Apa 3
Bi A Ṣe Lè Mọ̀ Pe Ọlọrun kan Wà
1, 2. Ilana wo ni o ṣeranwọ fun wa lati ṣawari boya Ọlọrun kan wa?
ỌNA kan lati sawari boya Ọlọrun kan wà ni lati lo ilana ti a fidi rẹ̀ mulẹ daradara yii: Ohun ti a ṣe beere fun oluṣe kan. Bi ohun ti a ṣe bá ti díjúpọ̀ tó, bẹẹni agbara oye-iṣe ti oluṣe naa gbọdọ ṣe pọ̀ tó.
2 Fun apẹẹrẹ, wò yika ile rẹ. Awọn tabili, àga-ijokoo, tabili gbọọrọ, ibusun, ìkòkò, abọ́ ìdáná, àwo, ati awọn ohun eelo ìjẹun miiran ni gbogbo wọn beere oluṣe kan, bi awọn ògiri, ilẹ̀ ati àjà ile ti beere fun pẹlu. Sibẹ, awọn nǹkan wọnyẹn rọrun lati ṣe ni ifiwera. Niwọn bi awọn ohun rirọrun ti ń beere fun oluṣe kan, kò ha bá ọgbọn ironu mu pe awọn ohun dídíjúpọ̀ yoo beere oluṣe ti o tubọ jẹ oloye jubẹẹ lọ bi?
Agbaye Wa Amuni Kún Fun Ẹ̀rù-Ọlọ́wọ̀
3, 4. Bawo ni agbaye wa ṣe ṣeranwọ fun wa lati mọ pe Ọlọrun wa?
3 Agogo kan ń beere oluṣe-agogo kan. Ki ni nipa ti eto-igbekalẹ ti o tubọ díjúpọ̀ lọ salaalu ti awọn planẹti ti wọn faramọ oorun, pẹlu Oorun ati awọn planẹti rẹ̀ ti ń yipo yikaakiri pẹlu iṣedeedee titi dori ààbọ̀ iṣẹju-àáyá lati ọrundun kan tẹle omiran? Ki ni nipa ti ìsùpọ̀ irawọ amuni-kun fun ẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ ti a ń gbe inu rẹ̀, ti a ń pe ni ìsùpọ̀ irawọ Milky Way, pẹlu awọn irawọ rẹ̀ ti wọn ju 100 billion ni iye? Iwọ ha ti fi igbakanri duro ni alẹ ki o si bojuwo ìsùpọ̀ irawọ Milky Way naa bi? Kò ha wu ọ lori bi? Nigba naa ronu nipa agbaye ti o gbooro lọna ti o ṣoro lati gbagbọ eyi ti o ni aimọye billion awọn ìsùpọ̀ irawọ bii ti ìsùpọ̀ irawọ Milky Way tiwa! Bakan naa, awọn iṣẹda oju-ọrun naa ṣe e gbarale tobẹẹ gẹẹ ninu ìrìn yipo wọn lati ọrundun kan tẹle omiran ti a fi fi wọn we agogo ti kii tase.
4 Bi agogo kan, ti o rọrun ni ifiwera, bá jẹ ẹri pe oluṣe agogo kan wà, dajudaju agbaye ti o tubọ díjúpọ̀ ti o si kun fun ẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ lọ salaalu naa jẹ ẹri pe olùwéwèé-gbekalẹ ati oluṣe kan wà. Idi niyii ti Bibeli fi kesi wa lati ‘gbe oju wa soke si ibi giga, ki a si wò,’ ti o si wa beere pe: “Ta ni o dá nǹkan wọnyi?” Idahun rẹ̀ ni: O jẹ ẹni naa [Ọlọrun] “ti ń mu ogun wọn jade wà ni iye: o ń pe gbogbo wọn ni orukọ nipa titobi ipá rẹ̀, nitori pe oun le ni ipá; kò si ọkan ti o kù.” (Isaiah 40:26) Nipa bayii, wiwa agbaye wa jẹ nipasẹ agbara oloye, alaiseefojuri, ti ń ṣakoso kan—Ọlọrun.
Ilẹ̀-Ayé Ni A Wéwèé-Gbekalẹ Lọna Àrà-Ọ̀tọ̀
5-7. Awọn otitọ wo nipa ilẹ̀-ayé ni o fihan pe o ni Olúwéwèé-Gbekalẹ kan?
