ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/12 ojú ìwé 25
  • Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti Ìlera

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti Ìlera
  • Jí!—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ní Ń Fúnni Ní Ọgbọ́n”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Pa Ọkàn-àyà Rẹ Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ní Ọkàn-àyà Tó Tẹ́ Jèhófà Lọ́rùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-àyà Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—2012
g 1/12 ojú ìwé 25

Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti Ìlera

“Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.”—ÒWE 14:30.

“Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”—ÒWE 17:22.

● Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye, tó sì jinlẹ̀ lọ́kàn ẹni yìí.a Ṣùgbọ́n, ṣé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ náà? Kí ni àwọn onímọ̀ ìṣègùn òde òní sọ nípa rẹ̀?

Nígbà tí ìwé kan tó ń jẹ́ Journal of the American College of Cardiology ń sọ̀rọ̀ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn jẹ́jẹ́ àtàwọn tó sábà máa ń bínú, ó sọ pé: “Ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn tó bá ń bínú gan-an tí wọ́n sì jẹ́ òṣónú máa ń ní àrùn nínú iṣan tó máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ wọnú ọkàn.” Ìwé náà tún wá sọ pé: ‘Béèyàn bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àrùn ọkàn yìí, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣíṣe eré ìmárale àti lílo oògùn nìkan, ó tún gba pé kí wọ́n ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣàkóso èrò inú wọn, kí wọ́n máa fiyè dénú, kí wọ́n má sì jẹ́ òṣónú.’ Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gan-an ló ṣe rí. Bí èèyàn kì í bá bínú sódì, ó máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ìlera tó dáa.

Bí èèyàn bá jẹ́ ẹni tí inú rẹ̀ máa ń dùn, ìyẹn pẹ̀lú máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ìlera tó dáa. Dókítà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Derek Cox, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera lórílẹ̀-èdè Scotland, sọ nínú ìròyìn kan ní Ilé Iṣẹ́ Rédíò Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (BBC) pé: “Tó bá jẹ́ pé inú rẹ sábà máa ń dùn, tó bá di ọjọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o kò ní máa ṣàìsàn bíi ti àwọn tí inú wọn kì í dùn.” Ìròyìn náà tún sọ pé: “Àwọn tí inú wọn máa ń dùn sábà máa ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro bí àrùn ọkàn àti rọpárọsẹ̀.”

Kí nìdí tí ọgbọ́n Sólómọ́nì àtàwọn òǹkọ̀wé Bíbélì míì fi wúlò gan-an títí di àkókò tá a wà yìí? Ìdáhùn ìbéèrè yìí kò ṣòro rárá. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi.” (1 Ọba 4:29) Bákan náà, ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yẹn kò ṣòro láti lóye, èyí mú kí gbogbo èèyàn lè jàǹfààní látinú rẹ̀. Ohun míì tún ni pé, ọ̀fẹ́ la gbà á!

O ò ṣe sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ti wá rí ayọ̀ ńláǹlà nínú ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” (Òwe 2:10, 11) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ yìí kò fini lọ́kàn balẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” sábà máa ń túmọ̀ sí irú ẹni téèyàn jẹ́ gan-an, títí kan bí nǹkan ṣe máa ń rí lára onítọ̀hún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́