Ohun Tí Àwọn Òbí Sọ
Ní gbogbo àkókò tí àwọn ọmọ fi ń bàlágà, onírúurú ìṣòro làwọn òbí máa ń dojú kọ. Báwo lo ṣe lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí ní àkókò yìí ní ìgbésí ayé rẹ̀, èyí tó lè mú kí nǹkan tojú sú u bó ṣe máa ń tojú sú ìwọ náà? Gbọ́ ohun tí àwọn òbí kárí ayé sọ.
ÀWỌN ÀYÍPADÀ
“Nígbà tí ọmọ mi ọkùnrin ṣì kéré, gbogbo ohun tí mo bá sọ fún un ló máa ń ṣe láìjanpata. Àmọ́, láàárín ìgbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ó jọ pé kì í fẹ́ tẹ̀ lé àṣẹ tí mo bá pa fún un mọ́. Kì í fara mọ ohun tí mo bá sọ àti ọ̀nà tí mo gbà sọ ọ́.”—Frank, Kánádà.
“Ọmọ mi ọkùnrin kì í sọ̀rọ̀ púpọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Mo ní láti béèrè ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, dípò tí màá fi máa retí pé kó fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀. Mi ò sì lè fi ipá mú un láti dáhùn ohun tí mo bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Kì í ṣe pé kò ní dáhùn o, àmọ́ kì í ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”—Francis, Ọsirélíà.
“Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kéèyàn máa ṣe sùúrù. Nígbà míì ó máa ń ṣe wá bíi pé ká jágbe mọ́ àwọn ọmọ wá, àmọ́ tá a bá fọwọ́ wọ́nú, tí àwa àtàwọn ọmọ sì jọ sọ̀rọ̀, ìyẹn máa ń sèso rere!”—Felicia, Amẹ́ríkà.
ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀
“Nígbà míì ọmọ mi obìnrin tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún máa ń fẹ́ ṣe àwáwí, nígbà míì ó sì máa ń ronú pé ńṣe ni mò ń wá ẹ̀sùn sí òun lẹ́sẹ̀. Mo ní láti jẹ́ kò mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé mo fẹ́ kó ṣe àṣeyọrí!”—Lisa, Amẹ́ríkà.
“Nígbà tí àwọn ọmọ mi ṣì kéré, gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n máa ń sọ fún mi. Kò ṣòro fún mi rárá láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Àmọ́ ní báyìí, mo ní láti sapá kí n tó lè lóye wọn, kí n sì fi hàn pé mo bọ̀wọ̀ fún wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn nìkan ló máa jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún mi.”—Nan-hi, Kòríà.
“Kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn kàn sọ fún àwọn ọmọ tó ti bàlágà pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan pàtó kan. A ní láti fèrò wérò pẹ̀lú wọn, ká sì jọ sọ ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Kí èyí lè ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ múra tán láti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ, kódà bí àwọn nǹkan tí a kò fẹ́ gbọ́ bá tiẹ̀ wà nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ.”—Dalila, Brazil.
“Bí mo bá fẹ́ bá ọmọ mi obìnrin wí, mo máa ń gbìyànjú kí n bá a wí tó bá ku èmi pẹ̀lú ẹ̀ nìkan, dípò tí máa fi bá a wí lójú àwọn èèyàn.”—Edna, Nàìjíríà.
“Nígbà míì, tí mo bá ń bá ọmọ mi ọkùnrin sọ̀rọ̀, àwọn nǹkan míì tí mò ń ṣe nínú ilé máa ń gbà mí lọ́kàn, mi ò sì ní fi gbogbo ọkàn sí ohun tí à ń sọ. Ó kíyè sí èyí, mo sì ronú pé ìyẹn wà lára ìdí tó fi jẹ́ pé kì í fi taratara bá mi sọ̀rọ̀ mọ́. Mo ní láti máa pọkàn pọ̀ dáadáa tó bá ń bá mi sọ̀rọ̀, kó lè túbọ̀ máa sọ ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ̀ fún mi.”—Miriam, Mẹ́síkò.