5 Bi awọn onimọ ijinlẹ bá ti ń kẹkọọ nipa ilẹ̀-ayé to, bẹẹni wọn ń mọ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ si i pe a wewe gbe e kalẹ lọna àrà-ọ̀tọ̀ fun ibugbe eniyan. O wà ni iwọn jíjìnnà ti o ṣe wẹku si oorun lati lè ri iwọn imọlẹ ati ooru ti o yẹ gbà. Lẹẹkan lọdun o ń rìn yipo oorun, pẹlu igun ìdábù títọ́, ti o mu ki awọn àsìkò ki o ṣeeṣe ni awọn apa ibi pupọ ni ilẹ̀-ayé. Ilẹ̀-ayé tun ń yipo biri lori òrò tirẹ̀ funraarẹ̀ ni wakati 24 kọọkan, ni pipese awọn akoko siṣedeedee fun imọlẹ ati okunkun. O ni ayika kan pẹlu iwọn idapọmọra awọn afẹfẹ yiyẹ wẹku ti a fi lè mí ti a sì daabobo wa kuro lọwọ itanṣan olóró lati oju ofurufu. O tun ni omi ati ilẹ̀ ṣiṣe pataki ti a nilo fun mimu ounjẹ dagba.
6 Laisi gbogbo awọn koko ipilẹ pataki wọnyẹn, ati awọn miiran, ti ń ṣiṣẹ papọ ni, iwalaaye yoo jẹ eyi ti kò ṣeeṣe. Gbogbo iwọnyẹn ha jẹ nipa èèsì bi? Iwe-irohin atigbadegba naa Science News sọ wi pe: “O dabi ẹni pe o nira pe ki iru awọn ipo pato ati yiyẹ wẹku yẹn ṣàdédé ṣẹlẹ.” Bẹẹkọ, wọn kò lè ṣe bẹẹ. Wọn ni ìwèwéè-gbekalẹ ti a pete rẹ̀ lati ọwọ Olùwéwèé-Gbekalẹ titayọlọla kan ninu.
7 Bi iwọ bá wọnu ile daradara kan tí o si ri i pe a ti kó ounjẹ rẹpẹtẹ kún inú rẹ̀, pe o ni iṣeto fun ìmúlé-mooru ati ìmúlé-tutù ti o kọyọyọ, ati pe o ni iṣeto omi ẹ̀rọ ti o dara, ki ni yoo jẹ opin ero tirẹ? Pe gbogbo rẹ̀ kàn ṣàdédé ṣẹlẹ funraarẹ̀? Bẹẹkọ, o daju pe iwọ yoo dori ero naa pe ẹni olóye kan ni o wéwèé gbe e kalẹ ti o sì ṣe e pẹlu iṣọra ńláǹlà. Ilẹ̀-ayé pẹlu ni a wéwèé-gbekalẹ ti a sì ṣe pẹlu iṣọra ńláǹlà lati lè pese ohun ti awọn olugbe rẹ̀ ń fẹ, o sì tun fi pupọpupọ díjúpọ̀ ti o sì ni awọn ipese funni ju ile eyikeyii lọ.
8. Ki ni ohun miiran ti o tun wa nipa ilẹ̀-ayé ti o fi ibikita onifẹẹ ti Ọlọrun fun wa han?
8 Bakan naa, gbe iye awọn ohun ti ń fikun ayọ wiwalaaye yẹwo. Wo ọpọ salaalu awọn òdòdó alawọ mèremère pẹlu awọn itasansan òórùn wọn fun awọn eniyan lati gbadun. Bẹẹ naa si ni oniruuru ounjẹ rẹpẹtẹ ti wọn gbaladun fun ìtọ́wò wa wà. Awọn igbó, oke, omi adagun, ati awọn iṣẹda miiran ti wọn dun-un wò wà. Ati pẹlu, wíwọ̀ oorun ẹlẹwa ti o ń fikun ayọ igbesi-aye wa ha ń kọ? Ati ni agbegbe ti awọn ẹranko, a kò ha ń mu inu wa dùn pẹlu eré apanilẹrin-in ati irisi afàfẹ́mọ́ra ti awọn ọmọ ajá, ologbo, ati awọn ọmọ ẹranko yooku bi? Nipa bayii ilẹ̀-ayé pese awọn ohun iyalẹnu ti o dunmọni ti kii ṣe dandangbọ̀n fun gbigbe iwalaaye ró. Iwọnyi fihan pe a wéwèé gbe ilẹ̀-ayé kalẹ lọna itọju onifẹẹ, pẹlu nini eniyan lọkan, ti o jẹ pe a ki yoo wulẹ walaaye lasan ṣugbọn a o gbadun igbesi-aye.
