ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 206
  • Omi Kékeré Di Odò Ńlá!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Omi Kékeré Di Odò Ńlá!
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Odò Náà Mú Ìbùkún Wá
  • Omi Ìyè
  • Àwọn Igi Tó Wà fún Oúnjẹ àti Ìwòsàn
  • ‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ìbùkún Jèhófà Lórí “Ilẹ̀” Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àwọn Odò Ìbùkún Látọ̀dọ̀ Jèhófà
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 206

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 19B

Omi Kékeré Di Odò Ńlá!

Ìsíkíẹ́lì rí omi tó rọra ń ṣàn láti ibi mímọ́ Jèhófà, tó sì di odò ńlá lọ́nà tó yani lẹ́nu, ó jìn, ó sì ń ya mùúmùú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, díẹ̀ ló fi ṣàn ju máìlì kan péré lọ! Ó rí àwọn igi ńláńlá létí odò náà tó ń pèsè oúnjẹ aṣaralóore, tó sì wà fún ìwòsàn. Kí ni gbogbo rẹ̀ túmọ̀ sí?

Omi kan tó ń ṣàn jáde látinú ibi mímọ́ Jèhófà, tó sì di odò ńlá. Àwọn àmì tó jẹ́ ká mọ bí omi náà ṣe jìn tó. 1,000 ìgbọ̀nwọ́: ó dé kókósẹ̀. 2,000 ìgbọ̀nwọ́: ó dé orúnkún. 3,000 ìgbọ̀nwọ́: ó dé ìbàdí. 4,000 ìgbọ̀nwọ́: kò ṣeé fi ẹsẹ̀ là kọjá.

Odò Náà Mú Ìbùkún Wá

NÍGBÀ ÀTIJỌ́: Bí àwọn ìgbèkùn náà ṣe ń pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìbùkún ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn bí wọ́n ṣe ń kópa nínú bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò ní tẹ́ńpìlì

LÓDE ÒNÍ: Ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò lọ́dún 1919, èyí mú kí odò ìbùkún tẹ̀mí tí kò sírú rẹ̀ rí ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run

LỌ́JỌ́ IWÁJÚ: Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ìbùkún tẹ̀mí àti tara máa ṣàn wá látọ̀dọ̀ Jèhófà

Omi Ìyè

NÍGBÀ ÀTIJỌ́: Jèhófà rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn olóòótọ́ èèyàn rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láásìkí nípa tẹ̀mí

LÓDE ÒNÍ: Nínú párádísè tẹ̀mí tó ń gbòòrò sí i, àwọn èèyàn tó ń pọ̀ sí i ló ń jàǹfààní àwọn ìbùkún tẹ̀mí tó túbọ̀ ń ṣàn wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ti di alààyè nípa tẹ̀mí

LỌ́JỌ́ IWÁJÚ: Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó jíǹde á dara pọ̀ mọ́ àwọn tó máa la Amágẹ́dọ́nì já, ìbùkún Jèhófà tó pọ̀ rẹpẹtẹ á sì kárí gbogbo wọn

Àwọn Igi Tó Wà fún Oúnjẹ àti Ìwòsàn

NÍGBÀ ÀTIJỌ́: Jèhófà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ nígbà tó mú wọn pa dà bọ̀ sípò ní ilẹ̀ wọn; ó tún wò wọ́n sàn lọ́wọ́ àìsàn tẹ̀mí tó ti ń bá wọn fínra tipẹ́

LÓDE ÒNÍ: Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí ń gba àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn àti ebi tẹ̀mí tó gbòde kan lóde òní

LỌ́JỌ́ IWÁJÚ: Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n á jọ ṣàkóso máa ran gbogbo èèyàn tó ń ṣègbọràn lọ́wọ́ láti di ẹni pípé kí wọ́n sì ní ìlera tó dáa títí láé!

Pa dà sí orí 19, ìpínrọ̀ 4 sí 21

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́