ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 31. Jésù Kristi ti di Ọba ní ọ̀run, ó dúró síwájú Jèhófà tó wà nínú ògo rẹ̀.

      Ẹ̀KỌ́ 31

      Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

      Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni ohun pàtàkì tí Bíbélì dá lé. Ìjọba yẹn ni Jèhófà máa lò láti sọ ayé di Párádísè pa dà. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ti ń ṣàkóso báyìí? Àwọn nǹkan wo ló ti ṣe? Àwọn nǹkan wo ló sì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú ẹ̀kọ́ yìí àtàwọn ẹ̀kọ́ méjì tó tẹ̀ lé e.

      1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta sì ni Ọba Ìjọba náà?

      Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní ọ̀run. Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba náà, àtọ̀run ló sì ti ń ṣàkóso. (Mátíù 4:17; Jòhánù 18:36) Bíbélì sọ pé Jésù “máa jẹ Ọba . . . títí láé.” (Lúùkù 1:32, 33) Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa ṣàkóso gbogbo àwọn tó wà láyé.

      2. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?

      Jésù nìkan kọ́ ló máa dá ṣàkóso. Àwọn èèyàn látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè . . . máa ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.” (Ìfihàn 5:9, 10) Àwọn mélòó ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi? Látìgbà tí Jésù ti wá sáyé, àìmọye èèyàn ló ti di Kristẹni. Àmọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) péré lára wọn ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ka Ìfihàn 14:1-4.) Gbogbo àwọn Kristẹni tó kù láyé sì máa jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.​—Sáàmù 37:29.

      3. Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ìjọba èèyàn lọ?

      Nígbà míì, a lè rí àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàkóso tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣohun tó dáa fáwọn aráàlú, àmọ́ agbára wọn kì í gbé e láti ṣe gbogbo ohun tó dáa tí wọ́n ní lọ́kàn. Tó bá yá, ẹlòmíì á rọ́pò wọn, onítọ̀hún sì lè má ní ire ará ìlú lọ́kàn. Àmọ́ ní ti Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, kò sẹ́ni tó lè rọ́pò ẹ̀ tàbí tó lè gba ìjọba lọ́wọ́ ẹ̀. Ọlọ́run ti “gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Gbogbo ayé ni Jésù máa ṣàkóso, kò sì ní ṣojúsàájú. Kò mọ síbẹ̀ o, ó nífẹ̀ẹ́ wa, olóore ni, ìdájọ́ òdodo ló máa ń ṣe, ó sì máa kọ́ àwọn èèyàn pé káwọn náà nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, kí wọ́n máa ṣoore, kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo.​—Ka Àìsáyà 11:9.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi dáa ju ìjọba èèyàn lọ.

      Jésù Kristi ń ṣàkóso ayé látorí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Àwọn tí wọ́n máa bá a ṣàkóso wà lórí ìjókòó lẹ́yìn rẹ̀. Ògo Jèhófà ń tàn yòò lẹ́yìn wọn.

      4. Ìjọba kan tó lágbára máa ṣàkóso gbogbo ayé

      Jésù lágbára ju gbogbo àwọn tó ti ṣàkóso láyé lọ. Ka Mátíù 28:18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló mú kí àṣẹ Jésù ju ti àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso lọ?

      Ní ti ìjọba èèyàn, tẹ́nì kan bá ṣàkóso lónìí, ẹlòmíì á gbà á lọ́la, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ti ní apá ibi tí àkóso ẹ̀ dé. Àmọ́ Ìjọba Ọlọ́run ńkọ́? Ka Dáníẹ́lì 7:14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé Ìjọba Ọlọ́run ‘kò ní pa run’?

      • Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé gbogbo ayé ni Ìjọba Ọlọ́run á máa ṣàkóso?

      5. Ìjọba èèyàn gbọ́dọ̀ dópin

      Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

      FÍDÍÒ: Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?​—Àyọlò (1:41)

      • Àkóbá wo ni ìjọba èèyàn ti ṣe fún aráyé?