9. Ta ni ṣe ilẹ̀-ayé, ki si ni idi ti o fi ṣe e?
9 Nitori naa, opin ero ti o mọgbọndani ni lati tẹwọgba Olufunni ni awọn ohun wọnyi, gẹgẹ bi onkọwe Bibeli naa ti o sọ nipa Jehofa Ọlọrun pe: “Iwọ ni o da ọrun oun ayé.” Fun ete wo? O funni ni idahun nipa ṣiṣapejuwe Ọlọrun gẹgẹ bi Ẹni “ti o mọ ayé, ti o si ṣe e; o ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò da a lasan, o mọ ọn ki a lè gbe inu rẹ̀.”—Isaiah 37:16; 45:18.
Sẹẹli Alaaye Agbayanu Naa
10, 11. Eeṣe ti sẹẹli alaaye kan fi jẹ agbayanu tobẹẹ?
10 Ki ni nipa ti awọn ohun alaaye? Wọn kò ha ń beere fun oluṣe kan bi? Fun apẹẹrẹ, ṣagbeyẹwo awọn ẹka agbayanu melookan ti sẹẹli (ohun alaaye tíntìntín) alaaye kan. Ninu iwe rẹ̀ Evolution: A Theory in Crisis, onimọ ijinlẹ nipa ipin ohun tíntìntín inu-ara ti o kere julọ naa Michael Denton ṣalaye pe: “Koda eyi ti o kere julọ ninu awọn eto-igbekalẹ ẹda alaaye ti o wà lori ilẹ̀-ayé lonii, awọn sẹẹli ti kokoro bacteria, jẹ awọn ohun ti o díjúpọ̀ lọna titayọ. Bi o tilẹ jẹ pe eyi ti o kere julọ ninu awọn sẹẹli ara kokoro bacteria naa ṣe bíntín lọna ti o ṣoro gbagbọ, . . . ọkọọkan jẹ ohun ti a lè pè ni ẹ̀dà ile-iṣẹ kónkóló kan niti gidi ti o ni ẹgbẹẹgbẹrun ẹ̀rọ ti ipin ohun tíntìntín inu-ara ti o kere julọ titakoko ti a wéwèé-gbekalẹ lọna olóye julọ ninu . . . eyi ti o takókó ju ẹ̀rọ eyikeyii ti eniyan tii ṣe rí ti kò sì ni alabaadọgba ninu ayé awọn ohun alailẹmi.”
11 Niti awọn ofin ipilẹ adanida ti o wà ninu sẹẹli kọọkan, oun wi pe: “Agbara iṣe ti DNA lati fi isọfunni pamọ tayọ ju ti eto-igbekalẹ eyikeyii miiran ti a tii mọ̀ lọ; o jafafa tobẹẹ gẹẹ debi pe gbogbo isọfunni ti a nilo lati fi ẹkunrẹrẹ isọfunni nipa ẹda kan ti o díjúpọ̀ gẹgẹ bi eniyan hàn ni o tẹ̀wọ̀n ti o kere ju ìdá kan ninu aadọta ọkẹ iwọn gram kan. . . . Ni ifiwera pẹlu iwọn ọgbọn oye-iṣẹ ati ìdíjúpọ̀ ti a ri ninu eto-igbekalẹ iṣẹ ṣiṣe ti ipin ohun alaaye tíntìntín ti iwalaaye, koda ń ṣe ni awọn [ipese-mujade] wa ti o gba iwaju julọ rí wúruwùru. A nimọlara ìrẹ̀nípòwálẹ̀.”