ÒMÌNIRA
“Ẹ̀rù máa ń bà mí láti fún àwọn ọmọ mi tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún lómìnira, èyí sì wà lára ohun tó máa ń dá wàhálà sílẹ̀. Mo bá wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Mo ṣàlàyé ohun tó ń bà mí lẹ́rù fún wọn, àwọn náà sì sọ ìdí tí wọ́n fi ń fẹ́ kí n fún wọn ní òmìnira díẹ̀ sí i. A sì jọ fohùn ṣọ̀kan lórí ibi tí màá fún wọn ní òmìnira dé.”—Edwin, Gánà.
“Ọmọ mi ọkùnrin fẹ́ rá alùpùpù. Àmọ́ nítorí pé mi ò fara mọ ohun tó fẹ́ ṣe yìí, mo fìbínú sọ̀rọ̀ sí i, mo sọ ohun tí kò dáa nípa ríra alùpùpù, mi ò sì fún un láyè láti ṣàlàyé ara rẹ̀. Ìyẹn múnú bí i, ó sì wá jẹ́ kó ranrí pé àfi kí òun rà á! Mo pinnu pé màá bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà míì. Mo sọ fún un pé kó ronú nípa ọ̀rọ̀ náà dáadáa, kó ronú nípa ewu tó wà níbẹ̀, owó tó máa ná àti àwọn ohun tí òfin béèrè láti ní ìwé àṣẹ. Mo tún sọ fún un pé kó gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn nínú ìjọ. Mo wá rí i pé dípò tí màá fi máa pàṣẹ fún ọmọ mi, ohun tó dáa jù ni pé kí n jẹ́ kó sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ohun tó wù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, màá lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.”—Hye-young, Kòríà.
“A máa ń sọ fún àwọn ọmọ wa pé ó níbi tá a lè gbà wọ́n láyè mọ, ṣùgbọ́n díẹ̀díẹ̀ la máa ń fún wọn ní òmìnira. Bí wọ́n bá lo òmìnira tá a fún wọn lọ́nà tó dáa, a máa tún fún wọn lómìnira tó pọ̀ sí i. A sọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe ká lè máa fún wọn ní òmìnira, a jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tá a fẹ́ ni pé kí wọ́n ní òmìnira láti ṣe ohun tí wọn fẹ́ ṣe; àmọ́ a sọ fún wọn pé bí wọ́n bá ti ṣi òmìnira tá a fún wọn lò, wọ́n máa jìyà rẹ̀.”—Dorothée, Faransé.
“Mi ò kì í fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìlànà tí mo bá fi lélẹ̀. Àmọ́ bí àwọn ọmọ mi bá ṣègbọràn, mo ṣe tán láti yọ̀ǹda àwọn nǹkan kan fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ń fún wọn láyè láti pẹ́ níta ju bí mo ṣe yọ̀ǹda fún wọn lọ. Àmọ́ bí wọ́n bá wá ki àṣejù bọ̀ ọ́, wọ́n máa jìyà rẹ̀.”—Il-hyun, Kòríà.