      Ka Oníwàásù 8:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Ṣé o gbà pé ó yẹ kí Ìjọba Ọlọ́run rọ́pò ìjọba èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      6. Ọ̀rọ̀ wa yé Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso

      Torí pé Jésù Ọba wa ti gbé ayé rí gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó lè “bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” (Hébérù 4:15) Bákan náà, “látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè” ni Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso.​—Ìfihàn 5:9.

      • Ṣé ọkàn ẹ balẹ̀ bó o ṣe mọ̀ pé Jésù àti gbogbo àwọn tó máa bá a ṣàkóso mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      Àwọn ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run ti ń yàn látìgbà àtijọ́ títí di òde òní. Inú gbogbo ẹ̀yà àti èdè ni Ọlọ́run ti yàn wọ́n.

      Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin látinú gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù

      7. Àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ti ìjọba èèyàn lọ

      Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Bákan náà, Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn òfin tí àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run náà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-​11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run?a

      • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ lé àwọn òfin yìí? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

      • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn òfin yìí lè yí pa dà?​—Wo ẹsẹ 11.

      Ọlọ́pàá kan dá mọ́tò dúró ní oríta kan táwọn èèyàn ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀. Àwọn èèyàn lọ́mọdé àti lágbá ń sọdá títì.

      Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Àmọ́ àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run ṣàǹfààní gan-an ju ti ìjọba èèyàn lọ

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ gbé kalẹ̀ ní ọ̀run, ó sì máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé.

      Kí lo rí kọ́?

      • Àwọn wo ló máa jẹ́ alákòóso Ìjọba Ọlọ́run?

      • Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ìjọba èèyàn lọ?

      • Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan ti Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ibi tí Jésù sọ pé Ìjọba Ọlọ́run wà.

      “Ṣé Inú Ọkàn Rẹ Ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi gbogbo ọkàn wa tì lẹ́yìn dípò ìjọba èèyàn?

      Ìjọba Ọlọ́run Ni Wọ́n Fara Mọ́ (1:43)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí Jèhófà yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.

      “Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Kí ló mú kí obìnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìrẹ́jẹ kúrò láyé?

      “Mo Ti Wá Mọ Bí Àìṣẹ̀tọ́ Ṣe Máa Dópin” (Jí!, July-September, 2011)

      a A máa ṣàlàyé àwọn kan lára òfin yìí tá a bá dé Apá 3.

  • Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 32. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run di ọ̀pá àṣẹ mú, ó sì ń ṣàkóso ayé.

      Ẹ̀KỌ́ 32

      Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

      Ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. Ọdún yẹn náà ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ìṣàkóso èèyàn bẹ̀rẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀? Jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa bí nǹkan ṣe máa rí láyé àti ìwà táwọn èèyàn á máa hù, èyí tó túbọ̀ ń hàn kedere láti ọdún 1914.

      1. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀?

      Ìwé Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn àkókò kan tí Bíbélì pè ní “ìgbà méje” ni Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. (Dáníẹ́lì 4:16, 17) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Jésù tún pe ìgbà méje yìí ní “àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ó sì sọ pé àkókò náà ò tíì parí. (Lúùkù 21:24) Bá a ṣe ń bá ẹ̀kọ́ yìí nìṣó, a máa rí i pé ọdún 1914 ni ìgbà méje yẹn parí.

      2. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìwà wo ló ti túbọ̀ ń hàn kedere láti ọdún 1914?

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Kí ló máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?’ (Mátíù 24:3) Jésù wá sọ oríṣiríṣi nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Lára àwọn nǹkan tó sọ pé á máa ṣẹlẹ̀ ni ogun, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀. (Ka Mátíù 24:7.) Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà táwọn èèyàn á máa hù ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” máa mú kí nǹkan “nira.” (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti ìwà àwọn èèyàn, ní pàtàkì látọdún 1914 fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

      3. Kí nìdí tí nǹkan fi nira gan-an láyé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

      Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù jagun, ó sì ṣẹ́gun wọn. Bíbélì sọ pé ‘a ju Sátánì sí ayé, a sì ju àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (Ìfihàn 12:9, 10, 12) Inú ń bí Sátánì gan-an, torí ó mọ̀ pé òun máa pa run. Ìdí nìyẹn tó fi ń dá wàhálà sílẹ̀ ní gbogbo ayé, tó sì ń mú káyé nira fáwa èèyàn. Abájọ tí wàhálà fi pọ̀ tó báyìí láyé! Àmọ́, Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú gbogbo ìṣòro tí Sátánì ti dá sílẹ̀.

