ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lff ẹ̀kọ́ 43
  • Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?
  • Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
  • KÓKÓ PÀTÀKÌ
  • ṢÈWÁDÌÍ
  • Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọtí Lo Fi Ń Wò Ó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Bó O Ṣe Lè Yẹra fún Ọtí Àmujù
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
lff ẹ̀kọ́ 43
Ẹ̀kọ́ 43. Ọtí líle àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò wà lórí tábìlì níbi àpèjẹ kan.

Ẹ̀KỌ́ 43

Ṣó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Mu Ọtí?

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

Kárí ayé, èrò tó yàtọ̀ síra làwọn èèyàn ní nípa ọtí mímu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn kan máa ń mu ọtí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àwọn kan sì wà tí wọn kì í mutí rárá. Àmọ́, ńṣe làwọn kan máa ń mutí yó. Kí ni Bíbélì sọ nípa ọtí mímu?

1. Ṣé ó burú kéèyàn máa mu ọtí?

Bíbélì ò sọ pé ká má mu ọtí. Dípò ìyẹn, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún àwa èèyàn, ó ka “wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀” mọ́ àwọn ẹ̀bùn náà. (Sáàmù 104:14, 15) Kódà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan wà tí Bíbélì sọ pé wọ́n mu ọtí.—1 Tímótì 5:23.

2. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún wa nípa ọtí?

Jèhófà ò fẹ́ ká máa mutí lámujù tàbí ká máa mutí yó. (Gálátíà 5:21) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Má ṣe wà lára àwọn tó ń mu wáìnì lámujù.” (Òwe 23:20) Torí náà, tá a bá fẹ́ mu ọtí, ì báà jẹ́ nínú ilé tàbí níta, kò yẹ ká ki àṣejù bọ̀ ọ́. Torí pé tá a bá mutí lámujù, a ò ní lè ronú lọ́nà tó tọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tí kò yẹ ká sọ, a lè hùwà tí kò yẹ ká hù, ó sì lè mú ká máa ṣàìsàn. Tá a bá rí i pé a ò lè mutí níwọ̀nba, á kúkú dáa ká má mutí mọ́ rárá.

3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe nípa ọtí mímu?

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu bóyá òun máa mu ọtí àbí òun ò ní mu. Tí ẹnì kan bá pinnu pé òun á mutí níwọ̀nba, kò yẹ ká fojú burúkú wo onítọ̀hún. Bákan náà, tí ẹnì kan bá sọ pé òun ò mutí, a ò gbọ́dọ̀ fipá mú un. (Róòmù 14:10) A lè yàn láti má mu ọtí láwọn ìgbà tá a bá rí i pé ó lè mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (Ka Róòmù 14:21.) Bíbélì sọ pé “kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ ká lè pinnu bóyá ó yẹ ká mutí tàbí kò yẹ àti bí ọtí tá a fẹ́ mu ṣe yẹ kó pọ̀ tó. Bákan náà, wàá tún rí ohun tó o lè ṣe tó o bá níṣòro ọtí mímu.

4. Ìwọ lo máa pinnu bóyá wàá mutí àbí o ò ní mu

Kí ni èrò Jésù nípa ọtí mímu? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe. Ka Jòhánù 2:1-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa èrò ẹ̀ lórí ọtí àti ojú tó fi ń wo àwọn tó ń mu ọtí?

  • Nígbà tó jẹ́ pé Jésù ò sọ pé ọtí mímu ò dáa, ṣó yẹ kí Kristẹni kan máa fojú burúkú wo àwọn tó bá ń mutí?

Àmọ́, tí Kristẹni kan bá tiẹ̀ lómìnira láti mutí, kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló bọ́gbọ́n mu pé kó máa mutí. Ka Òwe 22:3, lẹ́yìn náà kó o wò ó bóyá ó yẹ kó o mutí:

  • Tó o bá fẹ́ wa mọ́tò tàbí o fẹ́ fi ẹ̀rọ kan ṣiṣẹ́.

  • Tó o bá lóyún.

  • Tí dókítà bá sọ pé kó o má mutí mọ́.

  • Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lo máa ń mu ọtí lámujù.

  • Tí òfin ìjọba ò bá gbà ẹ́ láyè láti mutí.

  • Tó o bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í fẹ́ mutí rárá, torí pé o ti fìgbà kan níṣòro ọtí mímu.

