ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w08 9/1 ojú ìwé 3
  • Ǹjẹ́ O Mọ Baba Rẹ Ọ̀run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ Baba Rẹ Ọ̀run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Baba Wa Ọ̀run Nífẹ̀ẹ́ Wa Gan-an
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ǹjẹ́ O Ka Jèhófà sí Bàbá Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ta Ni Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2019
  • ‘Ọmọ Fẹ́ Láti Ṣí Baba Payá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
w08 9/1 ojú ìwé 3

Ǹjẹ́ O Mọ Baba Rẹ Ọ̀run?

ǸJẸ́ o mọ bàbá rẹ dáadáa? Ìbéèrè yìí lè ṣàjèjì sí ọ tó bá jẹ́ pé inú ilé tẹ́ ẹ ti nífẹ̀ẹ́ ara yín ni wọ́n ti tọ́ ẹ dàgbà. O lè dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ bàbá mi dáadáa!’ Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló mọ ohun tí bàbá wọn fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, bó ṣe máa ń hùwà láwọn ipò kan àti bó ṣe máa ń bójú tó ìdílé rẹ̀.

Síbẹ̀, ìgbà míì lè wà tí ẹnu máa yà ẹ́ tó o bá rí i tí bàbá rẹ ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí bó ṣe máa ń ṣe nǹkan tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kan lè mọ bàbá rẹ̀ sí ẹni jẹ́jẹ́ àti oníwà tútù títí dìgbà tí nǹkan pàjáwìrì kan bá ṣẹlẹ̀. Lójú ẹsẹ̀, yóò rí i tí bàbá rẹ̀ á ṣe ìṣe akin láti dáàbò bo ìdílé rẹ̀.

Báwo lo ṣe mọ Ẹlẹ́dàá wa tó? Bíbélì sọ fún wa nípa rẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìwàláàyè wa ti wá, òun ni Baba gbogbo àwọn tó wà láàyè. (Aísáyà 64:8) Tó bá jẹ́ pé èrò rẹ nìyẹn nípa Ọlọ́run, èrò yẹn dára ó sì tọ̀nà. Àmọ́ ṣá o, ohun púpọ̀ ṣì wà tó yẹ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run. Tá a bá mọ̀ wọ́n, á ṣe wá láǹfààní, á sì mú inú wa dùn.

Bó o ṣe mọ bàbá rẹ tó ló máa sọ irú èrò tó o máa ní nípa rẹ̀ àti bó o ṣe máa bọ̀wọ̀ fún un tó. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí ní ti Ọlọ́run. Bó o bá ṣe mọ̀ ọ́n tó, ni àjọṣe rẹ pẹ̀lú rẹ̀ yóò ṣe lágbára tó. Tó o bá mọ Ọlọ́run dáadáa, tó o sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò ìgbésí ayé rẹ.

Irú ẹni wo ni Ọlọ́run? Báwo ni àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣe lè ní ipa lórí èrò tó o ní nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ mímọ̀ tó o mọ Ọlọ́run gbé àwọn iṣẹ́ kan lé ọ lọ́wọ́? Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Bó o ṣe mọ àwọn ẹlòmíì tó ló máa sọ irú èrò tó o máa ní nípa wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́