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ohun tó mú kó dá wa lójú pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àti bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe kàn wá.

      4. Àwọn ìtàn inú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso

      Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Ọdún 1914 Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso (5:02)

      Ọlọ́run mú kí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá àlá kan nípa ohun kan tó máa ṣẹlẹ̀. Àlá yẹn àti ohun tí Dáníẹ́lì sọ pé ó túmọ̀ sí jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ló jẹ́ àsọtélẹ̀ nípa àkóso Nebukadinésárì àti Ìjọba Ọlọ́run.​—Ka Dáníẹ́lì 4:17.a

      Ka Dáníẹ́lì 4:20-26, lẹ́yìn náà kó o fi àtẹ tó wà lójú ìwé 133 dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • (A) Kí ni Nebukadinésárì rí nínú àlá?​—Wo ẹsẹ 20 àti 21.

      • (B) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí igi náà?​—Wo ẹsẹ 23.

      • (D) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí “ìgbà méje” náà bá parí?​—Wo ẹsẹ 26.

      Ohun Tí Àlá Nípa Igi Náà Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Ìjọba Ọlọ́run

      ÀSỌTẸ́LẸ̀ (Dáníẹ́lì 4:20-36)

      Àkóso

      (A) Igi ńlá náà

      Igi ńlá tó ga gan-an.

      Àkóso náà dáwọ́ dúró

      (B) “Ẹ gé igi náà lulẹ̀,” “títí ìgbà méje fi máa kọjá lórí rẹ̀”

      Wọ́n fi ọ̀já irin àti bàbà de kùkùté igi kan.

      Àkóso náà bẹ̀rẹ̀ pa dà

      (D) “Ìjọba rẹ máa pa dà di tìrẹ”

      Igi ńlá tó ga gan-an.

      Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ . . .

      • (E) Ta ni igi náà ṣàpẹẹre?​—Wo ẹsẹ 22.

      • (Ẹ) Báwo ni àkóso rẹ̀ ṣe dáwọ́ dúró?​—Ka Dáníẹ́lì 4:29-33.

      • (F) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì lẹ́yìn tí “ìgbà méje” náà parí?​—Ka Dáníẹ́lì 4:34-36.

      ÌGBÀ TÍ ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÁÀ KỌ́KỌ́ ṢẸ

      Àkóso

      (E) Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì

      Ọba Nebukadinésárì dúró, ó ń gbéra ga.

      Àkóso náà dáwọ́ dúró

      (Ẹ) Lẹ́yìn ọdún 606 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, orí Nebukadinésárì dà rú kò sì lè ṣàkóso mọ́ fún ọdún méje

      Nebukadinésárì jókòó sílẹ̀, ó ń jẹ koríko bí ẹranko.

      Àkóso náà bẹ̀rẹ̀ pa dà

      (F) Orí Nebukadinésárì pé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso pa dà

      Ọba Nebukadinésárì gbọ́wọ́ sókè, ó ń wojú ọ̀run.

      Nígbà kejì tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ . . .

      • (G) Àwọn wo ni igi náà ṣàpẹẹrẹ?​—Ka 1 Kíróníkà 29:23.

      • (GB) Báwo ni àkóso wọn ṣe dáwọ́ dúró? Báwo la ṣe mọ̀ pé àkóso náà ò tíì bẹ̀rẹ̀ pa dà nígbà tí Jésù wà láyé?​—Ka Lúùkù 21:24.

      • (H) Ìgbà wo ni ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ pa dà, ibo ló sì ti ń ṣàkóso?

