ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g16 No. 6 ojú ìwé 4-6
  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àrùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àrùn
  • Jí!—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 OMI
  • 2 OÚNJẸ
  • 3 KÒKÒRÒ
  • 4 ẸRANKO
  • 5 ÈÈYÀN
  • Ohun Tó Máa Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I
    Jí!—2015
  • Ohun 4—Ṣọ́ra fún Ohun Tó Lè Ṣàkóbá fún Ìlera Rẹ
    Jí!—2011
  • Fáírọ́ọ̀sì Panipani Kọ Lu Zaire
    Jí!—1996
  • Kí Ló Dé Tí Wọ́n Tún Fi Ń Padà Wá?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—2016
g16 No. 6 ojú ìwé 4-6

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ ÀRÙN

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àrùn

LÁYÉ àtijọ́, wọ́n máa ń mọ ògiri gìrìwò yí ìlú ká láti dáàbò bò ó. Bí àwọn ọ̀tá bá rí àlàfo kékeré gbà wọlé, gbogbo ìlú náà kó sí wàhálà nìyẹn. Bákan náà, ara wa dà bí ìlú tí ògiri yíká. Àmọ́ bí a ṣe ń bójú tó ara wa ló máa pinnu bí ìlera wa ṣe máa rí. Jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà márùn-ún tó ṣeé ṣe kí àrùn gbà wọlé sí wa lára àti bí a ṣe lè dènà wọn.

Ìyá àtọmọ ń gba àárín ọjà kọjá

1 OMI

EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn lè “wọlé” sínú àgọ́ ara wa látinú omi tó dọ̀tí.

BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Ohun tó gbéṣẹ́ jù tó o lè ṣe ni pé kí ó má ṣe jẹ́ kí ìdọ̀tí wọnú omi rẹ. Àmọ́ tó o bá kíyè sí pé ìdọ̀tí ti wọnú rẹ̀, o lè fi oògùn apakòkòrò sínú ẹ̀.a Jẹ́ kí omi máa wà nínú ohun tó ní ìdérí, kọ́ọ̀bù tó ní ọwọ́ ni kó o sì máa fi bù ú tàbí kó o ṣe ẹnu ẹ̀rọ sí i. Má ṣe máa kọwọ́ bọ inú omi. Tó bá ṣeé ṣe, rí i dájú pé àdúgbò tó mọ́ tónítóní lò ń gbé, kó sì jẹ́ ibi tí wọn kò fi ìgbẹ́ tàbí ìtọ̀ bà jẹ́.

2 OÚNJẸ

EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn lè wà nínú oúnjẹ

BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Àwọn oúnjẹ míì lè ní ìdọ̀tí tàbí májèlé nínú síbẹ̀ kó fani mọ́ra. Torí náà, fi kọ́ra láti máa fọ àwọn èso àti ẹ̀fọ́ rẹ dáadáa kó o tó jẹ ẹ́. Rí i dájú pé àwọn nǹkan ìdáná àti nǹkan ìjẹun rẹ títí kan ibi tó o ti ń dáná tàbí jẹun, wà ní mímọ́ tónítóní. Àwọn oúnjẹ kan wà tó o ní láti sè dáadáa torí àwọn kòkòrò tó lè fa àrùn. Ṣọ́ra fún jíjẹ́ oúnjẹ tó o bá fura sí pé ó ti ń bàjẹ́ tàbí tí àwọ̀ rẹ̀ ti yí pa dà tàbí tó ti ń rùn. Gbé oúnjẹ tí o kò bá jẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sínú fìríìjì. Má sì ṣe dáná oúnjẹ fún ẹnikẹ́ni nígbà tí ara rẹ kò bá yá.b

3 KÒKÒRÒ

EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò kan máa ń gbé ohun tó lè fa àrùn kiri, wọ́n sì lágbára láti kó àrùn tó wà lára wọn ran èèyàn.

BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Máa yẹra fún àwọn kòkòrò tó máa ń kó àrùn ranni. Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o wọ aṣọ tó bo ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tàbí kó o má ṣe jókòó síta lákòókò táwọn kòkòrò náà bá ń fò kiri. Ó tún lè sùn sábẹ́ nẹ́ẹ̀tì apẹ̀fọn tàbí kó o lo oògùn ẹ̀fọn. Tètè máa da omi ìdọ̀tí nù kí àwọn ẹ̀fọn tó sọ ibẹ̀ dilé.c

4 ẸRANKO

EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn tó ń gbénú ẹranko láìpa wọn lára lè hàn àwa èèyàn léèmọ̀. Bí ẹranko bá fi èékánná ya wá tàbí tó bá gé wá jẹ tàbí tá a fẹsẹ̀ kó ìgbẹ́ rẹ̀, a lè tipa bẹ́ẹ̀ kó àrùn.

BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Àwọn kan kì í jẹ́ kí àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wọnú ilé, kí wọ́n má bàa kó àìsàn látara wọn. Rí i pé o fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tó o bá fọwọ́ kan ẹran ọ̀sìn wọn, kó o sì yẹra fún fífara kan àwọn ẹranko igbó. Bí ẹranko bá fi èékánná ya ẹ́ tàbí gé ẹ jẹ, fomi fọ ibẹ̀ dáadáa kó o sì lọ sọ́dọ̀ dókítà.d

5 ÈÈYÀN

EWU IBẸ̀: Àwọn kòkòrò àrùn kan lè bá ikọ́ tàbí ikunmú ẹni kan jáde sára ẹlòmíì. A tún lè kó wọn tá a bá ń gbáni mọ́ra tàbí bọ ara ẹni lọ́wọ́. Nígbà míì àwọn kòkòrò bẹ́ẹ̀ lè lẹ̀ mọ́ ọwọ́ ìlẹ̀kùn, àtẹ̀gùn, ara tẹlifóònù, rìmóòtù, kọ̀ǹpútà tàbí keyboard.

