Ó Rán An Létí Àwọn Nǹkan Tó Nífẹ̀ẹ́ Sí
Lẹ́yìn tí obìnrin kan ti gba ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, ó pinnu láti mú ẹ̀dà kan lọ sọ́dọ̀ àǹtí rẹ̀. Àǹtí rẹ̀ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, ó sì ní àrùn ọdẹ orí tó máa ń bọ́jọ́ ogbó rìn. Àmọ́, fún àádọ́rin ọdún ló ti fi ara ẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti kíkọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ rántí nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ mọ́, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀.
Obìnrin tó mú ìwé wa tọ àǹtí rẹ̀ lọ yìí níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Lọ́jọ́ àkọ́kọ́, mo ṣàlàyé pé wọ́n ṣe ìwé náà láti ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbin àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ Bíbélì sáwọn ọmọ wọn lọ́kàn àti pé ó wù mí kí n kà á fún un. Kò dún pẹ́nkẹ́n. Àmọ́, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kà á, ọkàn rẹ̀ sọjí, ó sì ń dáhùn gbogbo ìbéèrè tá à ń bá pàdé nínú ìwé náà. Láwọn ìgbà míì tí mo bá ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, iyè rẹ̀ a sọ sí i pó ti kà á rí nígbà tó wà léwe, á sì bá mi parí ẹ̀, àmọ́ bó ṣe wà nínú ìtumọ̀ Bíbélì King James Version ló ṣe máa ń kà á. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bí mo bá ń sọ ìtàn Bíbélì kan, á gbá mi lọ́wọ́ mú, á sì sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo rántí ìtàn yẹn!’
“Nígbà tó kù díẹ̀ ká máa padà relé, tí mo sì ti kà kọjá ìdajì lára ìwé náà sí i létí, ó sọ pé á wu òun láti máa gbọ́ ọ nìṣó. Bí ọkọ ẹ̀, tí kò jẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣeré ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ka apá tó kù nínú ìwé náà fún un nìyẹn. Ọ̀ràn ti àǹtí mi yìí ló jẹ́ kí n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ka irú ìwé bẹ́ẹ̀ fáwọn àgbàlagbà àtàwọn aláìlera.”
Tàgbà tèwe ló ń gbádùn kíka ìwé olójú ewé 256, tó ní àwòrán rírẹwà tó sì fẹ̀ tó ìwé ìròyìn yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè tó rọrùn ni wọ́n fi kọ àwọn ìtàn inú ẹ̀, tó dá lórí ohun tí Jésù Kristi fi kọ́ni, kò sẹ́ni tí ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ ò wúlò fún. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.