ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 32
  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa
  • Jí!—2006
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 32

Ìrànlọ́wọ́ Láti Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Wa

Léṣìí, obìnrin kan láti ìpínlẹ̀ Virginia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé láti fi dúpẹ́ pé òun rí ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, gbà ó sì sọ pé: “Káwọn ọmọ ọmọ mi tó lọ sùn, wọ́n máa ń sọ fún mi pé: ‘Ìyá àgbà, ẹ ka ìtàn kan fún wa látinú ìwé Jésù.’ Ọmọ ọdún mẹ́rin, mẹ́fà àti méje làwọn ọmọkùnrin yìí, wọ́n sì fẹ́ràn àwọn ìtàn náà gan-an.”

Ìyá àgbà náà ṣàlàyé pé: “Mo ka orí 32 tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ ‘Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù.’ Ó wú mi lórí gan-an pé lẹ́yìn tí àkòrí náà sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Jésù, àkòrí náà tún ṣàlàyé báwọn èwe ṣe lè dáàbò bo ara wọn nípa fífún wọn ní ìmọ̀ràn tó wúlò. Ìwé náà sọ pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi [ẹ̀yà ìbímọ rẹ] ṣeré, kí o kọ̀, kí o sì kígbe sókè gan-an, pé: “Rárá o! Màá fẹjọ́ yín sùn!”’”

Lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ìyá kan tó ní ọmọbìnrin ọlọ́dún márùn-ún kan tó ń jẹ́ Betsaida sọ pé ìgbà kejì rèé tóun ti ń ka ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà fún ọmọ òun. Ìyá yìí sọ pé: “Ṣe ni ayé yìí túbọ̀ ń burú sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni wàhálà tó ń dojú kọ àwọn ọmọ wa kéékèèké ń lágbára sí i. Ọmọbìnrin mi sọ pé òun dúpẹ́ fún ìtọ́ni nípa bóun ṣe lè dáàbò bo ara òun lọ́wọ́ àwọn tó lè fẹ́ kó bá òun, bí àwọn tí ìwé náà sọ ní orí 32.”

Ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà ni ìwé yìí, tó ní ojú ewé 256 tó sì ní oríṣiríṣi àwòrán ti ṣe nínú ríran àwọn òbí lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìtọ́ni Bíbélì pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Òwe 22:6) Èdè tó rọrùn la fi ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀, èyí tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi fi kọ́ni, síbẹ̀ ó wúlò fún tàgbà tèwe láìka ọjọ́ orí sí. Bó o bá fẹ́ gba ẹ̀dà kan, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́