      ÌGBÀ KEJÌ TÍ ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÁÀ ṢẸ

      Àkóso

      (G) Àwọn ọba Ísírẹ́lì tó ń ṣojú fún Ọlọ́run

      Àwọn ọba Ísírẹ́lì jókòó sórí ìtẹ́, bí wọ́n ṣe jẹ tẹ̀ léra. Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí wọn látọ̀run.

      Àkóso náà dáwọ́ dúró

      (GB) Nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run, ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún (2,520) ọdún ni kò fi sí ọba kankan tó jẹ ní Ísírẹ́lì

      Wọ́n fi iná sun ìlú Jerúsálẹ́mù àtijọ́ lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó yá, 2,520 ọdún pé.

      Àkóso náà bẹ̀rẹ̀ pa dà

      (H) Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run

      Nígbà tó di ọdún 1914, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé látorí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ìmọ́lẹ̀ ń tàn yòò látọ̀dọ̀ rẹ̀.

      Báwo ni ìgbà méje náà ṣe gùn tó?

      Àwọn apá kan nínú Bíbélì máa ń jẹ́ káwọn apá ibòmíì túbọ̀ yé wa. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìfihàn sọ pé àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ àkókò jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà (1,260) ọjọ́. (Ìfihàn 12:6, 14) Ìlọ́po méjì àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ àkókò á wá jẹ́ àkókò méje, tàbí ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún (2,520) ọjọ́. Nínú Bíbélì, nígbà míì ọjọ́ kan máa ń túmọ̀ sí ọdún kan. (Ìsíkíẹ́lì 4:6) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn pẹ̀lú ìgbà méje tí ìwé Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ohun tó túmọ̀ sí ni ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún (2,520) ọdún.

      5. Ọdún 1914 ni ayé yí pa dà bìrí

      Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Ọdún 1914 Ni Ayé Yí Pa Dà Bìrí (1:10)

      Jésù sọ bí nǹkan ṣe máa rí láyé tóun bá ti di Ọba. Ka Lúùkù 21:9-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Èwo nínú àwọn nǹkan tá a kà yìí lo ti fojú ara ẹ rí tàbí tó o gbọ́ nípa ẹ̀?

      Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ bí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn ṣe máa rí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ìṣàkóso èèyàn. Ka 2 Tímótì 3:1-5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Èwo lára àwọn ìwà àti ìṣe yìí lo ti rí?

      Àwòrán: Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti ìwà àwọn èèyàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. 1. Ọ̀gá ológun kan dúró níbi pèpéle kan, ó gbọ́wọ́ sókè, ó ń pariwo sọ̀rọ̀. 2. Àwọn ilé kan wó lulẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì. 3. Ọkọ̀ òfúrufú àwọn ológun. 4. Àwọn èèyàn tó fi nǹkan bo imú ń rìn lọ. 5. Ilé gogoro méjì tó wà nílùú New York ń jóná lẹ́yìn táwọn afẹ̀míṣòfò ṣọṣẹ́ níbẹ̀. 6. Ọkùnrin kan ń lo oògùn olóró. 7. Ọkùnrin kan di ọwọ́ ẹ̀ṣẹ́ sí ìyàwó rẹ̀, ó sì ń pariwo mọ́ ọn. 8. Oríṣiríṣi oògùn olóró àti ọtí líle. 9. Àwọn obìnrin méjì wọ aṣọ oge ìgbàlódé, wọ́n sì lo àwọn ohun ọ̀ṣọ́ lóríṣiríṣi, wọ́n ń ya fọ́tò. 10. Ọkùnrin kan ń gbórin jáde níbi táwọn èèyàn ti ń ṣe fàájì, ó gbọ́wọ́ ijó sókè, àwọn èèyàn sì ń jó. 11. Inú ń bí ọkùnrin kan, ó sì ju ohun ìjà oníná síbì kan.

      6. Máa ṣe ohun tó fi hàn pé o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso

      Ka Mátíù 24:3, 14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Iṣẹ́ pàtàkì wo ló fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso?