12. Ki ni onimọ ijinlẹ kan wi nipa ipilẹṣẹ sẹẹli?
12 Denton fikun un pe: “Ìdíjúpọ̀ ti sẹẹli rirọrun julọ ti a mọ̀ gá pupọ tobẹẹ gẹẹ ti o fi jẹ pe kò ṣeeṣe lati gbà pe iru ẹda kan bẹẹ jẹ eyi ti a sọlu araawọn lojiji nipasẹ iru iṣẹlẹ ajeji kan, ti kò lè ṣeeṣe lọna gbigbooro.” O gbọdọ ni oluwewe gbekalẹ ati oluṣe kan.
Ọpọlọ Wa Ti O Kọyọyọ
13, 14. Eeṣe ti ọpọlọ fi tubọ jẹ agbayanu ju sẹẹli alaaye kan lọ?
13 Onimọ ijinlẹ yii sọ bayii lẹhin naa pe: “Niti ìdíjúpọ̀, sẹẹli kọọkan kò jamọ ohunkohun ti a bá fiwera pẹlu eto-igbekalẹ kan bii ti ọpọlọ ẹda afọmọlọmu kan. Ọpọlọ eniyan ní nǹkan bii aadọta ọkẹ lọna ẹgbẹrun mẹwa awọn sẹẹli iṣan imọlara. Olukuluku sẹẹli iṣan imọlara nawọ́ ohun ti o wa nítòsí nǹkan bii ẹgbẹrun mẹwa si ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un iṣan aso-nǹkan-pọ̀ jade nipasẹ eyi ti o fi ni isopọ pẹlu awọn sẹẹli iṣan imọlara yooku ninu ọpọlọ. Gbogbo apapọ iye isopọmọra ninu ọpọlọ eniyan sunmọ . . . aadọta ọkẹ lọna aadọta ọkẹ lọna ẹgbẹrun kan.”
14 Denton ń baa lọ pe: “Koda bi o bá tilẹ jẹ kiki ìdá kan ninu ọgọrun-un awọn isopọmọra ti inu ọpọlọ ni a ṣeto lọna ti o ṣe pato, eyi yoo ṣi jẹ apẹẹrẹ eto-igbekalẹ kan ti o ni iye isopọmọra ti o ṣe pato pupọpupọ ju ti inu gbogbo eto-isopọmọra ti ẹrọ ibanisọrọpọ Ilẹ̀-ayé lọ.” O wa beere lẹhin naa pe: “Ọna-ìgbàṣe nipasẹ èèsì ajeji kan ṣakala ha lè ko iru awọn eto-igbekalẹ wọnyi jọpọ̀ lae bi?” Dajudaju, idahun naa gbọdọ jẹ bẹẹkọ. Ọpọlọ ti nilati ni Olùwéwèé-Gbekalẹ ati Oluṣe kan ti o bikita.
15. Ki ni awọn ọ̀rọ̀ ilohun si ti awọn miiran ti sọ nipa ọpọlọ?
15 Ọpọlọ eniyan mu ki ani ẹrọ kọmputa ti o gba iwaju julọ rí bi ohun wúruwùru-játijàti kan. Onkọwe nipa imọ ijinlẹ naa Morton Hunt sọ pe: “Agbara iranti tiwa ti a ń lò maa ń tọju isọfunni lọna ọpọlọpọ billion iye ìgbà ju ti ẹrọ kọmputa nla ode-oni rẹ̀ ti a fi ń ṣe iwadii kan lọ.” Nipa bayii, oniṣegun iṣẹ-abẹ ọpọlọ naa Dokita Robert J. White de opin ero naa pe: “Emi kò ni yiyan eyikeyii ju pe ki n tẹwọgba wíwà Oloye Gigajulọ kan, ti o wà nidii ìwéwèé-gbekalẹ ati imudagba ibaṣepọ kikọyọyọ ti o wà laaarin ọpọlọ ati ero-inu—ohun kan ti o jìnnà rekọja agbara eniyan lati loye. . . . Mo nilati gbagbọ pe gbogbo iwọnyi ni ipilẹsẹ olóye kan, pe Ẹnikan ni o mu ki o ṣẹlẹ.” Ó si tun nilati jẹ Ẹnikan ti o bikita.
