ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe Àbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́?
    Jí!—2017 | No. 6
    • Doomsday Clock

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ AYÉ YÌÍ TI BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

      Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe Àbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́?

      ÌRÒYÌN burúkú kan látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni aráyé fi bẹ̀rẹ̀ ọdún 2017. Ní oṣù January, àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lágbàáyé kéde pé àjálù ńlá kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí máa tó bá ayé yìí. Wọ́n lo aago ńlá kan tó ń ka wákàtí tí wọ́n ń pè ní Doomsday Clock láti fi ṣàpèjúwe bí ayé yìí ṣe sún mọ́ àjálù náà tó. Wọ́n sún ọwọ́ tó ń ka ìṣẹ́jú síwájú sí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú àáyá. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ohun tó wà lójú Doomsday Clock yìí fi hàn pé ayé ti wà ní aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú méjì àtààbọ̀, tí ìyẹn sì fi hàn pé a ti sún mọ́ àkókò tí àjálù máa bá gbogbo ayé! Láti ọgọ́ta [60] ọdún tí aago yìí ti ń ka wákàtí, àkókò yìí ni aráyé sún mọ́ àjálù yìí jù lọ!

      Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pinnu láti tún aago yìí kà tó bá di ọdún 2018 láti fi mọ bí aráyé ṣe sún mọ́ àjálù tó. Tó bá di ìgbà yẹn, ṣé aago yìí ṣì tún máa fi hàn pé àjálù tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí ti fẹ́ dé bá ayé? Kí ni èrò rẹ? Ṣé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe? Ó lè dà bíi pé ìbéèrè yẹn ṣòro láti dáhùn. Kódà, èrò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pàápàá kò ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ náà. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé àjálù kan ń bọ̀ tó máa pa gbogbo ayé run.

      Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára. Wọ́n sọ pé àwọn ní ẹ̀rí tó dá àwọn lójú pé títí láé ni àwọn èèyàn á máa gbé ayé torí pé ayé ò lè pa rẹ́ láé, wọ́n tún sọ pé ìgbé ayé wa máa dára sí i. Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà lóòótọ́ pé nǹkan máa rí bẹ́ẹ̀? Ṣé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

      “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ṣe aago tí wọ́n ń pè ní Doomsday Clock. Aago yìí ni wọ́n fi ń mọ bí a ṣe sún mọ́ àkókò tí ayé yìí máa pa run tó àti bí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tí à ń fi ọwọ́ ara wa ṣe ṣe máa fa ìparun náà. Àwọn tó gbawájú nínú àwọn ẹ̀rọ yìí ni àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà, àwọn ẹ̀rọ tó ń ṣàkóbá fún ojú ọjọ́, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àtàwọn ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà kan tó lè ṣe jàǹbá tí kò ní àtúnṣe fún àwa èèyàn àti ayé yìí, bóyá torí pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ lò wọ́n lọ́nà tí kò dáa tàbí pé wọ́n ṣì wọ́n lò.”​—Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists.

  • Ohun Tí Àwọn Èèyàn Ń Sọ
    Jí!—2017 | No. 6
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ AYÉ YÌÍ TI BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

      Ohun Tí Àwọn Èèyàn Ń Sọ

      Ọ̀PỌ̀ èèyàn ni ẹ̀rù máa ń bà nítorí àwọn ìròyìn burúkú tí wọ́n ń gbọ́ lójoojúmọ́, ṣé bó ṣe máa ń rí lára tìẹ náà nìyẹn? Lọ́dún 2014, Barack Obama tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà kan sọ pé, torí pé àwọn nǹkan burúkú ni ìròyìn ń gbé jáde, ńṣe ni àwọn èèyàn rò pé “ayé yìí ń sáré tete lọ sí ìparun, kò sì sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe sí i.”

      Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sọ àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ ṣe láti yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Ó tiẹ̀ pe ìgbésẹ̀ tí àwọn ìjọba kan ń gbé ní “ìròyìn ayọ̀,” ó sì sọ pé: “Ọkàn òun balẹ̀, ìrètí òun sì dájú.” Lédè míì, ohun tó ń sọ ni pé gbogbo ìsapá tí àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere ń ṣe lè mú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ àjálù tó ń bọ̀.

      Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní irú èrò yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé, èrò wọn ni pé ìtẹ̀síwájú tó ń lọ nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ ló máa yanjú àwọn ìṣòro tí aráyé ní. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tiẹ̀ fi gbogbo ẹnu sọ pé tó bá máa fi di ọdún 2030, “ìmọ̀ ẹ̀rọ á ti tẹ̀síwájú lọ́nà tó gadabú, tó bá sì máa fi di ọdún 2045, ìtẹ̀síwájú náà á tún ti bùáyà ju ti ọdún 2030 lọ.” Ó tún sọ pé: “Lóòótọ́, àwọn ìṣòro aráyé kò tíì pọ̀ tó báyìí rí, àmọ́ àwọn ohun tá a lè ṣe láti yanjú wọn pọ̀ lọ súà. Torí náà, a lè sọ pé à ń gbìyànjú.”

