ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 3/15 ojú ìwé 3
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Wúlò Fún Wa Lónìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Bíbélì Wúlò Fún Wa Lónìí?
  • Jí!—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Wúlò Lóde Òní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
  • Àwọn Ìwà Rere Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dára
    Jí!—2014
  • Oro Isaaju
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Fìfẹ́ Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Jí!—2015
g 3/15 ojú ìwé 3

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ Bíbélì Wúlò Fún Wa Lónìí?

‘Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí màá láyọ̀ láyé mi.’

Ọ̀GBẸ́NI kan tó ń jẹ́ Hilton gbádùn eré àwọn tó máa ń kan ẹ̀ṣẹ́, àtìgbà tó sì ti wà ní ọmọ ọdún méje ló ti n kan ẹ̀ṣẹ́ kiri! Nígbà tó wà níléèwé gíga, ńṣe lòun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń rìn kiri inú ọgbà láti wá ẹni tí wọ́n máa lù. Hilton sọ pé nígbà yẹn, “mo máa ń jalè, mò ń ta tẹ́tẹ́, mò ń wo ìwòkuwò, mo máa ń fòòró àwọn obìnrin, mo tún máa ń bú àwọn òbí mi. Ìwà mi burú débi pé àwọn òbí mi ò rò pé mo lè yíwà pa dà mọ́ láé. Nígbà tí mo jáde iléèwé, mo kúrò nílé.”

Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí Hilton pa dà wálé, àwọn òbí rẹ̀ ṣì í mọ̀, ńṣe ló ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kò fa wàhálà mọ́, ó sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Kí ló ran Hilton lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà yìí? Nígbà tó kúrò nílé lọ́dún náà lọ́hùn-ún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Ó wá ṣàyẹ̀wò Bíbélì kó lè rí ìrànlọ́wọ́ tó máa mú kó yíwà pa dà. Hilton sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tí mò ń kọ́ sílò, èyí gba pé kí n jáwọ́ nínú àwọn ìwà mi àtijọ́, kí n sì máa tẹ̀ lé àṣẹ tó wà nínú ìwé Éfésù 6:2, 3 tó ni ká bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wa. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí mo ṣe ohun tó múnú àwọn òbí mi dùn, tó sì fún èmi náà láyọ̀!”

Ìtàn ráńpẹ́ tá a sọ nípa Hilton yìí fi hàn pé Bíbélì máa ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe. (Hébérù 4:12) Bíbélì lè mú ká ní àwọn ìwà rere bíi jíjẹ́ olóòótọ́, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfẹ́ àti ìṣòtítọ́ láàárín tọkọtaya. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn nǹkan yìí ṣe lè mú kí ayé wa dára sí i.

Ǹjẹ́ Bíbélì Bá Ìgbà Mu?

Ojú táwọn èèyàn fi n wo fóònù ayé àtijọ́ làwọn míì fi ń wo Bíbélì. Ẹni bá ń fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wo Bíbélì kò ríran kọjá igi imú rẹ̀, ó sì ń tan ara rẹ̀ jẹ lásán ni. Fóònù tó lòde lónìí lè máà bá ìgbà mu lọ́la, àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa èèyàn ò rí bẹ́ẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ ìfẹ́, ìṣòtítọ́, ìwà ìkà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ṣe rí lára àwọn baba ńlá wa náà ló ṣe rí lára tiwa náà lónìí, kò sí ìyàtọ̀. Torí náà tọ́rọ̀ bá kan bí ìwà àwa èèyàn ṣe rí, àá rí i pé, “kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.”—Oníwàásù 1:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́