ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 220
  • “Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ”
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A. “Ọrẹ”
  • B. “Gbogbo Ilẹ̀ Tí Wọ́n Fi Ṣe Ọrẹ”
  • D. “Ilẹ̀ Ìjòyè”
  • E. “Ilẹ̀ [Tàbí Ọrẹ] Mímọ́”
  • Ẹ. “Ibi Tó Ṣẹ́ Kù”
  • “Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Tẹ́ńpìlì Náà” Àti “Ìjòyè Náà” Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Pín Ilẹ̀ Náà Bí Ogún”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 220

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 21A

“Ilẹ̀ Tí Ẹ Ó Yà Sọ́tọ̀ Láti Fi Ṣe Ọrẹ”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 48:8

Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé Ìsíkíẹ́lì láti jọ wo ilẹ̀ tí Jèhófà yà sọ́tọ̀ náà dáadáa. Apá márùn-ún ni ilẹ̀ náà pín sí. Apá márùn-ún wo nìyẹn? Kí ló sì wà fún?

Àwòrán ilẹ̀ tí Jèhófà yà sọ́tọ̀, èyí tí wọ́n pè ní ‘ọrẹ’ àti àwòrán ilẹ̀ tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ (kìlómítà 13) ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti àríwá sí gúúsù àti láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn. Ilẹ̀ náà dọ́gba ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, Bíbélì sì pè é ní “Gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ.” Wọ́n pín in sí ọ̀nà mẹ́ta ní ìbú, ìyẹn apá òkè, àárín níbi tí tẹ́ńpìlì wà àti apá kékeré tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ìsàlẹ̀, níbi táa ti máa rí ìlú tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní “Jèhófà Wà Níbẹ̀.”

A. “Ọrẹ”

Àwọn tó ń ṣàkóso ìlú náà ló wà fún, wọ́n sì tún máa ń pè é ní “ibi tó wà fún iṣẹ́ àbójútó.”

ÌSÍK. 48:8

B. “Gbogbo Ilẹ̀ Tí Wọ́n Fi Ṣe Ọrẹ”

Ó wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti ìlú náà. Bákan náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan látinú gbogbo ẹ̀yà méjìlá (12) náà ló ń wọ ibẹ̀ láti wá jọ́sìn Jèhófà, kí wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn fún ètò àkóso ìlú náà.

ÌSÍK. 48:20

D. “Ilẹ̀ Ìjòyè”

“Ilẹ̀ yìí yóò di ohun ìní rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.” “Yóò sì jẹ́ ti ìjòyè.”

ÌSÍK. 45:​7, 8; 48:​21, 22

E. “Ilẹ̀ [Tàbí Ọrẹ] Mímọ́”

Wọ́n tún pè é ní ‘ìpín tó jẹ́ mímọ́.’ Ibi tó wà lápá òkè ilẹ̀ náà jẹ́ ti “àwọn ọmọ Léfì.” “Ohun mímọ́” ló jẹ́. “Ilẹ̀ mímọ́ tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà” ló wà ní àárín. “Ibẹ̀ ni ilé wọn máa wà, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ibi mímọ́” tàbí tẹ́ńpìlì.

ÌSÍK. 45:​1-5; 48:​9-14

Ẹ. “Ibi Tó Ṣẹ́ Kù”

“Yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Ísírẹ́lì.” “Ó máa jẹ́ ti gbogbo ìlú, wọ́n á máa gbé ibẹ̀, ẹran wọn á sì máa jẹko níbẹ̀.”

ÌSÍK. 45:6; 48:​15-19

Pa dà sí orí 21, ìpínrọ̀ 3

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́