      Báwo tiẹ̀ ni ayé yìí ṣe bà jẹ́ tó gan-an? Ṣé òótọ́ ni pé àjálù ńlá kan ń bọ̀ tó máa pa gbogbo ayé run? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóṣèlú kan àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń sọ fún àwọn èèyàn pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa, síbẹ̀, ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kò balẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Kí nìdí?

      Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ìṣòro míì tó le koko tí aráyé ń kojú. Àmọ́, tó o bá kàn ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tàbí tó ò ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìyẹn ò ní kó o mọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí gangan. Bá a ṣe sọ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ipò tí ayé yìí wà àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ibo la ti lè rí àwọn ìdáhùn náà?

      Bọ́ǹbù bú gbàù

      ÀWỌN OHUN ÌJÀ RUNLÉ-RÙNNÀ. Ìparapọ̀ orílẹ̀-èdè àtàwọn àjọ míì ti gbìyànjú gan-an láti dín àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà kù, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Ohun tó sì fà á ni pé, ńṣe làwọn aṣíwájú kan tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ kọ̀ láti gbárùkù ti òfin tó máa mú kí wọ́n dín àwọn ohun ìjà kù. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà kò da àwọn ohun ìjà wọn nù, ńṣe ni wọ́n tún ń ṣe àwọn bọ́ǹbù tuntun míì tó túbọ̀ lágbára sí i. Àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tiẹ̀ ní àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tẹ́lẹ̀ ti wá ní àwọn ohun ìjà tí wọ́n lè fi pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.

      Bí àwọn ohun ìjà yìí ṣe gbalẹ̀gbòde ti wá mú kí ayé yìí di ibi eléwu, kódà ní àkókò tó tiẹ̀ dà bíi pé àlàáfíà wà. Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientist sọ pé: “Ó ń kó ìdààmú ọkàn báni láti mọ̀ pé wọ́n ti fi kọ̀ǹpútà ṣe àwọn ohun ìjà kan tó lè máa pa àwon èèyàn lọ ràì láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni ló ń darí wọn.”

      Ọkùnrin kan wà lórí bẹ́ẹ̀dì nílé ìwòsàn

      ÀÌSÀN Ń HAN ÀWỌN ÈÈYÀN LÉÈMỌ̀. Pẹ̀lú gbogbo bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì ṣe ń sapá tó ká lè ní ìlera tó dáa, àwa èèyàn ò yéé ṣàìsàn. Ojoojúmọ́ làwọn nǹkan tó ń fa àìsan ń pọ̀ sí i, àwọn nǹkan bí ẹ̀jẹ̀ ríru, ìlòkulò oògùn, sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ àtàwọn ohun tó ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́. Èyí sì ti fa oríṣiríṣi àìsàn tó ń ṣekú pa ọ̀pọ̀ èèyàn bí àrùn jẹjẹrẹ, àìsàn ọkàn àti ìtọ̀ ṣúgà. Àìsàn ọpọlọ àtàwọn àìsàn míì sì ti sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìlera. Láwọn ọdún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá yìí, àwọn àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí míì tún jẹ yọ, bí àìsàn Ebola àti Zika. Kókó ibẹ̀ ni pé agbára ẹ̀dá èèyàn ò ká àìsàn, ó dà bíi pé àwa èèyàn ò ní yéé máa ṣàìsàn!

      Àwọn nǹkan olóró ń tú jáde sínú afẹ́fẹ́, àwọn èèyàn ń sọ omi di ẹlẹ́gbin

      ÀWỌN ÈÈYÀN Ń BA AYÉ JẸ́. Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́. Àìmọye èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún torí àwọn gáàsì gbẹ̀mígbẹ̀mí táwọn kan ń tú sínú afẹ́fẹ́.

      Àwọn èèyàn àtàwọn ilé iṣẹ́ ìjọba kan máa ń da oríṣiríṣi ìdọ̀tí sínú òkun bí omi ìdọ̀tí, oògùn, àwọn nǹkan oko, ike àtàwọn nǹkan míì. Ìwé Encyclopedia of Marine Science ṣàlàyé pé “ewu ni àwọn ìdọ̀tí tí wọ́n ń dà sínú òkun jẹ́ fún àwọn ohun ẹlẹ́mìí tó wà nínú òkun àtàwọn tó bá jẹ wọ́n.”

      Bẹ́ẹ̀ sì rèé, omi gidi ṣọ̀wọ́n. Òǹṣèwé onímọ̀ sáyẹ́ńsì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ésì tó ń jẹ́ Robin McKie sọ pé: “Gbogbo ayé pátá ni wàhálà ọ̀rọ̀ omi yìí máa kàn.” Àwọn olóṣèlú pàápàá gbà pé àwa èèyàn la fi ọwọ́ ara wa fa ìṣòro àìtó omi, èyí sì lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn.