Eto-Igbekalẹ Ìṣàn-Ẹ̀jẹ̀ Àrà-Ọ̀tọ̀ Naa
16-18. (a) Ni awọn ọna wo ni eto-igbekalẹ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ fi jẹ àrà-ọ̀tọ̀? (b) Opin ero wo ni a nilati mu wa de?
16 Ṣagbeyẹwo, pẹlu, eto-igbekalẹ ìṣàn-ẹ̀jẹ̀ àrà-ọ̀tọ̀ naa ti ń gbe awọn ohun ìṣaralóore ati afẹfẹ oxygen yikaakiri ara ti o si ń ṣedena àkóràn aarun. Niti awọn sẹẹli pupa inu ẹ̀jẹ̀, ohun ti eto-igbekalẹ yii ni ninu julọ, iwe naa ABC’s of the Human Body ṣalaye pe: “Ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ kanṣoṣo pere ní ohun ti o ju 250 million awọn sẹẹli ẹ̀jẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ninu . . . Ara ní iye wọn ti o jẹ boya 25 trillion ninu, ti o pọ̀ to, ti a bá tẹ́ wọn silẹ ni ifẹgbẹkẹgbẹ, lati bo pápá iṣere bọọlu tẹnisi mẹrin tán. . . . Awọn afirọpo ni a ń ṣe, ni iwọn iye ti o jẹ 3 million awọn sẹẹli titun ni iṣẹju àáyá kọọkan.”
17 Nipa ti awọn sẹẹli funfun inu ẹ̀jẹ̀, ẹ̀ka miiran ninu eto-igbekalẹ ìṣàn ẹ̀jẹ̀ àrà-ọ̀tọ̀ naa, orisun kan naa yii sọ fun wa pe: “Nigba ti o jẹ pe kiki oriṣi sẹẹli ẹ̀jẹ̀ pupa kanṣoṣo ni o wa, awọn sẹẹli ẹ̀jẹ̀ funfun wà ni ẹ̀yà oniruuru, oriṣi kọọkan pẹlu agbara iṣe lati ja ogun inu ara ni ọna ọtọọtọ. Oriṣi kan, fun apẹẹrẹ, ń run awọn sẹẹli ti wọn ti ku. Awọn oriṣi miiran ń pese eroja-ara agbogun-ti-aarun lodisi awọn kokoro virus, ń pa oró awọn ohun ajeji ti o wọnu ara, tabi ki wọn jẹ ki wọn si gbé awọn kokoro bacteria mì niti gidi.”
18 Ẹ wo iru eto-igbekalẹ agbayanu ati eleto giga ti eyi jẹ! Dajudaju ohunkohun ti a bá tò papọ daradara tobẹẹ ti o si jẹ alaabo tobẹẹ gbọdọ ni oluṣeto olóye ti o si bikita gidigidi kan—Ọlọrun.
Awọn Ohun Iyanu Miiran
19. Bawo ni oju ti ṣe ri ni ifiwera pẹlu awọn ohun eelo atọwọda ti eniyan?
19 Ọpọlọpọ awọn ohun iyanu miiran ni wọn wà ninu ara eniyan. Ọkan ni oju, ti a wewe gbekalẹ lọna ti o gọntiọ debi pe kò si kamẹra ti o lè ṣe bii tirẹ̀. Onimọ ijinlẹ nipa gbangba ojude ofurufu naa Robert Jastrow sọ pe: “O dabi pe ń ṣe ni a wéwèé gbe oju kalẹ; kò si olùwéwèé-gbekalẹ awọn awò afiwo-ojude-ofurufu kan ti ìbá ti lè ṣe daradara ju bẹẹ lọ.” Itẹjade naa Popular Photography si ṣalaye pe: “Oju eniyan ri oniruuru kulẹkulẹ pupọpupọ gan an ju bi film kan ti lè ṣe lọ. Wọn maa ń riran ni igun mẹta, ni igun ti o gbooro lọna kikọyọyọ, laisi idilọwọ, lọna ti o ń baa lọ . . . Fifi kamẹra wera pẹlu oju eniyan kii ṣe ọna ironu didara kan lati fi ìjọra hàn. Oju eniyan jọ àgbà-ẹrọ kọmputa agbayanu kan pẹlu agbara oye atọwọda, agbara iṣe lati bojuto isọfunni, iyara kankan ṣiṣẹ, ati ọna ìgbà ṣiṣẹ ti o fi pupọpupọ tayọ ẹrọ atọwọda ti eniyan eyikeyii, ìbáà jẹ́ ẹrọ kọmputa tabi kamẹra.”
