ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g17 No. 6 ojú ìwé 10-11
  • Ẹ Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè New Zealand

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè New Zealand
  • Jí!—2017
Jí!—2017
g17 No. 6 ojú ìwé 10-11
Milford Sound, New Zealand

Milford Sound

Ilẹ̀ Àti Àwọn Èèyàn

Ẹ Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè New Zealand

New Zealand lórí àwòrán ilẹ̀

NǸKAN bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún sẹ́yìn ni àwọn ẹ̀yà Maori rìnrìn àjò gba alagbalúgbú òkun tó fẹ̀ lọ salalu, kí wọ́n tó wá tẹ̀dó sí orílẹ̀-èdè New Zealand. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí i pé ilẹ̀ ibẹ̀ yàtọ̀ sí ti erékùṣù olóoru Polynesia tí wọ́n ti ń bọ̀. Àwọn òkè pọ̀ níbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí, àwọn òkìtì yìnyín àti ìsun omi tó lọ́wọ́ọ́wọ́ wà níbẹ̀, yìnyín sì tún máa ń jábọ́ níbẹ̀. Nǹkán bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kó débẹ̀, àwọn ẹ̀yà míì láti ilẹ̀ Yúróòpù kó wá síbẹ̀. Lónìí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè New Zealand ló fẹ́ràn àṣà àwọn ẹ̀yà méjéèjì tó tẹ ibẹ̀ dó, ìyẹn àwọn tó wá láti Polynesia àti àwọn Anglo-Saxon. Ìgboro ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó wà ní orílẹ̀-èdè yìí ń gbé. Wellington ni olú ìlú ibẹ̀, òun sì ni ìlú tó jìnnà sí gúúsù jù lọ lágbàáyé.

Ẹrẹ̀ tó ń hó kùṣùkùṣù tó wà ní Erékùṣù Àríwá New Zealand

Ẹrẹ̀ tó ń hó kùṣùkùṣù tó wà ní Erékùṣù Àríwá

Orílẹ̀-èdè New Zealand ò fi bẹ́ẹ̀ lókìkí tó àwọn orílẹ̀-èdè tó kù, àmọ́ torí pé àwọn nǹkan tó rẹwà gan-an pọ̀ níbẹ̀, àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sí ibẹ̀ lọ́dọọdún fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta.

Igi fern

Igi fern yìí máa ń ga ju ilé alájà-méjì lọ

Ẹyẹ takahe tí kì í fò

Láti ọdún 1948 ni kò ti sí ẹyẹ tó ń jẹ́ takahe yìí mọ́

Oríṣiríṣi àwọn ẹranko ló wà ní orílẹ̀-èdè New Zealand, ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn oríṣi ẹyẹ tí kì í fò pọ̀ sí jù lọ láyé. Ẹranko kan tó dá bí aláǹgbá tí wọ́n ń pè ní Tuatara pọ̀ níbẹ̀, ẹranko yìí lè lò tó ọgọ́rùn-ún [100] ọdún láyé! Díẹ̀ lára àwọn oríṣi ẹranko tó ń fọ́mọ́ lọmú tá a lè rí ní orílẹ̀-èdè yìí ni àwọn àdán, ẹja àbùùbùtán àti dolphin.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́fà [120] ọdún tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù lórílẹ̀-èdè New Zealand. Ó kéré tán, à ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè mọ́kàndínlógún [19], tó fi mọ́ èdè ìbílẹ̀ Polynesia tí wọ́n ń pè ní Niuean, èdè Rarotongan, èdè Samoan, àti èdè Tongan.

Àwọn ẹ̀yà Maori ń kọrin

Àwọn ẹ̀yà Maori wọ aṣọ ìbílẹ̀, wọ́n sì ń jó sí orin ìbílẹ̀ wọn kan

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Ara ìlú kan tó ń jẹ́ Zeeland ní orílẹ̀-èdè Netherlands ni wọ́n ti fa orúkọ náà New Zealand yọ. Orúkọ náà Aotearoa ní èdè Maori túmọ̀ sí “Ìlú Kùrukùru Funfun Tó Tẹ́ Rẹrẹ Lọ.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè New Zealand ń sọ, síbẹ̀ Maori tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ ibẹ̀ ṣì wà lẹ́nu àwọn èèyàn, wọ́n tiẹ̀ máa ń kọ́ àwọn ọmọléèwé ní èdè náà. Ìkànnì jw.org àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní èdè Maori.

  • IYE ÈÈYÀN: 4.7 MÍLÍỌ̀NÙ

  • OLÚ ÌLÚ: WELLINGTON

  • ILẸ̀: ERÉKÙṢÙ ÀRÍWÁ MÁA Ń MÓORU TORÍ ÀWỌN ÒKÈ TÓ Ń YỌ INÁ ÀTI ÈÉFÍN ÀTÀWỌN ÌSUN OMI TÓ LỌ́WỌ́Ọ́WỌ́. ÀWỌN ÒKÌTÌ YÌNYÍN SÌ PỌ̀ NÍ ERÉKÙṢÙ GÚÚSÙ RẸ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́