Ìgbéyàwó
Ta ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀?
Ta ló yẹ kí Kristẹni kan fẹ́?
Kí nìdí tí òbí kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kò fi ní fọwọ́ sí i pé kí ọmọ òun tó ti ṣèrìbọmi fẹ́ ẹni tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 24:1-4, 7—Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù ti darúgbó, àárín àwọn tó ń sin Jèhófà ló ti wá ìyàwó fún Ísákì ọmọ ẹ̀, kì í ṣe láàárín àwọn ọmọ Kénánì tó jẹ́ abọ̀rìṣà
Jẹ 28:1-4—Ísákì sọ fún Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ pé àárín àwọn tó ń sin Jèhófà ni kó ti fẹ́yàwó, dípò àwọn ọmọ Kénánì
Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ bá fẹ́ aláìgbàgbọ́?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Ọb 11:1-6, 9-11—Inú Jèhófà ò dùn sí Ọba Sólómọ́nì torí pé kò pa òfin Jèhófà mọ́ bó ṣe fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì, tó sì tún gbà káwọn obìnrin náà mú kó di abọ̀rìṣà
Ne 13:23-27—Bíi ti Jèhófà, inú bí Gómìnà Nehemáyà gan-an sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì tí kò sin Jèhófà, torí náà ó bá wọn wí
Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kẹ́nì kan fẹ́ ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tó sì ní orúkọ rere?
Tún wo Ef 5:28-31, 33
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
1Sa 25:2, 3, 14-17—Ọlọ́rọ̀ ni Nábálì, àmọ́ èèyàn tó le ni, ìwà ẹ̀ sì burú, torí náà kì í ṣe ọkọ rere fún Ábígẹ́lì
Owe 21:9—Tẹ́nì kan ò bá fara balẹ̀ nígbà tó ń yan ọkọ tàbí ayá tó máa fẹ́, ó lè fẹ́ ẹni tí kò ní jẹ́ kó láyọ̀, tí kò sì ní fi í lọ́kàn balẹ̀
Ro 7:2—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé tí obìnrin kan bá lọ́kọ, ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìpé máa ní àṣẹ lórí ẹ̀ dé àyè kan. Torí náà, tí obìnrin kan bá fẹ́ fi hàn pé òun jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó máa ronú jinlẹ̀ tó bá fẹ́ pinnu ẹni tóun máa fẹ́
Ó yẹ káwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó múra sílẹ̀
Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkùnrin kan rí i pé òun máa lè gbọ́ bùkátà ìyàwó àtàwọn ọmọ kó tó gbéyàwó?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Owe 24:27—Ó yẹ kí ọkùnrin kan ṣiṣẹ́ kára kó tó gbéyàwó tàbí bímọ, ìyẹn ló máa jẹ́ kó lè bójú tó ìdílé ẹ̀ dáadáa
Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà gba ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n, kí wọ́n sì gbìyànjú láti mọ ara wọn dáadáa, dípò tí wọ́n á fi máa wo ẹwà nìkan?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Rut 2:4-7, 10-12—Bóásì mọ irú ẹni tí Rúùtù jẹ́ nígbà tó ronú nípa ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹ̀, bó ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, bó ṣe ń ṣe sí Náómì àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Rut 2:8, 9, 20—Rúùtù mọ irú ẹni tí Bóásì jẹ́ nígbà tó kíyè sí bó ṣe jẹ́ onínúure, tó jẹ́ òlàwọ́, tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà kíyè sára kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń fẹ́ra wọn sọ́nà?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Owe 5:18, 19—Àwọn nǹkan kan wà tó jẹ́ pé àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè ṣe é láti fìfẹ́ hàn síra wọn
Sol 1:2; 2:6—Nígbà tí ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì àti ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà ń fẹ́ra wọn sọ́nà, wọ́n fìfẹ́ hàn síra wọn lọ́nà tó dáa, wọn ò ṣèṣekúṣe
Sol 4:12; 8:8-10—Ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì kó ara ẹ̀ níjàánu, kò sì hùwàkiwà, ńṣe ló dà bí ọgbà tí wọ́n tì pa
Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá òfin ìjọba mu?
Ohun tó yẹ kí ọkọ máa ṣe
Kí ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn ọkọ máa ṣe?
Àpẹẹrẹ ta ló yẹ káwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni máa tẹ̀ lé?
Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ kan máa gba ti ìyàwó ẹ̀ rò, kó sì máa fìfẹ́ hàn sí i?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 21:8-12—Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kó fetí sí ohun tí Sérà ìyàwọ́ ẹ̀ sọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù ò fara mọ́ ohun tí ìyàwó ẹ̀ sọ
Owe 31:10, 11, 16, 28—Ọkọ tó bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n kò ní máa jẹ gàba lórí ìyàwó ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní máa ṣàríwísí ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa fọkàn tán an, á sì máa gbóríyìn fún un
Ef 5:33—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó yẹ kí ọkọ máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ òun
Ohun tó yẹ kí ìyàwó máa ṣe
Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn ìyàwó tó jẹ́ Kristẹni máa ṣe?
Ṣé ipò tí Ọlọ́run fi àwọn aya sí fi hàn pé wọn ò níyì?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Owe 1:8; 1Kọ 7:4—Ọlọ́run fún àwọn aya àtàwọn ìyá láǹfààní láti lo àwọn àṣẹ kan nínú ìdílé
1Kọ 11:3—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé gbogbo wa la wà lábẹ́ àṣẹ kan tàbí òmíì nínú ètò Ọlọ́run, àyàfi Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ni kò sí lábẹ́ ẹnikẹ́ni
Heb 13:7, 17—Tọkùnrin tobìnrin ló gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn sí àwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni
Báwo ni aya tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Kristẹni ṣe lè múnú Jèhófà dùn?
Kí nìdí tó fi yẹ kí aya tó jẹ́ Kristẹni máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 18:12; 1Pe 3:5, 6—Sérà máa ń pọ́n ọkọ ẹ̀ lé, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un látọkàn wá, kódà ó pè é ní “olúwa mi”
Irú aya wo ni Bíbélì sọ pé wọ́n máa gbóríyìn fún?
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì:
Jẹ 24:62-67—Nígbà tí ìyá Ísákì kú, Rèbékà ìyàwó ẹ̀ tù ú nínú
1Sa 25:14-24, 32-38—Ábígẹ́lì gba ọkọ ẹ̀ tó hùwà òmùgọ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ Dáfídì, ó sì dáàbò bo agbo ilé rẹ̀ torí pé ó fìrẹ̀lẹ̀ bẹ Dáfídì pé kó ṣàánú àwọn
Ẹst 4:6-17; 5:1-8; 7:1-6; 8:3-6—Kí Ẹ́sítà Ayaba lè dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó lọ síwájú ọkọ ẹ̀ tó jẹ́ ọba láìjẹ́ pé ó pè é
Bí tọkọtaya ṣe lè yanjú ìṣòro
Àwọn ìlànà wo ló lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro?
Àwọn ìlànà wo ló lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ owó?
Lk 12:15; Flp 4:5; 1Ti 6:9, 10; Heb 13:5
Tún wo “Owó”