BÁ A ṢE LÈ DÈNÀ RẸ̀: Má ṣe máa pín bíléèdì lò títí kan tówẹ̀lì àti búrọ́ọ̀ṣì ìfọnu. Má ṣe jẹ́ kí omi ara títí kan ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì tàbí ti ẹranko kan ara rẹ. Rántí pé ara ọ̀nà kan tó o lè gbà yẹra fún àrùn ni pé kó o máa fọ ọwọ́ rẹ lóòrèkóòrè. Òun gan-an ni ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ láti yẹra fún àìsàn.

Tó bá ṣeé ṣe, dúró sílé tó o bá ń ṣàìsàn. Àjọ Centers for Disease Control and Prevention, tó ń rí sí ìdènà àrùn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé tó o bá fẹ́ sín, lo bébà tàbí aṣọ pélébé kan, má ṣe sín sínú ọwọ́ rẹ.

Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Òótọ́ ọ̀rọ̀ gbáà ni ọ̀rọ̀ yẹn, pàápàá lónìí tí ayé kún fún àwọn àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí! Torí náà, máa sá fún ewu kó o sì máa bójú tó ìlera rẹ déédéé. Máa kíyè sí ohun tó ń lọ láyìíká rẹ, kó o lè dènà àrùn!

a Àjọ Ìlera Àgbáyé dábàá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà tọ́jú omi wa. Wọ́n ní a lè máa se omi tàbí ká máa fi oògùn apakòkòrò sínú rẹ̀ tàbí ká máa gbé e sínú oòrùn, tàbí ká fi asẹ́ sẹ́ ẹ.

b Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i lórí bó o ṣe lè máa tọ́jú oúnjẹ, wo Jí! July-September 2012 ojú ìwé 3 sí 9.

c Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe láti dènà àìsàn ibà, wo Jí! September-October 2015 ojú ìwé 12 àti 13.

d Tí ejò bá ṣán ẹ tàbí tí àkekèé ta ẹ́, ojú ẹsẹ̀ ni kó o lọ sílé ìwòsàn.

Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ Nígbà Àjàkálẹ̀ Àrùn

Ìyá àtọmọ ń gba àárín ọjà kọjá

Lọ́dún 2014, àrùn Ẹ̀bólà bẹ̀rẹ̀ sí í jà ràn-ìn láwọn ilẹ̀ tó wà lápá Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, kárí ayé làwọn èèyàn sì ti gbọ́ nípa ẹ̀. Ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè yẹn gbé àwọn ìsọfúnni jáde tó ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn níbẹ̀ láti dènà àrùn náà. Ẹ gbọ́ díẹ̀ lára ohun tí aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nígbà náà sọ.

  • Ẹnì kan ń sọ̀rọ̀

    Báwo lẹ ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ bí àrùn náà ṣe léwu tó?

    A ṣètò ìkéde ìta gbangba láti ṣàlàyé fún àwọn èèyàn bí kòkòrò fáírọ́ọ̀sì náà ṣe ń kó àìsàn ranni àti àwọn àṣà tí wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún, ìlàlóye yìí mú ìbẹ̀rù kúrò lọ́kàn àwọn èèyàn.

  • Fífọ ọwọ́

    Ìgbésẹ̀ wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé?

    A lo irinṣẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní infrared Thermometer láti ṣàyẹ̀wò ìwọ̀n ìgbóná ara àwọn tó ń wọlé wá sí àwọn ibi ìjọsìn wa. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn sì yẹra fún ìfarakanra tí kò pọn dandan, bíi ká máa gbáni mọ́ra àti bíbọ ọwọ́. A tún pèsè ibi téèyàn ti lè fọwọ́, a sì pèsè omi tó ní oògùn apakòkòrò àti ọṣẹ síbẹ̀ kí wọ́n lè máa fọwọ́ lemọ́lemọ́.

  • Fóònù wà nínú ilé kan

    Ọgbọ́n wo lẹ wá ń dá sí i tẹ́ ẹ fi ń bá ìjọsìn àti ìwàásù yín nìṣó?

    Ìjọba ṣòfin kónílégbélé láwọn ibì kan, torí náà a dáwọ́ ìpàdé dúró fúngbà díẹ̀. Àmọ́ a ṣètò pé káwọn ìdílé tó wà níbẹ̀ máa jọ́sìn nílé wọn. Ọ̀pọ̀ sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn lórí fóònù, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dín ìfarakanra kù.

  • Kàlẹ́ńdà

    Tí ẹ bá fura pé ẹnì kan ti ní àmì àìsàn náà lára ńkọ́?

    A máa ń tètè jẹ́ kí àwọn aláṣẹ mọ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá sì fara kan ẹni tó ní Ẹ̀bólà tàbí tó lọ síbi ìsìnkú ẹni tó ní Ẹ̀bólà tàbí tó ní àmì àrùn náà máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ọjọ́ mọ́kànlélógún [21], ìyẹn iye ọjọ́ tí àwọn oníṣègùn sọ pé a gbọ́dọ̀ fi ya ẹni náà sọ́tọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́