ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 76-77
  • Àwọn Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọmọ Èèyàn”
  • “. . . Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
  • “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ”
  • Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • “Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Ọlọ́run Ni Kí O Jọ́sìn”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Kí Ni Ìjọsìn?
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 76-77

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 7B

Àwọn Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

“Ọmọ Èèyàn”

Ó LÉ NÍ ÌGBÀ 90 TÓ FARA HÀN

Ó lé ní àádọ́rùn-ún (90) ìgbà tí wọ́n pe Ìsíkíẹ́lì ni “ọmọ èèyàn.” (Ìsík. 2:1) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà ń rán Ìsíkíẹ́lì létí pé èèyàn lásán ló ṣì jẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó gbàfiyèsí pé nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, nǹkan bí ìgbà ọgọ́rin (80) ni wọ́n pe Jésù ní “Ọmọ èèyàn,” èyí sì fi hàn pé Jésù di èèyàn délẹ̀délẹ̀ nígbà tó wà láyé, kì í ṣe pé ó jẹ́ áńgẹ́lì tó kàn gbé ara èèyàn wọ̀.​—Mát. 8:20.

“. . . Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”

Ó LÉ NÍ ÌGBÀ 50 TÓ FARA HÀN

Ó ju àádọ́ta (50) ìgbà lọ tí Ìsíkíẹ́lì ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn á “wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,” èyí fi hàn pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ìjọsìn mímọ́ tọ́ sí.​—Ìsík. 6:7.

“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ”

ÌGBÀ 217 LÓ FARA HÀN

Ìgbà ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́tàdínlógún (217) ni gbólóhùn náà “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ” fara hàn, èyí jẹ́ ká rí bí Bíbélì ṣe gbé orúkọ Ọlọ́run lékè, ó sì tún fi hàn pé Jèhófà ju gbogbo ẹ̀dá lọ.​—Ìsík. 2:4.

Pa dà sí orí 7, ìpínrọ̀ 28

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́