      Ìjì àjàyípo

      ÌJÁBÁ Ń ṢẸLẸ̀ SÍ ÀWỌN ÈÈYÀN. Ìmìtìtì ilẹ̀, ìjì líle àti ìjì àjàyípo ti fa àkúnya omi, ó sì ń ba ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì jẹ́. Àwọn nǹkan yìí ti ṣe ìpalára fún ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà tó peléke jù ti ìgbàkigbà rí lọ. Nínú ìwádìí kan tí àjọ National Aeronautics and Space Administration ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe tí wọ́n sì tẹ̀ jáde, wọ́n sọ pé “ìjì líle, àwọn ìjì tó ń móoru gan-an àti omíyalé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sírú ẹ̀ rí máa tó ṣẹlẹ̀.” Ṣé àwọn ìjábá yìí ló máa pa ìran ẹ̀dá èèyàn run?

      Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ìṣòro mí ì tó le koko tí aráyé ń kojú. Àmọ́, tó o bá kàn ń ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tàbí tó ò ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìyẹn ò ní kó o mọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí gangan. Bá a ṣe sọ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ipò tí ayé yìí wà àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ibo la ti lè rí àwọn ìdáhùn náà?

  • Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Jí!—2017 | No. 6
    • Ọkùnrin kan nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí

      Ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ nípa aago Doomsday Clock kò ní ṣẹ torí pé Ọlọ́run ti ṣèlérí ọjọ́ iwájú kan tó dára fún gbogbo aráyé

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ AYÉ YÌÍ TI BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

      Kí Ni Bíbélì Sọ?

      ỌGỌ́RỌ̀Ọ̀RÚN ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ pé ayé yìí máa bà jẹ́ gan-an. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Bíbélì tún sọ pé ayé yìí ṣì máa dára gan-an tí gbogbo èèyàn á sì máa gbádùn. Kò yẹ kí èèyàn rò pé àlá tí kò lè ṣẹ ni àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ, torí pé ọ̀pọ̀ lára nǹkan tí Bíbélì sọ ló ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó kàmàmà lákòókò tá a wà yìí.

      Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí:

      • “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.”​—Mátíù 24:7.

      • “Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”​—2 Tímótì 3:​1-4.

      Táwọn kan bá ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ohun tí wọ́n máa sọ ni pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Tá a bá wò ó dáadáa lóòótọ́, ayé ti bà jẹ́ kọjá ààlà torí pé àkóso ayé yìí kò sí lọ́wọ́ èèyàn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn kò ní ọgbọ́n tàbí agbára láti fòpin sí ìṣòro ayé yìí. Òótọ́ yìí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí:

      • “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”​—Òwe 14:12.

      • “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”​—Oníwàásù 8:9.

      • “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀ . . . láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”​—Jeremáyà 10:23.

      Tí àwọn èèyàn bá ń bá a lọ láti máa ṣe ayé yìí bó ṣe wù wọ́n, ìparun ló máa yọrí sí. Àmọ́ ìyẹn kò ní ṣẹlẹ̀ láé! Kí nìdí? Ohun tí Bíbélì sọ ni pé:

      • Ọlọ́run “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”​—Sáàmù 104:5.

      • “Ìran kan ń lọ, ìran kan sì ń bọ̀; ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”​—Oníwàásù 1:4.

      • “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”​—Sáàmù 37:29.

      • “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”​—Sáàmù 72:16.

      Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ìdáhùn tó ṣe kedere. Kì í ṣe àìsàn, àìtó oúnjẹ àti omi tàbí bí àwọn èèyàn ṣè ń ba àyíká jẹ́, ló máa pa ìran èèyàn run. Ogun átọ́míìkì ò sì lè pa ayé yìí run. Kí nìdí? Ọlọ́run ló ń darí àgbáálá ayé wa yìí. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ti fàyè gbà á kí àwọn èèyàn ṣe ohun tó wù wọ́n, àmọ́ tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò tọ́, wọ́n máa jìyà àbájade rẹ̀. (Gálátíà 6:7) Ayé yìí kò dà bí ọkọ̀ ojú irin tó ń já lọ ṣòòròṣò tó fẹ́ mórí wọgbó tí èèyàn ò sì lè dá dúró lójijì. Ó níbi tí Ọlọ́run máa fàyè gba àwọn èèyàn láti ṣèpalára fún ara wọn mọ.​—Sáàmù 83:18; Hébérù 4:13.

      Ọlọ́run máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan míì. Ó máa pèsè “ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Ohun tá a rọra mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ yìí kàn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan rere tó ṣì máa ṣẹlẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti mọ̀ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

      Àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wá láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra jákèjádò ayé ló para pọ̀ di àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n ń jọ́sìn, Jèhófà sì ni orúkọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ. Wọn ò bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, torí Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.’ ”​—Aísáyà 45:18.

      Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú ayé yìí àtàwọn èèyàn inú rẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo ẹ̀kọ́ 5 nínú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì wa www.jw.org/yo

      O tún lè wo fídíò Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? Ó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo. (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN FÍDÍÒ)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́