẹ Ká Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?

NÍ ỌDÚN 1901, wọ́n tẹ Bíbélì ìtumọ̀ American Standard, èyí sì jẹ́ àtúnṣe sí Bíbélì King James Version, tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 1611. Lọ́dún 1902, ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ The Presbyterian and Reformed Review gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nípa Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí. Nínú àpilẹ̀kọ yẹn, ìwé ìròyìn yẹn sọ̀rọ̀ lórí bóyá ó yẹ kí wọ́n máa lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, níbi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí kò yẹ, àpilẹ̀kọ náà kà pé:

“Àwa olóòtú ìwé ìròyìn yìí kò mọ̀dí tí èrò àwọn èèyàn ò fi jọra lórí bóyá ó tọ́ láti máa lo orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì tàbí kò tọ́. Orúkọ Olúwa fúnra rẹ̀ nìyẹn, orúkọ yìí ni Ó sì yàn pé káwọn èèyàn Òun fi mọ Òun. Lójú tiwa àdánù ńláǹlà ló jẹ́ báwọn èèyàn ṣe ń fi orúkọ oyè dipò orúkọ Ọlọ́run. A kò ṣàìmọ̀ dájú pé àríyànjiyàn wà lórí bó ṣe yẹ ká máa kọ orúkọ náà àti bó ṣe yẹ ká máa pè é, kò sì sẹ́ni tó lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ‘Jèhófà’ tí wọ́n ń pè é báyìí, ló yẹ kí wọ́n máa pè é. Síbẹ̀, bá a ṣe ń sípẹ́lì rẹ̀ yìí, orúkọ Ọlọ́run lẹni tó ń ka èdè Gẹ̀ẹ́sì ń kà á sí. Téèyàn bá sì fi ọ̀rọ̀ bíi Yahwé tàbí àwọn ọ̀rọ̀ míì táwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ máa ń lò rọ́pò rẹ̀, ńṣe lá dà bí ìgbà téèyàn ń rin kinkin lórí ìlànà. Àti pé kò tiẹ̀ dájú pé ọ̀rọ̀ táwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń pè é yìí gan-an bá orúkọ náà mu. A sì gbà pé èrè ńláǹlà ló máa jẹ́ fẹ́ni tó ń ka Májẹ̀mú Láéláé lédè Gẹ̀ẹ́sì nígbà tó bá kọ́kọ́ rí ọ̀rọ̀ náà ‘Jèhófà’ nínú ìtumọ̀ Bíbélì tó wọ́pọ̀, tóun fúnra rẹ̀ ń kà, tó sì wá mọ bí ‘Jèhófà’ ṣe jẹ́ sí àwọn èèyàn rẹ̀ àti ohun tó ń ṣe fún wọn.”

Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn lédè Gẹ̀ẹ́sì ló ti lo orúkọ náà “Jèhófà” tàbí ọ̀nà mìíràn tí wọ́n gbà ń kọ orúkọ Ọlọ́run. Bákan náà, á rí orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì tí kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì, irú bí àwọn tẹ́ ẹ̀ ń wò lójú ìwé yìí. Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Mósè sọ̀rọ̀ nípa orúkọ rẹ̀, Jèhófà, ó sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kò gbọ́dọ̀ sí ìyeméjì lórí bóyá ó tọ̀nà pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run lákòókò wa yìí!—Ẹ́kísódù 3:13-15.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Sáàmù 83:18, bó ṣe wà lónírúurú èdè

Tsonga

Union Shona

Vietnamese

Spanish

Hindi

Tagalog

Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́