20. Ki ni awọn apá agbayanu miiran ninu ara eniyan?
20 Ronu, pẹlu, nipa ọna ti gbogbo awọn ẹ̀ka kekeeke dídíjúpọ̀ ti awọn ẹ̀yà ara gba ń ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ laisi awọn isapa aronuṣe tiwa. Fun apẹẹrẹ, a maa ń kó oniruuru ounjẹ ati ohun mimu si inu ikùn wa, sibẹ ara maa ń ṣiṣẹ le wọn lori ti wọn si maa ń pese agbara ìṣiṣẹ́. Gbiyanju lati fi oniruuru awọn nǹkan bẹẹ sinu jala epo ọkọ̀ kan ki o si ri bi yoo ti rin jìnna to! Iṣẹ iyanu ti ibimọ tun wà pẹlu, imujade ọmọ ọwọ kan ti a fẹran gidigidi—ẹ̀dà ti awọn obi rẹ̀—ni iwọn oṣu mẹsan pere. Ki sì ni nipa ti agbara iṣe ọmọde ọlọjọ ori diẹ pere kan lati kẹkọọ bi a ti ń fi ede dídíjúpọ̀ kan sọrọ?
21. Ni gbigbe awọn iyalẹnu ti ara yẹwo, ki ni awọn eniyan olóye sọ?
21 Bẹẹni, ọpọlọpọ awọn iṣẹda kekeeke titakoko, yiyanilẹnu ninu ara eniyan fi ẹ̀rù ọlọ́wọ̀ kun inu wa. Kò si onimọ ẹrọ kan ti o lè ṣe ẹ̀dà awọn nǹkan wọnyẹn. Wọn ha lè wulẹ jẹ iṣẹ ọwọ́ èèṣì afọju kan lasan bi? Dajudaju bẹẹkọ. Kàkà bẹẹ, nigba ti wọn bá ń ṣagbeyẹwo gbogbo ẹ̀ka ti o kun fun iyanu ninu ara eniyan, awọn eniyan olóye ń sọ, gẹgẹ bi olorin naa ti sọ pe: “Emi o yin ọ [Ọlọrun]; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu ni a da mi: iyanu ni iṣẹ rẹ̀.”—Orin Dafidi 139:14.
Akọ́lé Gigajulọ Naa
22, 23. (a) Eeṣe ti o fi yẹ ki a tẹwọgba wíwà Ẹlẹdaa naa? (b) Ki ni Bibeli sọ lọna ẹtọ nipa Ọlọrun?
22 Bibeli ṣalaye pe: “Olukuluku ile ni a kọ lati ọwọ́ ẹnikan, dajudaju; ṣugbọn Ọlọrun ni o kọ ohun gbogbo ti o wà.” (Heberu 3:4, The Jerusalem Bible) Niwọn bi ile eyikeyii, bi o ti wu ki o rọrun to, ti gbọdọ ni ẹni ti o kọ ọ, nigba naa agbaye wa ti o dijupọ lọpọlọpọ jubẹẹ lọ, papọ pẹlu ọ̀gọ̀rọ̀ oniruuru iwalaaye ori ilẹ̀-ayé, gbọdọ ti ni ẹnikan ti o kọ ọ pẹlu. Ati niwọn bi a ti tẹwọgba wíwà awọn eniyan ti o da awọn ohun eelo bii ọkọ̀ ofurufu, tẹlifisọn, ati ẹ̀rọ kọmputa, kò ha yẹ ki a tẹwọgba wíwà ti Ẹni naa ti o fun awọn eniyan ni ọpọlọ lati ṣe iru awọn nǹkan wọnyẹn bi?
23 Bibeli ṣe bẹẹ, ni pipe e ni “Ọlọrun Oluwa [“Jehofa,” NW] . . . ẹni ti o dá ọrun, ti o nà wọn jade; ẹni ti o tẹ́ ayé, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹni ti o fi eemi fun awọn eniyan lori rẹ̀.” (Isaiah 42:5) Bibeli polongo lọna ẹtọ pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW], iwọ ni o yẹ lati gba ogo ati ọlá ati agbara: nitori pe iwọ ni o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni wọn fi wà ti a si da wọn.”—Ìfihàn 4:11.