      • Kí ló yẹ kó o ṣe tí ìwọ náà bá fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ yìí?

      Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Láìpẹ́, ó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé. Ka Hébérù 10:24, 25, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ṣe bá a ṣe ń “rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé”?

      Àwòrán: 1. Obìnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. 2. Obìnrin náà ń wàásù fún ẹnì kan tó mọ̀ rí.

      Tó o bá mọ ohun kan tó lè ran àwọn míì lọ́wọ́ tó sì lè gba ẹ̀mí wọn là, kí ló yẹ kó o ṣe?

      ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ọdún pàtàkì ni ọdún 1914?”

      • Kí lo máa sọ?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, ìtàn Bíbélì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé fi hàn gbangba pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Tá a bá ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, ńṣe là ń fi hàn pé a gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lóòótọ́.

      Kí lo rí kọ́?

      • Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìgbà méje tí ìwé Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ parí?

      • Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

      • Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun táwọn òpìtàn àtàwọn míì sọ nípa bí ayé ṣe yí pa dà bìrí lọ́dún 1914.

      “Bí Ìwà Rere Ṣe Ṣàdédé Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jó Rẹ̀yìn” (Jí!, April 2007)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Mátíù 24:14 ṣe mú kí ìgbésí ayé ọkùnrin kan yí pa dà.

      “Mo Fẹ́ràn Baseball Gan-an!” (Ilé Ìṣọ́ No. 3 2017)

      Báwo la ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì orí 4 ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?

      “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀? (Apá 1)” (Ilé Ìṣọ́, October 1, 2014)

      Kí ló fi hàn pé ọdún 1914 ni “ìgbà méje” tí ìwé Dáníẹ́lì orí 4 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ parí?

      “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀? (Apá 2)” (Ilé Ìṣọ́, November 1, 2014)

      a Wo àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó gbẹ̀yìn apá Ṣèwádìí nínú ẹ̀kọ́ yìí.

  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe fún Aráyé
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • Ẹ̀kọ́ 33. Àwọn èèyàn ń gbé ayé tó ti di Párádísè.

      Ẹ̀KỌ́ 33

      Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe fún Aráyé

      Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Láìpẹ́, ó máa tún ayé yìí ṣe. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun rere tá a máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run.

      1. Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo jọba láyé?

      Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn burúkú run, ó sì máa fòpin sí gbogbo ìjọba èèyàn. (Ìfihàn 16:14, 16) Tó bá dìgbà yẹn, ohun tó wà ní Sáàmù 37:10 máa ṣẹ láìkù síbì kan. Ó ní: “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́.” Jésù máa lo Ìjọba Ọlọ́run láti mú kí àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo jọba ní gbogbo ayé.​—Ka Àìsáyà 11:4.

      2. Báwo ni ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́?

      Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, “àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sáàmù 37:29) Fojú inú wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí gbogbo èèyàn bá jẹ́ olódodo, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn! Àwọn èèyàn ò ní máa ṣàìsàn mọ́, wọ́n á sì wà láàyè títí láé.

      3. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run?

      Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run, Jésù máa ṣàkóso ayé fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. Nígbà yẹn, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá a ṣàkóso á sọ gbogbo èèyàn tó wà láyé di pípé. Tí ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn bá fi máa parí, ayé á ti di Párádísè, àwọn èèyàn tó jẹ́ aláyọ̀ torí pé wọ́n ń gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu ló sì máa wà ní gbogbo ayé. Lẹ́yìn náà, Jésù máa dá àkóso pa dà fún Jèhófà Bàbá rẹ̀. ‘Orúkọ Jèhófà á wá di mímọ́’ lọ́nà tó ga jù lọ. (Mátíù 6:9, 10) Ó máa wá hàn kedere pé Alákòóso tó dáa ni Jèhófà, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Jèhófà á wá pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù run, títí kan gbogbo àwọn èèyàn tó ń ta ko Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfihàn 20:7-10) Tí Ìjọba Ọlọ́run bá ti tún ayé yìí ṣe, kò tún ní sí ìṣòro kankan mọ́ títí láé!

      KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

      Jẹ́ ká wo ohun tó mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe gbogbo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

      4. Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí ìjọba èèyàn

      “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí ìyà tí ìjọba èèyàn fi ń jẹ aráyé.

      Ka Dáníẹ́lì 2:44 àti 2 Tẹsalóníkà 1:6-8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ni Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ máa ṣe sí ìjọba èèyàn àtàwọn tó ń ti ìjọba èèyàn lẹ́yìn?

      • Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù ṣe mú kó dá ẹ lójú pé wọ́n máa ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ fún gbogbo èèyàn?

      Jésù ti di Ọba ní ọ̀run, ó ń ṣàkóso ayé tó ti di Párádísè.

      5. Jésù ni Ọba tó yẹ wá

      Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ṣe aráyé láǹfààní. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí Jésù ṣe fi hàn pé ó ń wu òun gan-an láti ran àwa èèyàn lọ́wọ́ àti pé ó máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.

      FÍDÍÒ: Jésù Jẹ́ Ká Mọ Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe (1:13)

      Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe. Èwo lára àwọn ohun rere tó wà nísàlẹ̀ yìí ló ń wù ẹ́ jù? Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun rere náà.

      NÍGBÀ TÍ JÉSÙ WÀ LÁYÉ, Ó . . .

      LÁTỌ̀RUN, JÉSÙ MÁA . . .

      • mú kí ìjì líle pa rọ́rọ́.​—Máàkù 4:36-41.

      • mú kí ayé di ibi tó rẹwà, tó sì tura láti gbé​—Àìsáyà 35:1, 2.

      • fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní oúnjẹ.​—Mátíù 14:17-21.

      • mú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ wà láyé, ó sì máa kárí gbogbo èèyàn.​—Sáàmù 72:16.

      • mú ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn lára dá.​—Lúùkù 18:35-43.

      • mú kí ara gbogbo èèyàn jí pépé.​—Àìsáyà 33:24.

      • jí àwọn òkú dìde.​—Lúùkù 8:49-55.

      • jí àwọn òkú dìde, àwọn èèyàn ò sì ní máa kú mọ́.​—Ìfihàn 21:3, 4.

      6. Ìjọba Ọlọ́run máa mú káyé tura gan-an

      Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún àwa èèyàn níbẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn á máa gbé ayé títí láé. Wo FÍDÍÒ yìí kó o lè rí bí Jèhófà ṣe máa lo Ọmọ rẹ̀, Jésù, láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn fún àwa èèyàn.

      FÍDÍÒ: Àwọn Ohun Àgbàyanu Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la (4:38)

      Ka Sáàmù 145:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́”?

      ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Táwa èèyàn bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, a lè yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé fúnra wa.”

      • Àwọn ìṣòro wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú, àmọ́ tó jẹ́ pé ìjọba èèyàn ò lè yanjú wọn láé?

      KÓKÓ PÀTÀKÌ

      Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún àwa èèyàn. Ó máa sọ gbogbo ayé di Párádísè, àwọn èèyàn rere nìkan ló máa wà ní gbogbo ayé, wọ́n á sì máa jọ́sìn Jèhófà títí láé.

      Kí lo rí kọ́?

      • Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́?

      • Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe gbogbo àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

      • Èwo lára àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ló ń wù ẹ́ jù?

      Ohun tó yẹ kó o ṣe

      ṢÈWÁDÌÍ

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́.

      “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá.”—Mátíù 24:21.

      “Kí Ni Ìpọ́njú Ńlá?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

      Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn ìdílé ṣe lè máa ronú nípa àwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe.

      Wo Ara Rẹ Bíi Pé O Wà ní Párádísè (1:50)

      Ka ìtàn tí àkòrí ẹ̀ sọ pé, “Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè Ń Jà Gùdù Lọ́kàn Mi,” kó o lè rí bí ọkùnrin kan tó máa ń bá ìjọba fa wàhálà ṣe rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ń wá.

      “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2012)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́