“Bí òṣìṣẹ́ kan bá ṣe ń ṣègbọràn sí tó sì ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ rẹ̀ ni ọ̀gá rẹ̀ á ṣe máa gbà á láyè láti ṣe àwọn nǹkan kan. Bákan náà, ọmọ mi ọkùnrin ti rí i pé bí òun bá ṣe ń ṣègbọràn sí tí òun kò sì ń kọjá àyè òun, bẹ́ẹ̀ ni òun á ṣe máa ní òmìnira púpọ̀ sí i. Ọmọ mi mọ̀ pé bó ṣe jẹ́ pé òṣìṣẹ́ kan lè jìyà tí kò bá ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe tọ́, òun náà lè pàdánù òmìnira tí mo fún un bí kò bá fọwọ́ pàtàkì mú un.”—Ramón, Mẹ́síkò.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
“Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
ÌSỌFÚNNI NÍPA ÌDÍLÉ
“A Gbádùn Títọ́ Àwọn Ọmọ Wa Tí Wọ́n Ti Bàlágà”
Joseph: Àwọn ọmọ mi obìnrin méjì tí wọ́n dàgbà jù kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, àmọ́ mo rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí n máa fetí sí wọn kí n sì ka èrò wọn sí pàtàkì. Mo máa ń gba àwọn àṣìṣe mi, mo sì máa ń fọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ọmọbìnrin mi, èyí jẹ́ kí wọ́n lè máa bá mi sọ̀rọ̀. Ní kúkúrú, a gbádùn títọ́ àwọn ọmọ wa tí wọ́n ti bàlágà, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìtọ́sọ́nà tá a rí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Lisa: Mo kíyè sí i pé nígbà tí ọmọbìnrin wa tó dàgbà jù pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ó nílò àfiyèsí mi gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo rántí bí mo ṣe máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò tẹ́tí sí i, tí mò ń bá a sọ̀rọ̀, tí mo sì ń fí i lọ́kàn balẹ̀. Èmi àti ọkọ mi jẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin wa mọ̀ pé wọ́n lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn àti pé a máa ka èrò wọn sí. Mo gbìyànjú láti fi ohun tó wà nínú Jákọ́bù 1:19 sílò, èyí tó sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”
Victoria: Mọ́mì mi ni ọ̀rẹ́ mi tó sún mọ́ mi jù lọ. Mi ò tíì pàdé ẹnì kankan tó ṣèèyàn tó sì bìkítà bíi tiwọn, bí wọ́n sì ṣe ń ṣe sí gbogbo èèyàn nìyẹn. Mi ò mọ ọ̀rọ̀ tí mo lè fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ju kí n sọ pé “abiyamọ tòótọ́” ni wọ́n. Ìyá tí kò lẹ́gbẹ́ ni wọ́n.
Olivia: Dádì mi bìkítà gan-an, wọ́n sì lawọ́. Wọ́n máa ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe pé àwa náà ní nǹkan tó pọ̀. Dádì mi kì í gba gbẹ̀rẹ́ o, àmọ́ wọ́n tún mọ béèyàn ṣe ń gbádùn ara ẹ̀ dáadáa. Bàbá gidi ni wọ́n, inú mi sì dùn pé àwọn ló bí mi!
“Ilé Kì Í Sú Wa!”
Sonny: Bí àwọn ọmọbìnrin wa bá ní ìṣòro, ìdílé wa á jókòó pa pọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A kì í fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún ara wa, orí àwọn ìlànà Bíbélì la sì máa ń gbé àwọn ìpinnu wa kà. Èmi àti Ynez ìyàwó mi sì rí i dájú pé àwọn èèyàn rere tó ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù ni àwọn ọmọ wa ń bá rìn. Àwọn ọ̀rẹ́ wa ni ọ̀rẹ́ wọn, àwọn ọ̀rẹ́ tiwọn náà sì lọ̀rẹ́ wa.
Ynez: A kì í jókòó gẹlẹtẹ, a sì máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a máa ń wàásù dáadáa, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ìdílé wa sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀, a tún máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni, irú bíi ṣíṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́, ọ̀rọ̀ wa kì í ṣe iṣẹ́ laago ń ṣe kú o, a tún máa ń gbádùn ara wa. Ilé kì í sú wa!
Kellsie: Dádì mi máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa, kí wọ́n sì tó ṣe ìpinnu tó lágbára, wọ́n máa ń fi tó gbogbo wa létí. Gbogbo ìgbà ni mọ́mì mi náà máa ń ráyè gbọ́ témi, bóyá mo nílò ìrànlọ́wọ́ wọn ni o tàbí mo fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀.
Samantha: Mọ́mì mi máa ń ṣe ohun tó jẹ́ kí n mọ̀ pé èèyàn pàtàkì ni mo jẹ́, pé àwọn nífẹ̀ẹ́ mi àti pé èèyàn iyì ni mí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn lè má mọ bí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ṣe ní ipa lórí mi tó. Wọ́n máa ń fetí sílẹ̀. Wọ́n bìkítà. Mo mọyì àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní gan-an ni.
[Àwòrán]
Ìdílé Camera: Joseph, Lisa, Victoria, Olivia, àti Isabella
Ìdílé Zapata: Kellsie, Ynez, Sonny, àti Samantha
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn ní òmìnira dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ wọ́n tún ní láti sọ àwọn ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe fún wọn