24. Bawo ni a ṣe lè mọ̀ pe Ọlọrun kan wà?
24 Bẹẹni, awa lè mọ pe Ọlọrun kan wà nipasẹ awọn nǹkan ti oun ti ṣe. “Nitori ohun [Ọlọrun] ti o farasin lati igba dida ayé a ri wọn gbangba, a ń fi oyé ohun ti [Ọlọrun] dá mọ̀ ọn.”—Romu 1:20.
25, 26. Eeṣe ti àṣìlò ohun kan kii fii ṣe idi fun ariyanjiyan lodisi pe o ni oluṣe kan?
25 Otitọ naa pe a ṣi ohun kan ti a ṣe lò kò tumọ si pe kò ni oluṣe. Ọkọ̀ ofurufu kan ni a lè lò fun awọn ete alalaafia, gẹgẹ bi ọkọ̀ ofurufu akérò kan. Ṣugbọn a tun lè lò ó fun ṣiṣe iparun, gẹgẹ bi ọkọ̀ ofurufu kan ti a fi ń ju bọmbu. Lilo ti a lò ó ni ọna aṣekupani kan kò tumọ si pe kò ni oluṣe.
26 Lọna ti o farajọra, otitọ naa pe awọn eniyan ti yipada di buruku lọpọlọpọ ìgbà tobẹẹ kò tumọ si pe wọn kò ni Oluṣe kan, pe kò si Ọlọrun. Nitori naa, Bibeli sọrọ akiyesi lọna titọ pe: “Iwa idibajẹ ẹyin eniyan wọnyi! A ha nilati fi amọkoko funraarẹ̀ we amọ̀ bi? Tabi o ha yẹ ki ohun ti a ṣe sọ nipa oluṣe rẹ̀ pe: ‘Oun kò ṣe mi’? Ohun naa gan an ti a sì mọ ha lè sọ niti gidi nipa ẹni ti o mọ ọn pe: ‘Oun kò fi imoye han’?”—Isaiah 29:16, NW.
27. Eeṣe ti a fi lè reti pe ki Ọlọrun dahun awọn ibeere wa nipa ijiya?
27 Ẹlẹdaa naa ti fi ọgbọn rẹ̀ han nipasẹ ìdíjúpọ agbayanu ti awọn ohun ti oun ṣe. Oun fihan pe oun bikita nipa wa niti gidi nipa ṣiṣe ayé lọna yiyẹ wẹku fun gbigbe, nipa ṣiṣe ara ati ero-inu wa ni iru ọna kan ti o kun fun iyanu bẹẹ, ati nipa ṣiṣe ọpọlọpọ awọn ohun rere fun wa lati gbadun. Dajudaju oun yoo fi iru ọgbọn ati ibikita fifarajọra bẹẹ han nipa sisọ awọn idahun di mímọ̀ si iru awọn ibeere bii: Eeṣe ti Ọlọrun fi fayegba ijiya? Ki ni oun yoo ṣe nipa rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ilẹ̀-ayé, pẹlu ayika adaaboboni rẹ̀, jẹ ibugbe àrà-ọ̀tọ̀ kan ti a wéwèé-gbekalẹ fun wa lati ọwọ Ọlọrun kan ti o bikita
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ilẹ̀-ayé ni a ṣe pẹlu ibikita onifẹẹ ki a bá a lè gbadun iwalaaye ni kikun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
‘Ọpọlọ kanṣoṣo ni iye isopọmọra ti o ju ti inu gbogbo eto-isopọmọra ti ẹrọ ibanisọrọpọ Ilẹ̀-ayé lọ.’—Onimọ ijinlẹ nipa ipin ohun tíntìntín inu-ara ti o kere julọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
“O dabi pe ń ṣe ni a wéwèé gbe oju kalẹ; kò si olùwéwèé-gbekalẹ awọn awò afiwo-ojude-ofurufu kan ti ìbá ti lè ṣe daradara ju bẹẹ lọ.”—Onimọ ijinlẹ nipa gbangba ojude ofurufu