ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/13 ojú ìwé 12-13
  • Bá Wa Ká Lọ Sí Ilẹ̀ Kamẹrúùnù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá Wa Ká Lọ Sí Ilẹ̀ Kamẹrúùnù
  • Jí!—2013
Jí!—2013
g 1/13 ojú ìwé 12-13
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

ṢÉ O MỌ ILẸ̀ YÌÍ?

Bá Wa Ká Lọ sí Ilẹ̀ Kamẹrúùnù

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 12]

Ó ṢEÉ ṣe kó jẹ́ pé àwọn Bákà, táwọn èèyàn tún mọ̀ sí àwọn kúrékùré ni wọ́n tẹ ilẹ̀ Kamẹrúùnù dó. Àmọ́ láàárín ọdún 1500 sí 1599, àwọn Potogí náà dé síbẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, àwọn Fúlàní tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí gbógun ja àríwá ilẹ̀ Kamẹrúùnù wọ́n sì ṣẹ́gun. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, tá a bá pín iye èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù sọ́nà mẹ́wàá, ìdá mẹ́rin nínú wọn ló máa sọ pé ẹlẹ́sìn Kristẹni làwọn, ìdá méjì jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, nígbà tí ìdá mẹ́rin yòókù jẹ́ ẹlẹ́sìn àbáláyé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ni èdè Bassa, tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù

Àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn ìgbèríko ilẹ̀ Kamẹrúùnù lọ́yàyà, wọ́n sì fẹ́ràn àlejò. Bí wọ́n bá rí àlejò, wọ́n á kí i dáadáa, wọ́n á sì ní kó wọlé kí wọ́n lè fún un ní oúnjẹ àti omi. Tí àlejò yẹn kò bá gba ohun tí wọ́n gbé fún un, wọ́n gbà pé ó ti kan àwọn lábùkù nìyẹn. Àmọ́ bó bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fi lọ̀ ọ́, inú wọn á dùn pé ó pọ́n àwọn lé.

Ìkíni ni wọ́n fi máa ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn. Àlejò yẹn á kí gbogbo àwọn ará ilé, á sì béèrè àlàáfíà wọn. Wọ́n tiẹ̀ tún máa ń béèrè àlàáfíà àwọn ẹran ọ̀sìn wọn pàápàá! Ọ̀gbẹ́ni Joseph tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kamẹrúùnù sọ pé: “Tí àlejò wa bá ń lọ, kì í ṣe àṣà wa pé ká kàn yísẹ̀ pa dà lẹ́nu ọ̀nà. A máa ń sin àlejò wa dé ọ̀nà. A ó sì jọ máa sọ̀rọ̀ bá a ṣe ń lọ. Tó bá wá ṣe díẹ̀, a ó kí wọn pé ó dàbọ̀, a ó sì pa dà sílé. Bí a ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún àlejò kan, ó lè máa rò pé inú wa ò dùn sóun dáadáa.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi igi gbẹ́ làwọn èèyàn sábà máa ń wọ̀ lórí Odò Sanaga. Oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n bá rí i pé ó dáa ni wọ́n máa fi ń ṣe ìgbòkun ọkọ̀

Nígbà míì, àwọn tí wọ́n bá jẹ́ ọ̀rẹ́ máa ń jẹun pa pọ̀ nínú àwo kan náà. Ó sì lè jẹ́ ọwọ́ ni wọ́n á fi jẹun. Lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, wọ́n ka àṣà yìí sí pàtàkì gan-an torí ó jẹ́ àmì pé wọ́n wà níṣọ̀kan. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ti fi parí ìjà láàárín àwọn kan tí ọ̀rẹ́ wọn ò wọ̀ mọ́. Ohun tí àṣà yìí túmọ̀ sí ni pé, bí wọ́n bá ti lè jọ jẹun nínú àwo kan náà, “ìjà ti parí” nìyẹn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí. Iye ìjọ wa tó wà lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300]. Iye èèyàn tá a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè náà tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùn-lé-lọ́gọ́ta [65,000]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KAMẸRÚÙNÙ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn Kúrékùré ilẹ̀ Kamẹrúùnù tí wọ́n ti dàgbà kì í fi bẹ́ẹ̀ ga jù ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin àtààbọ̀ lọ

  • Iye Èèyàn: Nǹkan bí ogún [20] mílíọ̀nù

  • Olù Ìlú: Yaoundé

  • Ojú Ọjọ́: Ooru máa ń mú ní àríwá, àmọ́ ojú ọjọ́ máa ń tutù láwọn etíkun

  • Ohun Àmúṣọrọ̀: Epo rọ̀bì, kòkó, kọfí, òwú, igi àti tángaran

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé àti nǹkan bí àádọ́rin-lérúgba [270] àwọn èdè ìbílẹ̀ míì to jẹ́ ti ilẹ̀ Áfíríkà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́