Ṣó yẹ kó o fáwọn èèyàn ní ọtí níbi ìgbéyàwó ẹ tàbí níbi àpèjẹ míì? Kó o lè mọ ìpinnu ti wàá ṣe, wo FÍDÍÒ yìí.

FÍDÍÒ: Ṣó Yẹ Kí N Fún Àwọn Èèyàn Ní Ọtí Níbi Ìgbéyàwó Mi? (2:41)

Ka Róòmù 13:13 àti 1 Kọ́ríńtì 10:31, 32. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà yìí, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn?

Arákùnrin kan wà nílé oúnjẹ, ó sọ pé òun ò fẹ́ ọtí. Àwọn arábìnrin méjì tó wà pẹ̀lú ẹ̀ ń mu wáìnì.

Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa mu ọtí àbí òun ò ní mu. Àwọn ìgbà míì sì wà tẹ́nì kan lè rí i pé ohun tó máa dáa jù ni pé kí òun má mu ọtí

5. Má ṣe mu ọtí lámujù

Tó o bá fẹ́ mu ọtí, fi sọ́kàn pé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò sọ pé ká má ṣe mutí, ó sọ pé a ò gbọ́dọ̀ mutí lámujù. Kí nìdí? Ka Hósíà 4:11, 18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tẹ́nì kan bá ń mutí lámujù, kí ló lè ṣẹlẹ̀?

Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa mutí lámujù? A gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa, ká má kọjá àyè wa. Ka Òwe 11:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀wọ̀n ara ẹ tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu?

6. Pinnu pé wàá jáwọ́ nínú ọtí àmujù

Jẹ́ ká wo ohun tó mú kí ọkùnrin kan jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

FÍDÍÒ: ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi’ (6:32)

Àwòrán: Àwọn apá kan nínú fídíò náà ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi.’ 1. Dmitry ń wo ìgò ọtí tó wà lọ́wọ́ ẹ̀. 2. Dmitry, ìyàwó ẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀.
  • Nínú fídíò yẹn, báwo ni Dmitry ṣe máa ń ṣe tó bá ti mutí yó?

  • Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú ọtí mímu?

  • Kí ló ràn án lọ́wọ́ tó fi bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù?

Ka 1 Kọ́ríńtì 6:10, 11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni Bíbélì sọ nípa mímu ọtí lámujù?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tó ń mu ọtí àmujù lè yí pa dà?

Ka Mátíù 5:30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Ohun tí gígé ọwọ́ sọ nù ń ṣàpẹẹrẹ ni pé kẹ́nì kan sapá gan-an láti jáwọ́ nínú àṣà kan tó ti mọ́ ọn lára kó lè múnú Jèhófà dùn. Kí lo lè ṣe tó bá ṣòro fún ẹ láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù?a

Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tó bá jẹ́ pé àwọn tó ń mutí àmujù lò ń bá rìn, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ?

ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni kéèyàn mu ọtí?”

  • Kí lo máa sọ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Ọtí wà lára àwọn nǹkan rere tí Jèhófà fún àwa èèyàn láti máa fi gbádùn ara wa. Àmọ́, kò fẹ́ ká máa mutí lámujù tàbí ká máa mutí lámupara.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí ni Bíbélì sọ nípa ọtí?

  • Àkóbá wo ni ọtí àmujù lè ṣe fún wa?

  • Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì ṣe nípa ọtí mímu?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọtí Di Ìdẹkùn fún Ẹ (2:31)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù.

“Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2010)

Ṣó yẹ káwọn Kristẹni máa na ife ọtí sókè láti fi kan tí ẹlòmíì?

“Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” (Ilé Ìṣọ́, February 15, 2007)

Ka ìtàn ọkùnrin kan tí ọtí mímu ti di bárakú fún, àmọ́ tó bọ́ lọ́wọ́ àṣà yìí nígbà tó yá. Àkòrí ìtàn náà ni “Òkú ọ̀mùtí ni mí.”

“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, May 1, 2012)

a Tí ọtí àmujù bá ti di bárakú fún ẹnì kan, ohun tó máa dáa ni pé kó lọ rí àwọn dókítà tó máa ń tọ́jú àwọn tí ọtí ti di bárakú fún. Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn dókítà sọ ni pé tẹ́nì kan bá ti níṣòro ọtí mímu rí, kò yẹ kónítọ̀hún tún fẹnu kan ọtí mọ́ rárá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́